Fò sí àkóónú

circa 605–538 BC

The Babylonian Exile

Jerusalem falls and the temple burns; Ezekiel and Daniel minister among the exiles as Lamentations mourns the city's ruin.

1,784 ẹsẹ · 3 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ẹkún Jeremiah 3:7nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Ó ti tì mí mọ́ ilé, nítorí náà n kò le è sálọ; ó ti fi ẹ̀wọ̀n mú mi mọ́lẹ̀.

  2. Ẹkún Jeremiah 3:8nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Pàápàá nígbà tí mo ké fún ìrànlọ́wọ́, ó kọ àdúrà mi.

  3. Ẹkún Jeremiah 3:9nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Ó fi ògiri òkúta dí ọ̀nà mi; ó sì mú ọ̀nà mi wọ́.

  4. Ẹkún Jeremiah 3:10nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Bí i beari tí ó dùbúlẹ̀, bí i kìnnìún tí ó sá pamọ́.

  5. Ẹkún Jeremiah 3:11nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Ó wọ́ mi kúrò ní ọ̀nà, ó tẹ̀ mí mọ́lẹ̀ ó fi mi sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́.

  6. Ẹkún Jeremiah 3:12nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Ó fa ọfà rẹ̀ yọ ó sì fi mí ṣe ohun ìtafàsí.

  7. Ẹkún Jeremiah 3:13nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Ó fa ọkàn mí ya pẹ̀lú ọfà nínú àkọ̀ rẹ̀.

  8. Ẹkún Jeremiah 3:14nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Mo di ẹni yẹ̀yẹ́ láàrín àwọn ènìyàn mi; wọn yẹ̀yẹ́ mi pẹ̀lú orin ní gbogbo ọjọ́.

  9. Ẹkún Jeremiah 3:15nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Ó ti kún mi pẹ̀lú ewé kíkorò àti ìdààmú bí omi.

  10. Ẹkún Jeremiah 3:16nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Ó ti fi òkúta kán eyín mi; ó ti tẹ̀ mí mọ́lẹ̀ nínú eruku.

  11. Ẹkún Jeremiah 3:17nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Mo ti jìnnà sí àlàáfíà; mo ti gbàgbé ohun tí àṣeyege ń ṣe.

  12. Ẹkún Jeremiah 3:18nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà mo wí pé, “Ògo mi ti lọ àti ìrètí mi nínú Olúwa.”

  13. Ẹkún Jeremiah 3:19nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Mo ṣe ìrántí ìpọ́njú àti ìdààmú mi, ìkorò àti ìbànújẹ́.

  14. Ẹkún Jeremiah 3:20nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Mo ṣèrántí wọn, ọkàn mi sì gbọgbẹ́ nínú mi.

  15. Ẹkún Jeremiah 3:21nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Síbẹ̀, èyí ni mo ní ní ọkàn àti nítorí náà ní mo nírètí.

  16. Ẹkún Jeremiah 3:22nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Nítorí ìfẹ́ Olúwa tí ó lágbára ni àwa kò fi ṣègbé, nítorí ti àánú rẹ kì í kùnà.

  17. Ẹkún Jeremiah 3:23nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Wọ́n jẹ́ ọ̀tún ní àárọ̀; títóbi ni òdodo rẹ̀.

  18. Ẹkún Jeremiah 3:24nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Mo wí fún ara mi, ìpín mi ni Olúwa; nítorí náà èmi yóò dúró dè ọ́.

  19. Ẹkún Jeremiah 3:25nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Dídára ni Olúwa fún àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ̀, sí àwọn tí ó ń wá a.

  20. Ẹkún Jeremiah 3:26nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Ó dára kí a ní sùúrù fún ìgbàlà Olúwa.

  21. Ẹkún Jeremiah 3:27nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Ó dára fún ènìyàn láti gbé àjàgà nígbà tí ó wà ní èwe.

  22. Ẹkún Jeremiah 3:28nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Jẹ́ kí ó jókòó ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, nítorí Olúwa ti fi fún un.

  23. Ẹkún Jeremiah 3:29nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Jẹ́ kí ó bo ojú rẹ̀ sínú eruku— ìrètí sì lè wà.

  24. Ẹkún Jeremiah 3:30nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Jẹ́ kí ó fi ẹ̀rẹ̀kẹ́ fún àwọn tí yóò gbá a, sì jẹ́ kí ó wà ní ìdójútì.

  25. Ẹkún Jeremiah 3:31nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Ènìyàn kò di ìtanù lọ́dọ̀ Olúwa títí láé.