- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 605–538 BC
The Babylonian Exile
Jerusalem falls and the temple burns; Ezekiel and Daniel minister among the exiles as Lamentations mourns the city's ruin.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Ẹkún Jeremiah 2:4nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Ó na ọfà rẹ̀ bí ọ̀tá; ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ sì múra. Bí ti ọ̀tá tí ó ti parun ó tú ìbínú rẹ̀ jáde bí iná sórí àgọ́ ọmọbìnrin Sioni.
- Ẹkún Jeremiah 2:5nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Olúwa dàbí ọ̀tá; ó gbé Israẹli mì. Ó ti gbé gbogbo ààfin rẹ̀ mì ó pa ibi gíga rẹ̀ run. Ó sọ ìmí ẹ̀dùn àti ìbànújẹ́ di púpọ̀ fún àwọn ọmọbìnrin Juda.
- Ẹkún Jeremiah 2:6nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Ó mú ìparun bá ibi mímọ́, ó pa ibi ìpàdé rẹ̀ run. Olúwa ti mú Sioni gbàgbé àjọ̀dún tí a yàn àti ọ̀sẹ̀ tí ó yàn; nínú ìbínú gbígbóná rẹ̀ ni ó run ọba àti olórí àlùfáà.
- Ẹkún Jeremiah 2:7nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Olúwa ti kọ̀ pẹpẹ rẹ̀ sílẹ̀ ó sì ti kọ̀ ibi mímọ́ rẹ̀. Ó sì fi lé ọ̀tá lọ́wọ́ àwọn odi ààfin rẹ̀; wọ́n sì kígbe ní ilé Olúwa gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ àpèjẹ tí a yàn.
- Ẹkún Jeremiah 2:8nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Olúwa pinnu láti fa ògiri tí ó yí ọmọbìnrin Sioni ya. Ó gbé wọn sórí òsùwọ̀n, kò sì fa ọwọ́ rẹ̀ padà kúrò nínú ìparun wọn. Ó mú kí ilé ìṣọ́ àti odi rẹ̀ ṣọ̀fọ̀ wọ́n ṣòfò papọ̀.
- Ẹkún Jeremiah 2:9nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ ti wọ inú ilẹ̀; òpó rẹ̀ ni ó wó tí ó sì ti bàjẹ́. Ọba àti ọmọ ọbakùnrin rẹ̀ wà ní ìgbèkùn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, kò sí òfin mọ́, àwọn wòlíì rẹ̀ kò rí ìran láti ọ̀dọ̀ Olúwa mọ́.
- Ẹkún Jeremiah 2:10nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Àwọn àgbàgbà ọmọbìnrin Sioni jókòó sílẹ̀ ní ìdákẹ́rọ́rọ́; wọ́n da eruku sí orí wọn wọ́n sì wọ aṣọ àkísà. Àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin Jerusalẹmu ti tẹrí wọn ba sí ilẹ̀.
- Ẹkún Jeremiah 2:11nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Ojú mi kọ̀ láti sọkún, mo ń jẹ ìrora nínú mi, mo tú ọkàn mi jáde sí ilẹ̀ nítorí a pa àwọn ènìyàn mí run, nítorí àwọn ọmọdé àti ọmọ ọwọ́ ń kú ní òpópó ìlú.
- Ẹkún Jeremiah 2:12nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Wọ́n wí fún àwọn ìyá wọn, “Níbo ni ọkà àti wáìnì wà?” Wò ó bí wọ́n ṣe ń kú lọ bí àwọn ọkùnrin tí a ṣe léṣe ní àwọn òpópónà ìlú, bí ayé wọn ṣe ń ṣòfò láti ọwọ́ ìyá wọn.
- Ẹkún Jeremiah 2:13nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Kí ni mo le sọ fún ọ? Pẹ̀lú kí ni mo lè fi ọ́ wé, ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu? Kí sì ni mo lè fi ọ́ wé, kí n lè tù ọ́ nínú, ìwọ wúńdíá obìnrin Sioni? Ọgbẹ́ rẹ jì bí Òkun. Ta ni yóò wò ọ́ sàn?
- Ẹkún Jeremiah 2:14nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Ìran àwọn wòlíì rẹ jẹ́ kìkì ẹ̀tàn láìní ìwọ̀n; wọn kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ hàn tí yóò mú ìgbèkùn kúrò fún ọ. Àwọn òrìṣà tí wọ́n fún ọ jẹ́ èké àti ìmúniṣìnà.
- Ẹkún Jeremiah 2:15nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Àwọn tí ó gba ọ̀nà ọ̀dọ̀ rẹ pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí; wọ́n kẹ́gàn wọ́n ju orí wọn sí ọmọbìnrin Jerusalẹmu: “Èyí ha ni ìlú tí à ń pè ní àṣepé ẹwà, ìdùnnú gbogbo ayé?”
- Ẹkún Jeremiah 2:16nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ la ẹnu wọn gbòòrò sí ọ; wọ́n kẹ́gàn, wọ́n sì payínkeke wọ́n wí pé, “A ti gbé e mì tán. Èyí ni ọjọ́ tí a ti ń retí; tí a sì wá láti rí.”
- Ẹkún Jeremiah 2:17nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Olúwa ti ṣe ohun tí ó pinnu; ó ti mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ, tí ó sì pàṣẹ ní ọjọ́ pípẹ́. Ó ti ṣí ọ ní ipò láì láàánú, ó fún ọ̀tá ní ìṣẹ́gun lórí rẹ, ó ti gbé ìwo àwọn ọ̀tá rẹ̀ ga.
- Ẹkún Jeremiah 2:18nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Ọkàn àwọn ènìyàn kígbe jáde sí Olúwa. Odi ọmọbìnrin Sioni, jẹ́ kí ẹkún rẹ̀ sàn bí odò ní ọ̀sán àti òru; má ṣe fi ara rẹ fún ìtura, ojú rẹ fún ìsinmi.
- Ẹkún Jeremiah 2:19nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Dìde, kígbe sókè ní àṣálẹ́, bí ìṣọ́ òru ti bẹ̀rẹ̀ tú ọkàn rẹ̀ jáde bí omi níwájú Olúwa. Gbé ọwọ́ yín sókè sí i nítorí ẹ̀mí àwọn èwe rẹ̀ tí ó ń kú lọ nítorí ebi ní gbogbo oríta òpópó.
- Ẹkún Jeremiah 2:20nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
“Wò ó, Olúwa, kí o sì rò ó. Ta ni ìwọ ti fìyà jẹ bí èyí. Ǹjẹ́ àwọn obìnrin yóò ha jẹ ọmọ wọn, àwọn ọmọ tí wọn ń ṣe ìtọ́jú fún? Ǹjẹ́ kí a pa olórí àlùfáà àti àwọn wòlíì ní ibi mímọ́ Olúwa?
- Ẹkún Jeremiah 2:21nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
“Ọmọdé àti àgbà ń sùn papọ̀ sínú eruku àwọn òpópó; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin mi ti ṣègbé nípa idà. Ìwọ pa wọ́n run ní ọjọ́ ìbínú rẹ, Ìwọ pa wọ́n láìní àánú.
- Ẹkún Jeremiah 2:22nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
“Bí ó ti ṣe ní ọjọ́ àsè, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe fi ẹ̀rù sí ẹ̀gbẹ́ mi. Ní ọjọ́ ìbínú Olúwa kò sí ẹni tí ó sálà tí ó sì yè; àwọn tí mo ti tọ́jú tí mo sì fẹ́ràn, ni ọ̀tá mi parun.”
- Ẹkún Jeremiah 3:1nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Èmi ni ọkùnrin tí ó rí ìpọ́njú pẹ̀lú ọ̀pá ìbínú rẹ.
- Ẹkún Jeremiah 3:2nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Ó ti lé mi jáde ó sì mú mi rìn nínú òkùnkùn ju ti ìmọ́lẹ̀.
- Ẹkún Jeremiah 3:3nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Nítòótọ́, ó ti yí ọwọ́ rẹ̀ padà sí mi síwájú àti síwájú sí i ní gbogbo ọjọ́.
- Ẹkún Jeremiah 3:4nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Ó jẹ́ kí àwọ̀ mi àti ẹran-ara mi gbó ó sì tún ṣẹ́ egungun mi.
- Ẹkún Jeremiah 3:5nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Ó ti fi mí sí ìgbèkùn, ó sì ti yí mi ká pẹ̀lú ìkorò àti làálàá.
- Ẹkún Jeremiah 3:6nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Ó mú mi gbé nínú òkùnkùn, bí ti àwọn tó ti kú fún ìgbà pípẹ́.