Skip to content

Tyre

52 verses · 2 known names

A tún mọ̀ ọ́n sí: Tyrus

33.2700, 35.1900 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Tyre

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ààlà náà sì tẹ̀ sí ìhà Rama, ó sì lọ sí ìlú olódi Tire, ó sì yà sí Hosa, ó sì jáde ní Òkun Ńlá ní ilẹ̀ Aksibu,

  2. Hiramu ọba Tire sì rán àwọn ìránṣẹ́ sí Dafidi, àti igi kedari, àti àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, àti àwọn tí ń gbẹ́ òkúta, wọ́n kọ́ ilé kan fún Dafidi.

  3. Wọ́n sì wá sí ìlú olódi Tire, àti sí gbogbo ìlú àwọn Hifi, àti ti àwọn ará Kenaani, wọ́n sì jáde lọ síhà gúúsù ti Juda, àní sí Beerṣeba.

  4. Nígbà tí Hiramu ọba Tire sì gbọ́ pé, a ti fi òróró yan Solomoni ní ọba ní ipò Dafidi baba rẹ̀, ó sì rán àwọn ikọ̀ rẹ̀ sí Solomoni, nítorí ó ti fẹ́ràn Dafidi ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo.

  5. Solomoni ọba ránṣẹ́ sí Tire, ó sì mú Hiramu wá,

  6. ẹni tí ìyá rẹ̀ jẹ́ opó láti inú ẹ̀yà Naftali àti tí baba rẹ̀ sì ṣe ará Tire, alágbẹ̀dẹ idẹ. Hiramu sì kún fún ọgbọ́n àti òye, àti ìmọ̀ láti ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ idẹ. Ó wá sọ́dọ̀ Solomoni ọba, ó sì ṣe gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún un.

  7. Solomoni ọba sì fi ogún ìlú ní Galili fún Hiramu ọba Tire, nítorí tí Hiramu ti bá a wá igi kedari àti igi firi àti wúrà gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìfẹ́ rẹ̀.

  8. Ṣùgbọ́n nígbà tí Hiramu sì jáde láti Tire lọ wo ìlú tí Solomoni fi fún un, inú rẹ̀ kò sì dùn sí wọn.

  9. Nísinsin yìí Hiramu àti ọba Tire rán oníṣẹ́ sí Dafidi, àti pẹ̀lú igi kedari pẹ̀lú àwọn ọ̀mọ̀lé àti gbẹ́nàgbẹ́nà láti kọ́ ààfin fún un.

  10. Solomoni rán iṣẹ́ yìí sí Hiramu ọba Tire: “Rán àwọn igi kedari sí mi gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe fún baba à mi Dafidi. Nígbà tí ó fi igi kedari ránṣẹ́ sí i láti kọ́ ààfin tí ó ń gbé.

  11. Hiramu ọba Tire fèsì padà nípasẹ̀ ìwé sí Solomoni: “Nítorí tí Olúwa fẹ́ràn àwọn ènìyàn rẹ̀, ó ti ṣe ọ́ ní ọba wọn.”

  12. Ọmọbìnrin kan nínú àwọn ọmọbìnrin Dani àti tí baba a rẹ̀ wá láti Tire tí ó gbọ́ngbọ́n àti ṣiṣẹ́ ní wúrà àti ní fàdákà, ní idẹ, ní irin, ní òkúta àti ní ìtì igi, ní èse-àlùkò, ní aláró, àti ní ọ̀gbọ̀ tí ó dára, àti òdòdó, láti gbẹ́ onírúurú ohun gbígbẹ́ pẹ̀lú, àti láti ṣe àwárí ìmọ̀ ẹ̀rọ irú ẹ̀yàkẹ́yà tí a ó fún un ṣe. Òun yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọlọ́gbọ́n rẹ̀, àti pẹ̀lú àwọn ọlọ́gbọ́n olúwa mi, Dafidi baba a rẹ.

  13. Ọmọbìnrin ọba Tire yóò wá pẹ̀lú ẹ̀bùn àwọn ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yóò máa wá ojúrere rẹ̀.

  14. Gebali, Ammoni àti Amaleki, Filistia, pẹ̀lú àwọn ènìyàn Tire.

  15. “Èmi ó dárúkọ Rahabu àti Babeli láàrín àwọn tí ó jẹ́wọ́ mi: Filistia pẹ̀lú, àti Tire, pẹ̀lú Kuṣi, yóò sọ pé, ‘Èyí ni a bí ní Sioni.’ ”

  16. Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Tire. Hu, ìwọ ọkọ̀ ojú omi Tarṣiṣi! Nítorí a ti pa Tire run láìsí ilé tàbí èbúté. Láti ilẹ̀ Saipurọsi ni ọ̀rọ̀ ti wá sọ́dọ̀ wọn.

  17. Nígbà tí ọ̀rọ̀ bá dé Ejibiti, wọn yóò wà ní ìpayínkeke nípa ìròyìn láti Tire.

  18. Ta ló gbèrò èyí sí Tire, ìlú aládé, àwọn oníṣòwò ẹni tí ó jẹ́ ọmọ-aládé tí àwọn oníṣòwò wọ́n jẹ́ ìlúmọ̀míká ní orílẹ̀ ayé?

  19. Ní àkókò náà a ó gbàgbé Tire fún àádọ́rin ọdún, ọjọ́ ayé ọba kan. Ṣùgbọ́n ní òpin àádọ́rin ọdún wọ̀nyí, yóò ṣẹlẹ̀ sí Tire gẹ́gẹ́ bí orin àgbèrè:

  20. Ní òpin àádọ́rin ọdún náà, Olúwa yóò bá Tire jà. Òun yóò sì padà sí àyálò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí panṣágà, yóò sì máa ṣe òwò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ọba tí ó wà ní ilẹ̀ ayé.

  21. gbogbo àwọn ọba Tire àti Sidoni; gbogbo àwọn ọba erékùṣù wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ ní ìkọjá Òkun.

  22. Kí o rán ọ̀rọ̀ sí ọba ti Edomu, Moabu, Ammoni, Tire àti Sidoni láti ọwọ́ àwọn ikọ̀ tí ó wá sí Jerusalẹmu sọ́dọ̀ Sedekiah ọba Juda.

  23. Nítorí tí ọjọ́ náà ti pé láti pa àwọn Filistini run, kí a sì mú àwọn tí ó là tí ó lè ran Tire àti Sidoni lọ́wọ́ kúrò. Olúwa ti ṣetán láti pa Filistini run, àwọn tí ó kù ní agbègbè Kafitori.

  24. “Ọmọ ènìyàn, nítorí pé Tire sọ nípa Jerusalẹmu pé, ‘Háà! A fọ́ èyí tí í ṣe bodè àwọn orílẹ̀-èdè, a yí i padà sí mi, èmi yóò di kíkún, òun yóò sì di ahoro,’

  25. nítorí náà, báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí, kíyèsi i, èmí dojúkọ ọ́ ìwọ tire, Èmi yóò sì jẹ́ kí Orílẹ̀-èdè púpọ̀ dìde sí ọ, gẹ́gẹ́ bí Òkun tí ru sókè.