Skip to content

Dan

63 ẹsẹ · 15 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Dan

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Rakeli sì wí pé, “Ọlọ́run ti ṣe ìdájọ́ mi; ó sì ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi, ó sì fún mi ni ọmọkùnrin kan.” Nítorí ìdí èyí ni ó ṣe pe orúkọ rẹ̀ ní Dani.

  2. Àwọn ọmọ Biliha ìránṣẹ́bìnrin Rakeli: Dani àti Naftali.

  3. Àwọn ọmọ Dani: Huṣimu.

  4. “Dani yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yà Israẹli.

  5. Dani yóò jẹ́ ejò ni pópónà àti paramọ́lẹ̀ ní ẹ̀bá ọ̀nà, tí ó bu ẹṣin jẹ ní ẹsẹ̀, kí ẹni tí ń gùn ún bá à le è ṣubú sẹ́yìn.

  6. Dani àti Naftali; Gadi àti Aṣeri.

  7. Síwájú sí i, èmi ti yan Oholiabu ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀yà Dani, láti ràn án lọ́wọ́. “Bákan náà, Èmi ti fi ọgbọ́n fún gbogbo àwọn oníṣẹ́-ọnà láti ṣe ohun gbogbo tí mo pàṣẹ fún ọ:

  8. Ó sì fún òun àti Oholiabu ọmọ Ahisamaki ti ẹ̀yà Dani, ni agbára láti kọ́ àwọn tókù.

  9. Pẹ̀lú rẹ̀ ni Oholiabu ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀yà Dani: alágbẹ̀dẹ, àti oníṣẹ́-ọnà àti oníṣọ̀nà tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe ní aṣọ aláró àti elése àlùkò àti òdòdó àti ọ̀gbọ̀ dáradára.)

  10. Ọmọkùnrin arábìnrin Israẹli náà sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Olúwa pẹ̀lú èpè, wọ́n sì mú un tọ Mose wá. (Orúkọ ìyá rẹ̀ ní Ṣelomiti, ọmọbìnrin Debiri, ti ẹ̀yà Dani.)

  11. Láti ọ̀dọ̀ Dani, Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai.

  12. Láti ìran Dani, gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.

  13. Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Dani jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélọ́gbọ̀n ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (62,700).

  14. Ní ìhà àríwá: ni ìpín Dani yóò pa ibùdó sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olórí Dani ni Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai.

  15. Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Dani jẹ́ ẹgbàá méjìdínlọ́gọ̀rin ó lé ẹgbẹ̀jọ (157,600). Àwọn ni yóò jáde kẹ́yìn lábẹ́ ọ̀págun wọn.

  16. Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai, olórí àwọn ọmọ Dani ni ó mú ọrẹ tirẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹwàá.

  17. Lákòótan, àwọn ọmọ-ogun tó ń mójútó ẹ̀yìn ló tún kàn, àwọn ni ìpín ti ibùdó Dani lábẹ́ ọ̀págun wọn. Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai ni ọ̀gágun wọn.

  18. láti inú ẹ̀yà Dani, Ammieli ọmọ Gemalli;

  19. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Dani gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Ṣuhamu, ìdílé àwọn ọmọ Ṣuhamu. Wọ̀nyí ni ìdílé Dani gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn.

  20. Bukki ọmọ Jogli, láti ẹ̀yà olórí àwọn ọmọ Dani;

  21. Àwọn ẹ̀yà yìí yóò dúró lórí òkè Ebali láti gé ègún: Reubeni, Gadi, àti Aṣeri, àti Sebuluni, Dani, àti Naftali.

  22. Ní ti Dani ó wí pé, “Ọmọ kìnnìún ni Dani, tí ń fò láti Baṣani wá.”

  23. Nígbà náà ni Mose gun òkè Nebo láti pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu sí orí Pisga tí ó dojúkọ Jeriko. Níbẹ̀ ni Olúwa ti fi gbogbo ilẹ̀ hàn án láti Gileadi dé Dani,

  24. Ìbò kéje jáde fún ẹ̀yà Dani, ní agbo ilé ní agbo ilé.

  25. (Ṣùgbọ́n àwọn ará Dani ní ìṣòro láti gba ilẹ̀ ìní wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gòkè lọ, wọ́n sì kọlu Leṣemu, wọ́n sì gbà á, wọ́n sì fi idà kọlù ú, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀. Wọ́n sì ń gbé ní Leṣemu, wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Dani orúkọ baba ńlá wọn).