Fò sí àkóónú

circa 605–538 BC

The Babylonian Exile

Jerusalem falls and the temple burns; Ezekiel and Daniel minister among the exiles as Lamentations mourns the city's ruin.

1,784 ẹsẹ · 3 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ẹkún Jeremiah 3:32nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Lóòtítọ́ ó mú ìbànújẹ́ wá, yóò fi àánú hàn, nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ̀.

  2. Ẹkún Jeremiah 3:33nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Nítorí kò mọ̀ ọ́n mọ̀ mú ìpọ́njú wá tàbí ìrora wá fún ọmọ ènìyàn.

  3. Ẹkún Jeremiah 3:34nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Láti tẹ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n ní ilẹ̀ náà.

  4. Ẹkún Jeremiah 3:35nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Láti ṣẹ́ ọmọ ènìyàn fún ẹ̀tọ́ rẹ̀ níwájú Ọ̀gá-ògo jùlọ,

  5. Ẹkún Jeremiah 3:36nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    láti yí ìdájọ́ ènìyàn padà, ǹjẹ́ Olúwa kò rí ohun bẹ́ẹ̀.

  6. Ẹkún Jeremiah 3:37nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Ta ni yóò sọ̀rọ̀ tí yóò rí bẹ́ẹ̀ tí Olúwa kò bá fi àṣẹ sí i.

  7. Ẹkún Jeremiah 3:38nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Ǹjẹ́ kì í ṣe láti ẹnu Ọ̀gá-ògo jùlọ ni rere àti búburú tí ń wá?

  8. Ẹkún Jeremiah 3:39nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Kí ló dé tí ẹ̀dá alààyè ṣe ń kùn nígbà tí ó bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀?

  9. Ẹkún Jeremiah 3:40nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Ẹ jẹ́ kí a yẹ ọ̀nà wa, kí a sì dán an wò, kí a sì tọ Olúwa lọ.

  10. Ẹkún Jeremiah 3:41nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Ẹ jẹ́ kí a gbé ọkàn àti ọwọ́ wa sókè sí Ọlọ́run ní ọ̀run, kí a wí pé,

  11. Ẹkún Jeremiah 3:42nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    “Àwa ti ṣẹ̀ a sì ti ṣọ̀tẹ̀ ìwọ kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá.

  12. Ẹkún Jeremiah 3:43nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    “Ìwọ fi ìbínú bo ara rẹ ìwọ sì ń lépa wa; ìwọ ń parun láìsí àánú.

  13. Ẹkún Jeremiah 3:44nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Ìwọ ti fi àwọsánmọ̀ bo ara rẹ pé kí àdúrà wa má ba à dé ọ̀dọ̀ rẹ.

  14. Ẹkún Jeremiah 3:45nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Ó ti sọ wá di èérí àti ààtàn láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo.

  15. Ẹkún Jeremiah 3:46nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    “Gbogbo àwọn ọ̀tá wa ti la ẹnu wọn gbòòrò sí wa.

  16. Ẹkún Jeremiah 3:47nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Àwa ti jìyà àti ìparun, nínú ìbẹ̀rù àti ewu.”

  17. Ẹkún Jeremiah 3:48nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Omijé ń sàn ní ojú mi bí odò nítorí a pa àwọn ènìyàn mi run.

  18. Ẹkún Jeremiah 3:49nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Ojú mi kò dá fún omijé, láì sinmi,

  19. Ẹkún Jeremiah 3:50nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    títí ìgbà tí Olúwa yóò síjú wolẹ̀ láti òkè ọ̀run tí yóò sì rí i.

  20. Ẹkún Jeremiah 3:51nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Ohun tí mo rí mú ìbẹ̀rù wá ọkàn mi nítorí gbogbo àwọn obìnrin ìlú mi.

  21. Ẹkún Jeremiah 3:52nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìnídìí dẹ mí bí ẹyẹ.

  22. Ẹkún Jeremiah 3:53nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Wọ́n gbìyànjú láti mú òpin dé bá ayé mi nínú ihò wọ́n sì ju òkúta lù mí.

  23. Ẹkún Jeremiah 3:54nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Orí mi kún fún omi, mo sì rò pé ìgbẹ̀yìn dé.

  24. Ẹkún Jeremiah 3:55nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Mo pe orúkọ rẹ, Olúwa, láti ọ̀gbun ìsàlẹ̀ ihò.

  25. Ẹkún Jeremiah 3:56nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Ìwọ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi, “Má ṣe di etí rẹ sí igbe ẹ̀bẹ̀ mi fún ìtura.”