Fò sí àkóónú

circa 605–538 BC

The Babylonian Exile

Jerusalem falls and the temple burns; Ezekiel and Daniel minister among the exiles as Lamentations mourns the city's ruin.

1,784 ẹsẹ · 3 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Daniẹli 12:5nǹkan bí 534 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà, ni èmi Daniẹli, wò, ní iwájú mi àwọn méjì mìíràn dúró, ọ̀kan dúró sí apá ìhín ní etí bèbè odò ẹnìkan náà ní apá òdìkejì ọ̀hún etí i bèbè.

  2. Daniẹli 12:6nǹkan bí 534 ṣáájú Kristi

    Ọ̀kan lára wọn sọ fún ọkùnrin tí ó wọ aṣọ àlà, ẹni tí ó wà lórí omi odò pé, “Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó kí àwọn nǹkan ìyanu wọ̀nyí tó wá sí ìmúṣẹ?”

  3. Daniẹli 12:7nǹkan bí 534 ṣáájú Kristi

    Ọkùnrin tí ó wọ aṣọ àlà, ẹni tí ó wà lórí omi odò, gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti ọwọ́ òsì rẹ̀, mo gbọ́ tí ó fi ẹni tí ó wà títí láé búra, ó sọ wí pé, “Yóò ṣe ní àkókò kan, àkókò méjì àti ààbọ̀. Nígbà tí agbára àwọn ẹni mímọ́ yóò ti fọ́ tán pátápátá, gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò sì parí.”

  4. Daniẹli 12:8nǹkan bí 534 ṣáájú Kristi

    Èmi gbọ́, ṣùgbọ́n kò yé mi. Nígbà náà ni mo béèrè pé, “Olúwa mi, kí ni yóò jẹ́ àbábọ̀ àwọn nǹkan wọ̀nyí?”

  5. Daniẹli 12:9nǹkan bí 534 ṣáájú Kristi

    Ó sì dáhùn pé, “Máa lọ ní ọ̀nà rẹ, Daniẹli nítorí tí a ti pa ọ̀rọ̀ náà dé, a sì ti fi èdìdì dì í di ìgbà ìkẹyìn.

  6. Daniẹli 12:10nǹkan bí 534 ṣáájú Kristi

    Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni a ó fọ̀ mọ́, wọn yóò wà láìlábàwọ́n, a ó sì tún wọn ṣe, ṣùgbọ́n àwọn ẹni búburú yóò máa ṣe búburú lọ, kò sí ẹni búburú tí òye yóò yé ṣùgbọ́n òye yóò yé àwọn ọlọ́gbọ́n.

  7. Daniẹli 12:11nǹkan bí 534 ṣáájú Kristi

    “Láti àkókò tí a ó mú ẹbọ ojoojúmọ́ kúrò, tí a ó sì gbé ìríra tí ó ń fa ìsọdahoro kalẹ̀ yóò sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún àti igba lé àádọ́rùn-ún ọjọ́ (1,290).

  8. Daniẹli 12:12nǹkan bí 534 ṣáájú Kristi

    Ìbùkún ni fún ẹni tí ó dúró, ti ó sì di òpin ẹgbẹ̀rún àti ọ̀ọ́dúnrún lé àrùndínlógójì (1,335) ọjọ́.

  9. Daniẹli 12:13nǹkan bí 534 ṣáájú Kristi

    “Ṣùgbọ́n ìwọ, máa lọ ní ọ̀nà rẹ, títí di òpin. Ìwọ yóò sinmi, àti ní òpin ọjọ́ ìwọ yóò dìde láti gba èrè rẹ.”