Fò sí àkóónú

circa 605–538 BC

The Babylonian Exile

Jerusalem falls and the temple burns; Ezekiel and Daniel minister among the exiles as Lamentations mourns the city's ruin.

1,784 ẹsẹ · 3 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ẹkún Jeremiah 5:19nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Ìwọ, Olúwa, jẹ ọba títí láé; ìjọba rẹ dúró láti ìran kan dé ìran mìíràn.

  2. Ẹkún Jeremiah 5:20nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Kí ló dé tí o ń gbàgbé wa ní gbogbo ìgbà? Kí ló dé tí o fi kọ̀ wá sílẹ̀ fún ọjọ́ pípẹ́?

  3. Ẹkún Jeremiah 5:21nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Mú wa padà sí ọ̀dọ̀ rẹ, Olúwa, kí àwa kí ó le padà; mú ọjọ́ wa di tuntun bí ìgbàanì,

  4. Ẹkún Jeremiah 5:22nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    àyàfi tí o bá ti kọ̀ wá sílẹ̀ pátápátá tí ìbínú rẹ sí wa sì kọjá ìwọ̀n.

  5. Esekiẹli 1:1nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Ní ọjọ́ karùn-ún, oṣù kẹrin tí mo di ọmọ ọgbọ̀n ọdún tí mo wà láàrín àwọn ìgbèkùn ní etí odò Kebari, àwọn ọ̀run ṣí sílẹ̀, mo sì rí ìran Ọlọ́run.

  6. Esekiẹli 1:2nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Ní ọjọ́ karùn-ún oṣù—tí ó jẹ́ ọdún karùn-ún ìgbèkùn ọba Jehoiakini—

  7. Esekiẹli 1:3nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ àlùfáà Esekiẹli, ọmọ Busii wá, létí odò Kebari ni ilẹ̀ àwọn ará Babeli. Níbẹ̀ ni ọwọ́ Olúwa ti wà lára rẹ̀.

  8. Esekiẹli 1:4nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Mo wò, mo sì rí ìjì tó ń jà bọ̀ láti ìhà àríwá ìkùùkuu tó nípọn pẹ̀lú mọ̀nàmọ́ná ti n bù yẹ̀rì pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ rokoṣo tó yí i ká. Àárín iná náà rí bí ìgbà tí irin bá ń bẹ nínú iná,

  9. Esekiẹli 1:5nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    àti láàrín iná náà ni ohun tó dàbí ẹ̀dá alààyè mẹ́rin wà. Ìrísí wọn jẹ́ ti ènìyàn,

  10. Esekiẹli 1:6nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    ṣùgbọ́n ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ní ojú mẹ́rin àti ìyẹ́ apá mẹ́rin.

  11. Esekiẹli 1:7nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Ẹsẹ̀ wọn sì tọ́; àtẹ́lẹsẹ̀ wọn sì rí bí ti ọmọ màlúù, wọ́n sì tàn bí awọ idẹ dídán.

  12. Esekiẹli 1:8nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Ní abẹ́ ìyẹ́ wọn ní ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọn ní ọwọ́ ènìyàn. Gbogbo àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní ojú àti àwọn ìyẹ́,

  13. Esekiẹli 1:9nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    ìyẹ́ wọn kan ara wọn. Bẹ́ẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn kò padà lọ́nà ibi tí ó ń lọ; ṣùgbọ́n wọ́n ń lọ tààrà ni.

  14. Esekiẹli 1:10nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Báyìí ni ìrísí ojú àwọn ẹ̀dá alààyè yìí: ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ojú ènìyàn, ní apá ọ̀tún wọn, wọ́n ní ojú kìnnìún ní ìhà ọ̀tún, wọ́n ní ojú màlúù ní ìhà òsì, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọ́n sì tún ní ojú ẹyẹ idì.

  15. Esekiẹli 1:11nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Báyìí ni àpèjúwe ojú wọ́n. Ìyẹ́ wọn gbé sókè; ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ìyẹ́ méjì, ìyẹ́ ọ̀kan sì kan ti èkejì ni ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́, ìyẹ́ méjì tó sì tún bo ara wọn.

  16. Esekiẹli 1:12nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Olúkúlùkù wọn ń lọ tààrà. Níbikíbi tí èmi bá ń lọ, ni àwọn náà ń lọ, láì wẹ̀yìn bí wọ́n ti ń lọ.

  17. Esekiẹli 1:13nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Ìrísí àwọn ẹ̀dá alààyè yìí dàbí ẹyin iná tí ń jó tàbí bí i iná fìtílà. Iná tó ń jó ń lọ sókè lọ sódò láàrín àwọn ẹ̀dá alààyè; iná yìí mọ́lẹ̀ rokoṣo, ó sì ń bù yẹ̀rì yẹ̀rì jáde lára rẹ̀.

  18. Esekiẹli 1:14nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Àwọn ẹ̀dá alààyè yìí sì ń sáré lọ sókè lọ sódò bí i ìtànṣán àrá.

  19. Esekiẹli 1:15nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Bí mo ti ń wo àwọn ẹ̀dá alààyè yìí, mo rí kẹ̀kẹ́ ní ilẹ̀ ni ẹ̀gbẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹ̀dá alààyè wọ̀nyí pẹ̀lú ojú rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin.

  20. Esekiẹli 1:16nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Àpèjúwe àti ìrísí àwọn kẹ̀kẹ́ náà nìyìí: kẹ̀kẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rí bákan náà, wọ́n sì ń tàn yinrin yinrin bí i kirisoleti, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn kẹ̀kẹ́ yìí rí bí i ìgbà tí a fi kẹ̀kẹ́ bọ kẹ̀kẹ́ nínú.

  21. Esekiẹli 1:17nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Àwọn kẹ̀kẹ́ yìí ń yí bí wọ́n ti ń yí, wọ́n ń lọ tààrà sí ibi tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹ̀dá alààyè kọjú sí, kẹ̀kẹ́ wọn kò sì yapa bí àwọn ẹ̀dá náà ti n lọ.

  22. Esekiẹli 1:18nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Àwọn ríìmù wọ́n ga, wọ́n sì ba ni lẹ́rù, àwọn ríìmù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì jẹ́ kìkìdá ojú yíká.

  23. Esekiẹli 1:19nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Bí àwọn ẹ̀dá bá ń rìn, kẹ̀kẹ́ ẹ̀gbẹ́ wọn náà yóò rìn, bí wọ́n fò sókè, kẹ̀kẹ́ náà yóò fò sókè.

  24. Esekiẹli 1:20nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Ibikíbi tí ẹ̀mí bá ń lọ, kẹ̀kẹ́ wọn yóò sì bá wọn lọ, nítorí pé ẹ̀mí àwọn ẹ̀dá alààyè yìí wà nínú kẹ̀kẹ́ wọn.

  25. Esekiẹli 1:21nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Bí àwọn ẹ̀dá yìí bá ń lọ, kẹ̀kẹ́ náà yóò lọ; bí wọ́n bá dúró jẹ́ẹ́ kẹ̀kẹ́ náà yóò dúró jẹ́ẹ́, bẹ́ẹ̀ sì ni bí àwọn ẹ̀dá yìí bá dìde nílẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ yìí yóò dìde pẹ̀lú wọn, nítorí pé ẹ̀mí ẹ̀dá alààyè wọ̀nyí wà nínú àwọn kẹ̀kẹ́.