Fò sí àkóónú

circa 605–538 BC

The Babylonian Exile

Jerusalem falls and the temple burns; Ezekiel and Daniel minister among the exiles as Lamentations mourns the city's ruin.

1,784 ẹsẹ · 3 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Esekiẹli 1:22nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Ohun tí ó dàbí òfúrufú ràn bo orí àwọn ẹ̀dá alààyè wọ̀nyí, ó ń tàn yinrin yinrin bí i yìnyín, ó sì ba ni lẹ́rù.

  2. Esekiẹli 1:23nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Ìyẹ́ wọn sì tọ́ lábẹ́ òfúrufú, èkínní sí èkejì, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ní ìyẹ́ méjì méjì tí ó bo ara wọn.

  3. Esekiẹli 1:24nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí àwọn ẹ̀dá náà gbéra, mo gbọ́ ariwo ìyẹ́ wọn tó bolẹ̀ bí i ríru omi, bí i ohùn Olódùmarè, bí i híhó àwọn jagunjagun. Nígbà tí wọ́n dúró jẹ́ẹ́, wọ́n sì rẹ ìyẹ́ wọn sílẹ̀.

  4. Esekiẹli 1:25nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Bí wọ́n ṣe dúró tí wọ́n sì rẹ ìyẹ́ wọn sílẹ̀, ohùn kan jáde láti inú òfúrufú tó rán bò wọ́n.

  5. Esekiẹli 1:26nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Lókè àwọ̀ òfúrufú tó borí wọn yìí ni ohun tí ó ní ìrísí ìtẹ́. Ìtẹ́ náà dàbí òkúta safire, lókè ní orí ìtẹ́ ní ohun tó dàbí ènìyàn wà.

  6. Esekiẹli 1:27nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Láti ibi ìbàdí ènìyàn náà dé òkè, o dàbí irin tí ń kọ yànrànyànràn. O dàbí pe kìkì iná ni, láti ibi ìbàdí rẹ dé ìsàlẹ̀ dàbí iná tó mọ́lẹ̀ yí i ká.

  7. Esekiẹli 1:28nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Ìmọ́lẹ̀ tó yí i ká yìí dàbí ìrísí òṣùmàrè tó yọ nínú àwọsánmọ̀ ní ọjọ́ òjò, bẹ́ẹ̀ ni ìmọ́lẹ̀ tò yí i ká. Báyìí ni ìrísí ògo Olúwa. Nígbà tí mo rí i, mo dojúbolẹ̀, mo sì gbọ́ ohùn ẹnìkan tó ń sọ̀rọ̀.

  8. Esekiẹli 2:1nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Ó sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, dìde dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ. Èmi yóò bá ọ sọ̀rọ̀.”

  9. Esekiẹli 2:2nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Bí ó ṣe ń sọ̀rọ̀, ẹ̀mí sì wọ inú mi ó mú mi dúró lórí ẹsẹ̀ mi, mo sì ń gbọ́ tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀.

  10. Esekiẹli 2:3nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Ó sọ pé, “Ọmọ ènìyàn, mo ń rán ọ sí àwọn ọmọ Israẹli, sí ọlọ̀tẹ̀ orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi; àwọn àti baba ńlá wọn ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi títí di òní olónìí.

  11. Esekiẹli 2:4nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Àwọn ènìyàn tí mo ń rán ọ sí jẹ́ aláìgbọ́ràn àti ọlọ́kàn líle. Sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí.’

  12. Esekiẹli 2:5nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Bí wọn fetísílẹ̀ tàbí wọn kò fetísílẹ̀ nítorí pé wọ́n ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n—wọn yóò mọ̀ pé wòlíì kan wà láàrín wọn.

  13. Esekiẹli 2:6nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Àti ìwọ, ọmọ ènìyàn, má ṣe bẹ̀rù wọn tàbí ọ̀rọ̀ ẹnu wọn. Má ṣe bẹ̀rù, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òṣùṣú àti ẹ̀gún yí ọ ká, tí o sì ń gbé àárín àwọn àkéekèe. Má ṣe bẹ̀rù ohun tí wọ́n ń sọ tàbí bẹ̀rù wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ̀tẹ̀ ìdílé ni wọ́n.

  14. Esekiẹli 2:7nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Ìwọ gbọdọ̀ sọ ọ̀rọ̀ mi fún wọn, bí wọ́n gbọ́ bí wọn kọ̀ láti gbọ́ torí pé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.

  15. Esekiẹli 2:8nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n ìwọ, ọmọ ènìyàn, gbọ́ ohun tí mo ń sọ fún ọ. Má ṣe ṣọ̀tẹ̀ bí i ti ìdílé ọlọ́tẹ̀; la ẹnu rẹ kí o sì jẹ ohun tí mo fún ọ.”

  16. Esekiẹli 2:9nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Mo sì wò, mo sì rí ọwọ́ kan tí a nà sí mi. Ìwé kíká sì wà níbẹ̀,

  17. Esekiẹli 2:10nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    ó sì tú ìwé náà fún mi. Ní ojú àti ẹ̀yìn ìwé náà ni a kọ ìpohùnréré ẹkún, ọ̀fọ̀ àti ègún sí.

  18. Esekiẹli 3:1nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Síwájú sí i, ó sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, jẹ ohun tí ó wà níwájú rẹ, jẹ ìwé kíká yìí; kí o sì lọ fi bá ilé Israẹli sọ̀rọ̀.”

  19. Esekiẹli 3:2nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Mo sì ya ẹnu mi, ó sì mú mi jẹ ìwé kíká náà.

  20. Esekiẹli 3:3nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Ó tún sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, jẹ ìwé kíká tí mo fún ọ yìí, fi bọ́ inú àti ikùn rẹ.” Nígbà náà ni mo jẹ ẹ́, dídùn rẹ̀ dàbí oyin ní ẹnu mi.

  21. Esekiẹli 3:4nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Ó sì tún sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, lọ ni ìsinsin yìí bá mi sọ ọ̀rọ̀ mi fún ilé Israẹli.

  22. Esekiẹli 3:5nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    A kò rán ọ sí àwọn tó ń sọ èdè àjèjì tàbí tí èdè wọn ṣòro láti gbọ́, ṣùgbọ́n orílẹ̀-èdè Israẹli ni mo rán ọ sí

  23. Esekiẹli 3:6nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    kì í ṣe sí ọ̀pọ̀ ènìyàn tó ń sọ àjèjì èdè tàbí tí èdè wọn ṣòro láti gbọ́, àwọn tí ọ̀rọ̀ wọn le fún ọ láti gbọ́ yé. Dájúdájú bí mo bá rán ọ sí wọn, wọn ìbá sì fetísílẹ̀ sí ọ.

  24. Esekiẹli 3:7nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n ilé Israẹli kò fẹ́ gbọ́ tìrẹ nítorí pé wọn kò fẹ́ láti gbọ́ tèmi, torí pé aláìgbọ́ràn àti ọlọ́kàn líle ni gbogbo ilé Israẹli.

  25. Esekiẹli 3:8nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n bí i tiwọn lèmi náà yóò ṣe jẹ́ kí ojú àti ọkàn rẹ le.