Fò sí àkóónú

circa 605–538 BC

The Babylonian Exile

Jerusalem falls and the temple burns; Ezekiel and Daniel minister among the exiles as Lamentations mourns the city's ruin.

1,784 ẹsẹ · 3 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Esekiẹli 4:7nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Ìwọ dojúkọ ìgbógunti Jerusalẹmu, na ọwọ́ rẹ sí i, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìlú náà.

  2. Esekiẹli 4:8nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò dè ọ́ ní okùn dé bi pé ìwọ kò ní í le yírapadà láti ìhà ọ̀tún sí ìhà òsì títí tí ọjọ́ ìgbóguntì rẹ yóò fi pé.

  3. Esekiẹli 4:9nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    “Mú alikama, ọkà bàbà àti barle, erèé àti lẹntili, jéró àti ẹwẹ; fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe àkàrà tí ìwọ yóò máa jẹ nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀ fún irinwó ọjọ́ ó dín mẹ́wàá (390).

  4. Esekiẹli 4:10nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Wọn òsùwọ̀n ogún ṣékélì oúnjẹ tí ìwọ yóò máa jẹ lójoojúmọ́ kí o sì máa jẹ ẹ́ ní àkókò tí a ti yà sọ́tọ̀.

  5. Esekiẹli 4:11nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Bákan náà, wọn ìdámẹ́fà omi, kí ìwọ ó sì máa mú ní àkókò tí a yà sọ́tọ̀.

  6. Esekiẹli 4:12nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Ìwọ yóò sì jẹ ẹ́ bí àkàrà barle; dín in ní ojú àwọn ènìyàn, ìgbẹ́ ènìyàn ni kí o fi dáná rẹ.”

  7. Esekiẹli 4:13nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Olúwa sọ pé, “Báyìí ni àwọn ọmọ Israẹli yóò jẹ oúnjẹ àìmọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè tí èmi yóò lé wọn lọ.”

  8. Esekiẹli 4:14nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni mo wí pé, “Háà! Kò rí bẹ́ẹ̀ Olúwa Olódùmarè! Láti ìgbà èwe mi di ìsinsin yìí èmi kò tí ì sọ ara mi di aláìmọ́ rí. Èmi kò tí ì jẹ ohun tó kú fúnra rẹ̀ tàbí èyí tí ẹranko búburú fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Bẹ́ẹ̀ ni ẹran àìmọ́ kan kò tí ì wọ ẹnu mi rí.”

  9. Esekiẹli 4:15nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ló wí fún mi pé, “Wò ó, Èmi ó fún ọ ní ìgbẹ́ màlúù dípò ìgbẹ́ ènìyàn. Èmi yóò mú ki ó dín àkàrà rẹ lórí ìgbẹ́ màlúù dípò ìgbẹ́ ènìyàn.”

  10. Esekiẹli 4:16nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    Ó sì tún sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, èmi yóò dáwọ́ ìpèsè oúnjẹ dúró ní Jerusalẹmu. Ní pípín ni àwọn ènìyàn yóò máa pín oúnjẹ jẹ pẹ̀lú ìfọkànsọ́nà bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni wọn yóò máa mu omi pẹ̀lú ìdààmú,

  11. Esekiẹli 4:17nǹkan bí 595 ṣáájú Kristi

    nítorí pé oúnjẹ àti omi yóò wọ́n. Wọn yóò máa wo ara wọn pẹ̀lú ìyanu, èmi yóò sì jẹ́ kí wọ́n ṣọ̀fọ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

  12. Esekiẹli 5:1nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    “Báyìí, ọmọ ènìyàn, mú ìdá tí ó mú kí o sì fi ṣe abẹ ìfárí onígbàjámọ̀, kí o fi fá irun orí àti irùngbọ̀n rẹ. Fi irun yìí sórí ìwọ̀n kí o sì pín in.

  13. Esekiẹli 5:2nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí ọjọ́ ìgbóguntì bá parí, sun ìdákan nínú ìdámẹ́ta irun yìí níná láàrín ìlú. Mú ìdákan nínú mẹ́ta kí o fi idà bù ú káàkiri ìlú. Kí o sì tú ìdákan yòókù ká sínú afẹ́fẹ́. Nítorí pé pẹ̀lú idà ni èmi yóò máa lé wọn ká.

  14. Esekiẹli 5:3nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n mú díẹ̀ nínú irun yìí kí o sì ta á mọ́ etí aṣọ rẹ.

  15. Esekiẹli 5:4nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Tún ju díẹ̀ nínú irun yìí sínú iná, kí o sun ún níná. Torí pé láti ibẹ̀ ni iná yóò ti jáde lọ sí gbogbo ilé Israẹli.

  16. Esekiẹli 5:5nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    “Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èyí ní Jerusalẹmu, tí mo gbé kalẹ̀ sí àárín àwọn Orílẹ̀-èdè, pẹ̀lú àwọn ìlú gbogbo tí o yí i ká.

  17. Esekiẹli 5:6nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Síbẹ̀ nínú ìwà búburú rẹ ó ti ṣọ̀tẹ̀ si òfin àti ìlànà mi ju àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ilẹ̀ tó yí i ká lọ. Ó ti kọ òfin mi sílẹ̀, o kò sì pa ìlànà mi mọ́.

  18. Esekiẹli 5:7nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    “Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Nítorí pé ẹ̀yin ti ṣe àìgbọ́ràn ju àwọn orílẹ̀-èdè tó yí yín ká lọ, tí ẹ kò sì tẹ̀lé ìlànà mi tàbí kí o pa òfin mi mọ́. O kò tilẹ̀ túnṣe dáradára tó àwọn orílẹ̀-èdè tó yí ọ ká.

  19. Esekiẹli 5:8nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    “Nítorí náà báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmi gan an lòdì sí ọ, Jerusalẹmu, èmi yóò sì jẹ ọ́ ní yà lójú àwọn orílẹ̀-èdè tó yí ọ ká.

  20. Esekiẹli 5:9nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Nítorí gbogbo ohun ìríra rẹ, èmi yóò ṣe ohun tí n kò tí ì ṣe rí láàrín rẹ àti èyí tí n kò ní í ṣe irú rẹ̀ mọ́.

  21. Esekiẹli 5:10nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà láàrín rẹ àwọn baba yóò máa jẹ ọmọ wọn, àwọn ọmọ náà yóò máa jẹ baba wọn. Èmi yóò jẹ ọ́ ní yà, èmi yóò sì tú àwọn tó bá ṣẹ́kù ká sínú ẹ̀fúùfù.

  22. Esekiẹli 5:11nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà, Olúwa Olódùmarè wí pé, bí mo ṣe wà láààyè, nítorí pé ìwọ ti sọ ibi mímọ́ mi di àìmọ́ pẹ̀lú àwọn àwòrán ẹ̀gbin àti àwọn ohun ìríra rẹ, èmi yóò mú ojúrere mi kúrò lára rẹ, èmi kò ní í da ọ sí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò wò ọ́ pẹ̀lú àánú mọ́.

  23. Esekiẹli 5:12nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Ìdámẹ́ta nínú àwọn ènìyàn rẹ yóò kú nípa àjàkálẹ̀-ààrùn tàbí kí ìyàn run wọ́n: ìdámẹ́ta yóò ṣubú nípa idà lẹ́yìn odi rẹ, èmi yóò sì tú ìdámẹ́ta yòókù ká sínú ẹ̀fúùfù, èmi yóò sì máa fi idà lé wọn.

  24. Esekiẹli 5:13nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    “Ìbínú mi yóò sì dúró, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú gbígbóná mi yóò sì rọlẹ̀, èmi yóò sì ti gba ẹ̀san mi. Nígbà tí mo bá sì parí ìbínú mi lórí wọn, wọn ó mọ̀ pé, Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀ nínú ìtara mi.

  25. Esekiẹli 5:14nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    “Èmi yóò fi ọ́ ṣòfò, èmi yóò sì sọ ọ́ di ẹ̀gàn fún àwọn orílẹ̀-èdè tó yí ọ ká, àti lójú àwọn tó ń kọjá.