Fò sí àkóónú

circa 605–538 BC

The Babylonian Exile

Jerusalem falls and the temple burns; Ezekiel and Daniel minister among the exiles as Lamentations mourns the city's ruin.

1,784 ẹsẹ · 3 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Esekiẹli 5:15nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    O ó wá di ẹ̀gàn, ẹ̀sín àti ẹ̀kọ̀ àti ohun ẹ̀rù àti ìyanu fún àwọn orílẹ̀-èdè tó yí ọ ká, nígbà tí mo bá fìyà jẹ ọ́ nínú ìbínú àti nínú ìbínú gbígbóná mi. Èmi Olúwa ni ó sọ bẹ́ẹ̀.

  2. Esekiẹli 5:16nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí èmi ó rán ọfà búburú ìyàn sí wọn, èyí tí yóò jẹ́ fún ìparun wọn. Èmí tí èmi yóò rán run yín. Èmí yóò sì sọ ìyàn di púpọ̀ fún yín. Èmí yóò sì ṣẹ́ ọ̀pá oúnjẹ yín.

  3. Esekiẹli 5:17nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò rán ìyàn àti ẹranko búburú sí i yín, wọn yóò fi yín sílẹ̀ ni àìlọ́mọ. Àjàkálẹ̀-ààrùn àti ìtàjẹ̀ sílẹ̀ yóò kọjá láàrín yín. Èmi yóò si mú idà wá sórí rẹ. Èmi Olúwa ló sọ bẹ́ẹ̀.”

  4. Esekiẹli 6:1nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá wí pé,

  5. Esekiẹli 6:2nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    “Ọmọ ènìyàn, dojúkọ àwọn òkè Israẹli; kí o sì sọtẹ́lẹ̀ lòdì sí wọn

  6. Esekiẹli 6:3nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    wí pé, ‘Ẹ̀yin òkè Israẹli, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Olódùmarè. Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí sí ẹ̀yin òkè ńlá àti àwọn òkè kéékèèké, sí àwọn odò ṣíṣàn àti sí àfonífojì, èmi yóò mú idà wa sórí yín, èmí yóò sì pa ibi gíga yín run.

  7. Esekiẹli 6:4nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò wó pẹpẹ yín lulẹ̀, èmi yóò sì fọ́ pẹpẹ tùràrí yín túútúú; èmi yóò sì pa àwọn ènìyàn yín síwájú àwọn òrìṣà wọn.

  8. Esekiẹli 6:5nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò tẹ́ òkú àwọn ará Israẹli síwájú òrìṣà wọn, èmi yóò sì fọ́n egungun wọn yí pẹpẹ wọn ká.

  9. Esekiẹli 6:6nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Gbogbo ibi tí ẹ ń gbé àti àwọn ibi gíga yín ni yóò di píparun, gbogbo pẹpẹ yín ni yóò di ahoro, àwọn òrìṣà yín yóò di fífọ́ túútúú, àwọn pẹpẹ tùràrí yín ni a ó gé lulẹ̀, gbogbo iṣẹ́ yín yóò parẹ́.

  10. Esekiẹli 6:7nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Àwọn ènìyàn yín yóò ṣubú láàrín yín, ẹ ó sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.

  11. Esekiẹli 6:8nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    “ ‘Ṣùgbọ́n èmi yóò dá àwọn kan sí nítorí pé díẹ̀ nínú yín ni yóò bọ́ lọ́wọ́ idà, nígbà tí a bá fọ́n yín ká sí gbogbo ilẹ̀ àti orílẹ̀-èdè.

  12. Esekiẹli 6:9nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Àwọn ti ó bọ́ nínú yin yóò sì rántí mi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè níbi tí wọn yóò dìwọ́n ní ìgbèkùn lọ, nítorí wọ́n yóò máa rántí mi bí wọ́n ti bà mí lọ́kàn jẹ́ nípa àgbèrè wọn, tí ó yà wọ́n kúrò lọ́dọ̀ mi àti nípa ojú wọn tí ó ṣàfẹ́rí àwọn òrìṣà. Wọn yóò sì ṣú ara wọn nítorí ìwà ibi tí wọ́n ti hù nípa gbogbo ìríra wọn.

  13. Esekiẹli 6:10nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Wọn yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa; àti pé kì í ṣe lásán ni mo ń lérí pé èmi yóò mú ìdààmú bá wọn.

  14. Esekiẹli 6:11nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    “ ‘Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí, Pàtẹ́wọ́ kí o tún fẹsẹ̀ janlẹ̀, kí o wá kígbe síta pé, “Ó ṣe!” Ilé Israẹli yóò ṣubú nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn nítorí gbogbo ìwà ìríra búburú tí wọ́n hù. Wọn yóò ṣubú nípa idà àti ìyàn.

  15. Esekiẹli 6:12nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Ẹni tó wà lókèèrè yóò kú pẹ̀lú àjàkálẹ̀-ààrùn, àti ẹni tó wà nítòsí yóò ṣubú pẹ̀lú idà, ìyàn ni yóò pa ẹni tó bá ṣẹ́kù sílẹ̀. Báyìí ni èmi yóò ṣe mú ìbínú gbígbóná mi wá sórí wọn.

  16. Esekiẹli 6:13nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Wọn yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa, nígbà tí òkú àwọn ènìyàn wọn bá wà níbẹ̀ láàrín òrìṣà wọn yí pẹpẹ wọn ká, lórí àwọn òkè gíga gbogbo, àti lórí góńgó òkè àti lábẹ́ igi tútù àti lábẹ́ igi óákù, níbi tí wọ́n ti ń fi tùràrí olóòórùn dídùn rú ẹbọ sí gbogbo òrìṣà wọn.

  17. Esekiẹli 6:14nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò na ọwọ́ mi jáde sí wọn láti mú kí ilẹ̀ náà ṣòfò, kí ó sì dahoro dé aṣálẹ̀ ìhà Dibila—ní gbogbo ibùgbé wọn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.’ ”

  18. Esekiẹli 7:1nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:

  19. Esekiẹli 7:2nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    “Ọmọ ènìyàn, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí sí ilé Israẹli: “ ‘Òpin! Òpin ti dé sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ náà!

  20. Esekiẹli 7:3nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Òpin tí dé sí ọ báyìí, èmi yóò sì tú ìbínú mi jáde sí ọ, èmi yóò dájọ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìwà rẹ, èmi yóò sì san án fún ọ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìwà ìríra rẹ.

  21. Esekiẹli 7:4nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Ojú mi kò ní i dá ọ sì, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò ṣàánú; ṣùgbọ́n èmi yóò san án fún ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ àti gbogbo ìwà ìríra tó wà láàrín rẹ. Nígbà náà ní ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’

  22. Esekiẹli 7:5nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    “Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Ibi! Ibi kan ṣoṣo. Kíyèsi, ó bọ̀ ní orí rẹ!

  23. Esekiẹli 7:6nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Òpin ti dé! Òpin ti dé! Ó ti dìde lòdì sí ọ. Kíyèsi, ó ti dé!

  24. Esekiẹli 7:7nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Ìparun ti dé sórí rẹ, ìwọ tó ń gbé ní ilẹ̀ náà. Àkókò náà dé! Ọjọ́ wàhálà ti súnmọ́ etílé! Kì í ṣe ọjọ́ ariwo ayọ̀ lórí òkè.

  25. Esekiẹli 7:8nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Mo ṣetán láti tú ìbínú gbígbóná mi lé ọ lórí àti láti lo ìbínú mi lórí rẹ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀nà rẹ, èmi yóò sì dá ọ lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ àti gẹ́gẹ́ bí ìwà ìríra rẹ ni èmi yóò sì san án fún ọ.