Fò sí àkóónú

circa 605–538 BC

The Babylonian Exile

Jerusalem falls and the temple burns; Ezekiel and Daniel minister among the exiles as Lamentations mourns the city's ruin.

1,784 ẹsẹ · 3 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Esekiẹli 8:7nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Ó mú mi wá sí ẹnu-ọ̀nà àgbàlá. Mo wò ó, mo sì rí ihò kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri.

  2. Esekiẹli 8:8nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ló sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, gbẹ́ inú ògiri náà,” nígbà tí mo sì gbẹ́ inú ògiri, mo rí ìlẹ̀kùn kan.

  3. Esekiẹli 8:9nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Ó sì wí fún mi pé, “Wọlé kí ìwọ kí ó rí ohun ìríra búburú tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀.”

  4. Esekiẹli 8:10nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Mo wọlé, mo sì rí àwòrán oríṣìíríṣìí ẹranko tí ń fà nílẹ̀ àti àwọn ẹranko ìríra àti gbogbo òrìṣà ilẹ̀ Israẹli tí wọ́n yà sára ògiri.

  5. Esekiẹli 8:11nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Níwájú wọn ni àádọ́rin ọkùnrin tó jẹ́ àgbàgbà ilé Israẹli dúró sí, Jaaṣaniah ọmọ Ṣafani sì dúró sí àárín wọn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì mú àwo tùràrí lọ́wọ́, òórùn sì ń tú jáde.

  6. Esekiẹli 8:12nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Ó sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, ṣé o ti rí ohun tí àwọn àgbàgbà ilé Israẹli ń ṣe nínú òkùnkùn, olúkúlùkù ní yàrá òrìṣà rẹ̀? Wọ́n ní, ‘Olúwa kò rí wa; Olúwa ti kọ̀ ilé náà sílẹ̀.’ ”

  7. Esekiẹli 8:13nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Ó tún sọ fún mi pé, “Ìwọ yóò rí wọn tí wọ́n ń ṣe àwọn ohun ìríra tó burú jù bẹ́ẹ̀ lọ.”

  8. Esekiẹli 8:14nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Ó mú mi wá sí ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa tó wà ní ìhà àríwá, mo sì rí àwọn obìnrin tó jókòó, tí wọ́n sí ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa tó wà ní ìhà àríwá, mo sì rí àwọn obìnrin tó jókòó, tí wọ́n sì ń ṣọ̀fọ̀ fún Tamusi.

  9. Esekiẹli 8:15nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Ó sọ fún mi pé, “Ṣé ìwọ rí báyìí, ọmọ ènìyàn? Ìwọ yóò tún rí ìríra tó ga jù èyí lọ.”

  10. Esekiẹli 8:16nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Ó mú mi wá sí ibi àgbàlá ilé Olúwa, ní ẹnu-ọ̀nà tẹmpili Olúwa, láàrín ìloro àti pẹpẹ, ni ìwọ̀n ọkùnrin mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n (25) wà, tí wọ́n kẹ́yìn sí tẹmpili Olúwa tí wọn sì kọjú sí ìlà-oòrùn, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún oòrùn ní apá ìlà-oòrùn.

  11. Esekiẹli 8:17nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Ó sì wí fún mi, “Ṣé ìwọ ti rí èyí ọmọ ènìyàn? Ǹjẹ́ ohun kékeré ni fún ilé Juda láti ṣe àwọn ohun ìríra tí wọn ń ṣe níbi yìí? Ṣé o tún yẹ kí wọ́n fi ìwà ipá kún ilẹ̀ kí wọn sì máa mú mi bínú ní gbogbo ìgbà? Wò wọn bi wọn ṣe n fi ẹ̀ka wọn sínú inú wọn.

  12. Esekiẹli 8:18nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà, èmi yóò fi ìbínú bá wọn wí; èmi kò ní i dá wọn sí bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì ní fojú àánú wò wọ́n. Bí wọ́n tilẹ̀ ń pariwo sí mi létí, èmi kò ní fetí sí wọn.”

  13. Esekiẹli 9:1nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Mo gbọ́ ti ó kígbe ní ohùn rara pé, “Mú àwọn olùṣọ́ ìlú súnmọ́ itòsí, kí olúkúlùkù wọn mú ohun ìjà olóró lọ́wọ́.”

  14. Esekiẹli 9:2nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Lójú ẹsẹ̀ ni ọkùnrin mẹ́fà jáde láti ẹnu-ọ̀nà òkè tó kọjú sí ìhà àríwá, olúkúlùkù pẹ̀lú ohun ìjà olóró lọ́wọ́ wọn. Ọkùnrin kan tó wọ aṣọ funfun gbòò wa láàrín wọn, pẹ̀lú ohun ìkọ̀wé lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Gbogbo wọn sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ idẹ.

  15. Esekiẹli 9:3nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Ògo Ọlọ́run Israẹli sì gòkè kúrò lórí kérúbù, níbi tó wà tẹ́lẹ̀ lọ sí ibi ìloro tẹmpili. Nígbà náà ni Olúwa pe ọkùnrin tó wọ aṣọ funfun náà tí ó sì ní ohun ìkọ̀wé lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.

  16. Esekiẹli 9:4nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Ó sì sọ fún un pé, “La àárín ìlú Jerusalẹmu já, kí ìwọ sì fi àmì síwájú orí gbogbo àwọn tó ń kẹ́dùn, tó sì ń sọkún nítorí ohun ìríra tí wọn ń ṣe láàrín rẹ̀.”

  17. Esekiẹli 9:5nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Bí mo ṣe ń fetí sí èyí, O tún sọ fún àwọn yòókù pé, “Tẹ̀lé ọkùnrin náà lọ sí àárín ìlú láti pa láì dá sí àti láì ṣàánú rárá.

  18. Esekiẹli 9:6nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Ẹ pa arúgbó àti ọ̀dọ́mọkùnrin, ẹ pa ọlọ́mọge, obìnrin àti ọmọ kéékèèké, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe fi ọwọ́ kan àwọn tó ní àmì. Ẹ bẹ̀rẹ̀ láti ibi mímọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn àgbàgbà tó wà níwájú tẹmpili.

  19. Esekiẹli 9:7nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà lo sọ fún wọn pé, “Ẹ sọ tẹmpili náà di àìmọ́, kí òkú sì kún àgbàlá náà. Ẹ lọ!” Wọ́n jáde síta, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í pa ènìyàn láàrín ìlú.

  20. Esekiẹli 9:8nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Èmi nìkan ló ṣẹ́kù nígbà tí wọ́n lọ pa àwọn ènìyàn, mo dójú mi bolẹ̀, mo kígbe pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè! Ìwọ yóò ha pa ìyókù Israẹli nípa dída ìbínú gbígbóná rẹ sórí Jerusalẹmu?”

  21. Esekiẹli 9:9nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Ó dá mi lóhùn pé, “Ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli àti Juda pọ gidigidi; ilé wọn kún fún ìtàjẹ̀ sílẹ̀ àti àìṣòótọ́. Wọ́n ní, ‘Olúwa tí kọ ilẹ̀ náà sílẹ̀; Olúwa kò sì rí wa.’

  22. Esekiẹli 9:10nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà, èmi kò ní wò wọ́n pẹ̀lú àánú, èmi kò sì ní dá wọn sí, ṣùgbọ́n Èmi yóò dá ohun tí wọ́n ti ṣe padà sórí wọn.”

  23. Esekiẹli 9:11nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Ọkùnrin tí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀, tí ó ní ìwo tàdáwà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ròyìn pé, “Mo ti ṣe gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti pàṣẹ fún mi.”

  24. Esekiẹli 10:1nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Mo sì wò ó, mo rí ohun kan tó dàbí òkúta safire nínú òfúrufú tó wà lókè orí kérúbù, ìrísí ohun yìí sì dàbí ìtẹ́.

  25. Esekiẹli 10:2nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi

    Olúwa sì sọ fún ọkùnrin tó wọ aṣọ funfun pé, “Lọ sí àárín àwọn kẹ̀kẹ́ tó wà lábẹ́ kérúbù. Bu ẹyin iná tó kúnwọ́ rẹ láàrín kérúbù, kí o sì fọ́n sórí ìlú náà.” Ó sì lọ lójú mi.