- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 605–538 BC
The Babylonian Exile
Jerusalem falls and the temple burns; Ezekiel and Daniel minister among the exiles as Lamentations mourns the city's ruin.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Esekiẹli 10:3nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi
Àwọn kérúbù dúró sí apá gúúsù tẹmpili nígbà tí ọkùnrin náà wọlé, ìkùùkuu sì bo inú àgbàlá.
- Esekiẹli 10:4nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi
Ògo Olúwa sì kúrò lórí àwọn kérúbù, ó bọ́ sí ibi ìloro tẹmpili. Ìkùùkuu sì bo inú tẹmpili, àgbàlá sì kún fún ìmọ́lẹ̀ àti ògo Olúwa.
- Esekiẹli 10:5nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi
A sì gbọ́ ariwo ìyẹ́ àwọn kérúbù yìí títí dé àgbàlá tó wà ní ìta gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí Ọlọ́run Olódùmarè bá ń sọ̀rọ̀.
- Esekiẹli 10:6nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi
Nígbà tí Olúwa pàṣẹ fún ọkùnrin aláṣọ funfun yìí pé, “Mú iná láàrín àwọn kẹ̀kẹ́, láàrín àwọn kérúbù,” ó sì lọ dúró ṣẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn kẹ̀kẹ́ náà.
- Esekiẹli 10:7nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi
Ọ̀kan nínú àwọn kérúbù sì nawọ́ sí ibi iná tó wà láàrín kérúbù yòókù. Ó mú lára rẹ, ó fi sínú ọwọ́ ọkùnrin aláṣọ funfun, òun náà gbà á, ó sì jáde lọ.
- Esekiẹli 10:8nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi
(Ohun tó dàbí ọwọ́ ènìyàn wà lábẹ́ ìyẹ́ àwọn kérúbù yìí.)
- Esekiẹli 10:9nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi
Nígbà tí mo sì wò, kíyèsí i, àwọn kẹ̀kẹ́ mẹ́rin wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn kérúbù yìí, kẹ̀kẹ́ kọ̀ọ̀kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kérúbù kọ̀ọ̀kan; ìrí àwọn kẹ̀kẹ́ yìí ń tàn yanran bí àwọ̀ òkúta berili.
- Esekiẹli 10:10nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi
Ní ti ìrísí wọn, gbogbo wọn jọra wọn; ọ̀kọ̀ọ̀kan rí bí ìgbà tí kẹ̀kẹ́ kan wà nínú kẹ̀kẹ́ mìíràn.
- Esekiẹli 10:11nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi
Nígbà tí wọ́n ń lọ, wọ́n tẹ̀lé ọ̀kan nínú ọ̀nà mẹ́rin tí àwọn kérúbù dojúkọ; àwọn kẹ̀kẹ́ náà kò yípadà bí àwọn kérúbù ti ń lọ. Àwọn kérúbù ń lọ sí ibi tí orí dojúkọ láì yà.
- Esekiẹli 10:12nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi
Gbogbo ara wọn àti ẹ̀yìn, ọwọ́ wọn àti ìyẹ́ wọn, àti àwọn kẹ̀kẹ́ kún fún ojú yíkákiri kẹ̀kẹ́, tí àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní.
- Esekiẹli 10:13nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi
Mo gbọ́ tí wọ́n pe àwọn kẹ̀kẹ́ yìí ni “kẹ̀kẹ́ àjà.”
- Esekiẹli 10:14nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi
Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn kérúbù yìí ni ojú mẹ́rin: ojú èkínní jẹ́ ojú kérúbù, ojú kejì jẹ́ ti ènìyàn, ojú kẹta jẹ́ ti kìnnìún nígbà tí ojú kẹrin jẹ́ ti ẹyẹ idì.
- Esekiẹli 10:15nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi
A gbé àwọn kérúbù sókè. Èyí ni àwọn ẹ̀dá alààyè tí mo rí létí odò Kebari.
- Esekiẹli 10:16nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi
Bí àwọn kérúbù yìí bá ń lọ àwọn kẹ̀kẹ́ ẹgbẹ́ wọn náà yóò lọ; bẹ́ẹ̀ ni bí àwọn kérúbù bá tú ìyẹ́ wọn ká láti dìde nílẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ yìí kò ní kúrò lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn.
- Esekiẹli 10:17nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi
Bí àwọn kérúbù bá dúró díẹ̀ àwọn kẹ̀kẹ́ náà yóò dúró jẹ́ẹ́; bí àwọn kérúbù bá dìde àwọn kẹ̀kẹ́ náà yóò dìde, nítorí pé ẹ̀mí àwọn ẹ̀dá alààyè yìí wà nínú wọn.
- Esekiẹli 10:18nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi
Ògo Olúwa kúrò níbi ìloro tẹmpili, ó sì dúró sórí àwọn kérúbù.
- Esekiẹli 10:19nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi
Àwọn kérúbù gbé ìyẹ́ wọn sókè, wọ́n sì fò kúrò nílẹ̀ lójú mi, wọ́n sì lọ pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ wọn lẹ́ẹ̀kan náà. Wọ́n dúró níbi ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà ìlà-oòrùn ilé Olúwa, ògo Ọlọ́run Israẹli sì wà lórí wọn.
- Esekiẹli 10:20nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi
Àwọn wọ̀nyí ni ẹ̀dá alààyè tí mo rí lábẹ́ Ọlọ́run Israẹli létí odò Kebari, mo sì mọ̀ pé kérúbù ni wọ́n.
- Esekiẹli 10:21nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi
Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ojú mẹ́rin àti ìyẹ́ mẹ́rin, lábẹ́ ìyẹ́ wọn ni ohun tó jọ ọwọ́ ènìyàn wà.
- Esekiẹli 10:22nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi
Àfiwé ojú àti ìrísí wọn rí bákan náà pẹ̀lú àwọn tí mo rí létí odò Kebari. Olúkúlùkù wọn sì ń lọ sí ọ̀kánkán tààrà.
- Esekiẹli 11:1nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi
Ẹ̀mí sì gbé mi sókè, ó mú mi lọ sí ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa èyí tó dojúkọ ìlà-oòrùn. Ní àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà yìí ni àwọn ọkùnrin mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n wá, mo rí Jaaṣaniah ọmọ Assuri àti Pelatiah ọmọ Benaiah, tí wọ́n jẹ́ ìjòyè àwọn ènìyàn.
- Esekiẹli 11:2nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi
Olúwa sì sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, àwọn ọkùnrin yìí ló ń pète ibi, wọ́n sì ń gbé ìmọ̀ràn búburú kalẹ̀ nínú ìlú.
- Esekiẹli 11:3nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi
Wọ́n ní, ‘Kò ha tí ì tó àsìkò láti kọ́lé? Ìlú yìí ni ìkòkò ìdáná, àwa sì ni ẹran’.
- Esekiẹli 11:4nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi
Nítorí náà sọtẹ́lẹ̀ nípa wọn; ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀.”
- Esekiẹli 11:5nǹkan bí 594 ṣáájú Kristi
Ẹ̀mí Olúwa sì bà lé mi, ó sì wí pé, “Sọ̀rọ̀!” Báyìí ni Olúwa wí, ohun tí ẹ ń sọ nìyìí, ilé Israẹli, mo mọ ohun tó wà lọ́kàn yín.