Fò sí àkóónú

Creation Era

The Tower of Babel

Scattered nations and confused languages mark the beginning of the diversity of peoples across the earth.

64 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Gẹnẹsisi 10:26nǹkan bí 2247 ṣáájú Kristi

    Joktani sì bí Almodadi, Ṣelefi, Hasarmafeti, Jera.

  2. Gẹnẹsisi 10:27nǹkan bí 2247 ṣáájú Kristi

    Hadoramu, Usali, Dikla,

  3. Gẹnẹsisi 10:28nǹkan bí 2207 ṣáájú Kristi

    Obali, Abimaeli, Ṣeba.

  4. Gẹnẹsisi 10:29nǹkan bí 2207 ṣáájú Kristi

    Ofiri, Hafila àti Jobabu. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Joktani.

  5. Gẹnẹsisi 10:30nǹkan bí 2207 ṣáájú Kristi

    Agbègbè ibi tí wọn ń gbé bẹ̀rẹ̀ láti Meṣa títí dé Sefari, ní àwọn ilẹ̀ tó kún fún òkè ní ìlà-oòrùn.

  6. Gẹnẹsisi 10:31nǹkan bí 2207 ṣáájú Kristi

    Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà ọmọ Ṣemu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn, ní èdè wọn, ní ilẹ̀ wọn àti ní orílẹ̀-èdè wọn.

  7. Gẹnẹsisi 10:32nǹkan bí 2207 ṣáájú Kristi

    Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà ọmọ Noa gẹ́gẹ́ bí ìran wọn, ní orílẹ̀-èdè wọn. Ní ipasẹ̀ wọn ni àwọn ènìyàn ti tàn ká ilẹ̀ ayé lẹ́yìn ìkún omi.

  8. Gẹnẹsisi 11:1nǹkan bí 2247 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn náà, gbogbo àgbáyé sì ń sọ èdè kan ṣoṣo.

  9. Gẹnẹsisi 11:2nǹkan bí 2247 ṣáájú Kristi

    Bí àwọn ènìyàn ṣe ń tẹ̀síwájú lọ sí ìhà ìlà-oòrùn, wọ́n rí pẹ̀tẹ́lẹ̀ kan ní ilẹ̀ Ṣinari, wọ́n sì tẹ̀dó síbẹ̀.

  10. Gẹnẹsisi 11:3nǹkan bí 2247 ṣáájú Kristi

    Wọ́n sì wí fún ara wọn pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a mọ bíríkì kí a sì sún wọ́n jìnà.” Bíríkì ni wọ́n ń lò ní ipò òkúta, àti ọ̀dà ilẹ̀ tí wọn ń lò láti mú wọn papọ̀ dípò ẹfun (òkúta láìmù tí wọ́n fi ń ṣe símẹ́ńtì àti omi).

  11. Gẹnẹsisi 11:4nǹkan bí 2247 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni wọ́n wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a tẹ ìlú kan dó fún ara wa, kí a sì kọ́ ilé ìṣọ́ kan tí yóò kan ọ̀run, kí a ba à lè ní orúkọ, kí a má sì tú káàkiri sórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”

  12. Gẹnẹsisi 11:5nǹkan bí 2247 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n, Olúwa sọ̀kalẹ̀ láti wo ìlú àti ilé ìṣọ́ tí àwọn ènìyàn náà ń kọ́.

  13. Gẹnẹsisi 11:6nǹkan bí 2247 ṣáájú Kristi

    Olúwa wí pé, “Bí àwọn ènìyàn bá ń jẹ́ ọ̀kan àti èdè kan tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ yìí, kò sí ohun tí wọ́n gbèrò tí wọn kò ní le ṣe yọrí.

  14. Gẹnẹsisi 11:7nǹkan bí 2247 ṣáájú Kristi

    Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a sọ̀kalẹ̀ lọ, kí a da èdè wọn rú kí èdè wọn má ba à yé ara wọn mọ́.”

  15. Gẹnẹsisi 11:8nǹkan bí 2247 ṣáájú Kristi

    Olúwa sì tú wọn ká sórí ilẹ̀ gbogbo, wọ́n sì ṣíwọ́ ìlú náà tí wọn ń tẹ̀dó.

  16. Gẹnẹsisi 11:9nǹkan bí 2247 ṣáájú Kristi

    Ìdí èyí ni a fi pè é ní Babeli nítorí ní ibẹ̀ ni Olúwa ti da èdè gbogbo ayé rú. Olúwa tí sì tú àwọn ènìyàn ká sí gbogbo orí ilẹ̀ ayé.

  17. Gẹnẹsisi 11:10nǹkan bí 2346 ṣáájú Kristi

    Wọ̀nyí ni ìran Ṣemu. Ọdún méjì lẹ́yìn ìkún omi, tí Ṣemu pé ọgọ́rùn-ún ọdún ni ó bí Arfakṣadi.

  18. Gẹnẹsisi 11:11nǹkan bí 1846 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn tí ó bí Arfakṣadi, Ṣemu tún wà láààyè fún ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún (500), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

  19. Gẹnẹsisi 11:12nǹkan bí 2311 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Arfakṣadi pé ọdún márùndínlógójì ni ó bí Ṣela.

  20. Gẹnẹsisi 11:13nǹkan bí 1908 ṣáájú Kristi

    Arfakṣadi sì wà láààyè fún ọdún mẹ́tàlénírinwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Ṣela, ó sì bí àwọn ọmọbìnrin àti àwọn ọmọkùnrin mìíràn.

  21. Gẹnẹsisi 11:14nǹkan bí 2281 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Ṣela pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Eberi.

  22. Gẹnẹsisi 11:15nǹkan bí 1878 ṣáájú Kristi

    Ṣela sì wà láààyè fún ọdún mẹ́tàlénírinwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Eberi tán, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

  23. Gẹnẹsisi 11:16nǹkan bí 2247 ṣáájú Kristi

    Eberi sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n, ó sì bí Pelegi.

  24. Gẹnẹsisi 11:17nǹkan bí 1817 ṣáájú Kristi

    Eberi sì wà láààyè fún irinwó ọdún ó lé ọgbọ̀n (430) lẹ́yìn tí ó bí Pelegi, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

  25. Gẹnẹsisi 11:18nǹkan bí 2217 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Pelegi pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Reu.