Fò sí àkóónú

Creation Era

The Tower of Babel

Scattered nations and confused languages mark the beginning of the diversity of peoples across the earth.

64 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Gẹnẹsisi 11:19nǹkan bí 2008 ṣáájú Kristi

    Pelegi sì tún wà láààyè fún igba ọdún ó lé mẹ́sàn-án (209) lẹ́yìn tí ó bí Reu, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

  2. Gẹnẹsisi 11:20nǹkan bí 2185 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Reu pé ọdún méjìlélọ́gbọ̀n ni ó bí Serugu.

  3. Gẹnẹsisi 11:21nǹkan bí 1978 ṣáájú Kristi

    Reu tún wà láààyè lẹ́yìn tí ó bí Serugu fún igba ọdún ó lé méje (207), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mìíràn.

  4. Gẹnẹsisi 11:22nǹkan bí 2155 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Serugu pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Nahori.

  5. Gẹnẹsisi 11:23nǹkan bí 1955 ṣáájú Kristi

    Serugu sì wà láààyè fún igba ọdún lẹ́yìn tí ó bí Nahori, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

  6. Gẹnẹsisi 11:24nǹkan bí 2126 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Nahori pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n, ó bí Tẹra.

  7. Gẹnẹsisi 11:25nǹkan bí 2007 ṣáájú Kristi

    Nahori sì wà láààyè fún ọdún mọ́kàn dín lọ́gọ́fà lẹ́yìn ìbí Tẹra, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

  8. Gẹnẹsisi 11:26nǹkan bí 2056 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn tí Tẹra pé ọmọ àádọ́rin ọdún ó bí Abramu, Nahori àti Harani.

  9. Gẹnẹsisi 11:27nǹkan bí 1996 ṣáájú Kristi

    Wọ̀nyí ni ìran Tẹra. Tẹra ni baba Abramu, Nahori àti Harani. Harani sì bí Lọti.

  10. Gẹnẹsisi 11:28nǹkan bí 1996 ṣáájú Kristi

    Harani sì kú ṣáájú Tẹra baba rẹ̀ ní ilẹ̀ ìbí rẹ̀ ní Uri ti ilẹ̀ Kaldea.

  11. Gẹnẹsisi 11:29nǹkan bí 1996 ṣáájú Kristi

    Abramu àti Nahori sì gbéyàwó. Orúkọ aya Abramu ni Sarai, nígbà tí aya Nahori ń jẹ́ Milka, tí ṣe ọmọ Harani. Harani ni ó bí Milka àti Iska.

  12. Gẹnẹsisi 11:30nǹkan bí 1996 ṣáájú Kristi

    Sarai sì yàgàn, kò sì bímọ.

  13. Gẹnẹsisi 11:31nǹkan bí 1926 ṣáájú Kristi

    Tẹra sì mú ọmọ rẹ̀ Abramu àti Lọti ọmọ Harani, ọmọ ọmọ rẹ̀, ó sì mú Sarai tí i ṣe aya ọmọ rẹ̀. Abramu pẹ̀lú gbogbo wọn sì jáde kúrò ní Uri ti Kaldea láti lọ sí ilẹ̀ Kenaani. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọn dé Harani wọ́n tẹ̀dó síbẹ̀.

  14. Gẹnẹsisi 11:32nǹkan bí 1921 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Tẹra pé ọmọ igba ọdún ó lé márùn-ún (205) ni ó kú ní Harani.