- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1010–970 BC
The Reign of David
David unites the tribes, conquers Jerusalem, and establishes Israel's golden age—even through deep personal failure.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- 1 Kronika 11:17nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi
Dafidi sí pòǹgbẹ fún omi ó sì wí pé, “Háà, ẹnìkan yóò ha bu omi láti inú kànga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu-bodè Bẹtilẹhẹmu fún un mu?”
- 1 Kronika 11:18nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn mẹ́ta náà sì là láti ogun ará Filistini, ó sì fa omi jáde láti inú kànga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu-bodè Bẹtilẹhẹmu ó sì gbé padà tọ Dafidi wá. Ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti mu ú: dípò, ó sì tú jáde níwájú Olúwa.
- 1 Kronika 11:19nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi
“Kí Ọlọ́run má jẹ́ kí èmi ó má ṣe ṣe èyí!” ó wí pé. “Ṣé kí èmi kí ó mú ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yí ẹni tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu?” Nítorí wọ́n fi ẹ̀mí wọn wéwu láti mú padà wá, Dafidi kò ní mu ú. Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn akọni mẹ́ta ọkùnrin náà ṣe ohun ìyanu ńlá.
- 1 Kronika 11:20nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi
Abiṣai arákùnrin Joabu ìjòyè àwọn mẹ́ta. Ó sì gbé ọ̀kọ̀ rẹ̀ sókè lórí àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) àwọn ènìyàn, àwọn ẹni tí ó pa, bẹ́ẹ̀ ni ó sì di olókìkí gẹ́gẹ́ bí àwọn mẹ́ta.
- 1 Kronika 11:21nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi
Ó sì gba ìlọ́po ọlá lórí àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ó sì di olórí wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò ka kún ara wọn.
- 1 Kronika 11:22nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi
Benaiah ọmọ Jehoiada ó sì jẹ́ akọni oníjà láti Kabṣeeli, ẹni tí ó ṣe iṣẹ́ agbára ńlá. Ó sì pa àwọn ọmọ Arieli méjì ti Moabu, ó sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ sí inú ihò lákokò yìnyín dídì, ó sì pa kìnnìún kan
- 1 Kronika 11:23nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi
Ó sì pa ara Ejibiti ẹni tí ó ga ní ìwọ̀n ẹsẹ̀ méje àti ààbọ̀ ṣùgbọ́n àwọn ará Ejibiti wọn ní ọ̀kọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdábùú igi ahunṣọ àti ọ̀pá ní ọwọ́ rẹ̀, Benaiah sọ̀kalẹ̀ lórí rẹ̀ pẹ̀lú kùmọ̀. Ó sì gba ọ̀kọ̀ náà láti ọwọ́ ará Ejibiti ó sì pa á pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀.
- 1 Kronika 11:24nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi
Nǹkan wọ̀nyí sì ní ìwà akin Benaiah ọmọ Jehoiada; ohun náà pẹ̀lú sì di olókìkí gẹ́gẹ́ bí àwọn akọni ọkùnrin mẹ́ta.
- 1 Kronika 11:25nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi
Ó sì ní ọlá púpọ̀ ju àwọn ọgbọ̀n lọ, ṣùgbọ́n a kò kà á láàrín àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Dafidi sì fi sí ìkáwọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́.
- 1 Kronika 11:26nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi
Àwọn akọni ọkùnrin náà nìyí: Asaheli arákùnrin Joabu, Elhanani ọmọ Dodo láti Bẹtilẹhẹmu,
- 1 Kronika 11:27nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi
Ṣamotu ará Harori, Helesi ará Peloni
- 1 Kronika 11:28nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi
Ira ọmọ Ikẹsi láti Tekoa, Abieseri láti Anatoti,
- 1 Kronika 11:29nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi
Sibekai ará Huṣati, láti ará Ahohi
- 1 Kronika 11:30nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi
Maharai ará Netofa, Heledi ọmọ Baanah ará Netofa,
- 1 Kronika 11:31nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi
Itai ọmọ Ribai láti Gibeah ní Benjamini, Benaiah ará Piratoni,
- 1 Kronika 11:32nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi
Hurai láti àfonífojì Gaaṣi, Abieli ará Arbati,
- 1 Kronika 11:33nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi
Asmafeti ará Bahurimu Eliaba ará Ṣaalboni.
- 1 Kronika 11:34nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi
Àwọn ọmọ Haṣemu ará Gisoni Jonatani ọmọ Ṣage ará Harari.
- 1 Kronika 11:35nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi
Ahiamu ọmọ Sakari ará Harari, Elifali ọmọ Uri
- 1 Kronika 11:36nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi
Heferi ará Mekerati, Ahijah ará Peloni,
- 1 Kronika 11:37nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi
Hesro ará Karmeli Naarai ọmọ Esbai,
- 1 Kronika 11:38nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi
Joẹli arákùnrin Natani Mibari ọmọ Hagari,
- 1 Kronika 11:39nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi
Seleki ará Ammoni, Naharai ará Beroti ẹni tí ó jẹ́ ẹni tí n ru ìhámọ́ra Joabu ọmọ Seruiah.
- 1 Kronika 11:40nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi
Ira ará Itri, Garebu ará Itri,
- 1 Kronika 11:41nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi
Uriah ará Hiti Sabadi ọmọ Ahlai.