- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1010–970 BC
The Reign of David
David unites the tribes, conquers Jerusalem, and establishes Israel's golden age—even through deep personal failure.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- 1 Kronika 10:1nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi
Nísinsin yìí, àwọn ará Filistini dojú ìjà kọ Israẹli, àwọn ará Israẹli sì sálọ kúrò níwájú wọn, a sì pa ọ̀pọ̀ wọn sí orí òkè Gilboa.
- 1 Kronika 10:2nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi
Àwọn ará Filistini sí lépa Saulu gidigidi àti àwọn ọmọ rẹ̀. Wọ́n sì pa àwọn ọmọ rẹ̀. Jonatani, Abinadabu àti Malikiṣua.
- 1 Kronika 10:3nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi
Ogun náà sí gbóná janjan fún Saulu, nígbà tí àwọn tafàtafà sì lé e bá, wọ́n sì ṣá a lọ́gbẹ́.
- 1 Kronika 10:4nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi
Saulu sì sọ fún ẹni tí ó gbé ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Fa idà rẹ yọ, kí o sì fi gún mi, kí àwọn aláìkọlà wọ̀nyí má wá láti bú mi.” Ṣùgbọ́n ẹni tí ó ń gbé ìhámọ́ra rẹ̀ ń bẹ̀rù, kò sì le ṣe é, bẹ́ẹ̀ ni Saulu mú idà tirẹ̀ ó sì ṣubú lé e.
- 1 Kronika 10:5nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi
Nígbà tí agbé-ìhámọ́ra rí pé Saulu ti kú, òhun pẹ̀lú ṣubú lórí idà tirẹ̀, ó sì kú.
- 1 Kronika 10:6nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi
Bẹ́ẹ̀ ni Saulu àti ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kú, gbogbo ilé rẹ̀ sì kú ṣọ̀kan, lọ́jọ́ kan náà.
- 1 Kronika 10:7nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi
Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rí wí pé àwọn ọmọ-ogun ti sálọ àti pé Saulu àti àwọn ọmọ rẹ̀ ti kú wọ́n kọ àwọn ìlú wọn sílẹ̀, wọ́n sì sálọ. Àwọn ará Filistini wá, wọ́n sì jókòó nínú wọn.
- 1 Kronika 10:8nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ kejì, nígbà tí àwọn ará Filistini wá láti kó òkú, wọ́n rí Saulu àti àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n ṣubú sórí òkè Gilboa.
- 1 Kronika 10:9nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi
Wọ́n bọ́ ní aṣọ, wọ́n sì gbé orí rẹ̀ àti ìhámọ́ra rẹ̀, wọ́n sì rán ìránṣẹ́ lọ káàkiri ilẹ̀ àwọn ará Filistini láti kéde ìròyìn náà láàrín àwọn òrìṣà wọn àti àwọn ènìyàn wọn.
- 1 Kronika 10:10nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi
Wọ́n gbé ìhámọ́ra rẹ̀ sí inú ilé tí wọ́n kọ́ fún òrìṣà wọn, wọ́n sì fi orí rẹ̀ kọ́ sí inú ilé Dagoni.
- 1 Kronika 10:11nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi
Nígbà tí gbogbo àwọn olùgbé Jabesi—Gileadi gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn ará Filistini ṣe fún Saulu,
- 1 Kronika 10:12nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi
gbogbo àwọn akọni ọkùnrin wọn lọ láti mú àwọn ará Saulu àti àwọn ọmọ rẹ̀, wọ́n sì kó wọn wá sí Jabesi. Nígbà náà, wọ́n sin egungun wọn sábẹ́ igi óákù ní Jabesi, wọ́n sì gbààwẹ̀ fún ọjọ́ méje.
- 1 Kronika 10:13nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi
Saulu kú nítorí kò ṣe òtítọ́ sí Olúwa, kò pa ọ̀rọ̀ Olúwa mọ́ pẹ̀lú, ó tọ abókùúsọ̀rọ̀ lọ fún ìtọ́sọ́nà.
- 1 Kronika 10:14nǹkan bí 1056 ṣáájú Kristi
Kò sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa pa á, Ó sì yí ìjọba náà padà sọ́dọ̀ Dafidi ọmọ Jese.
- 1 Kronika 11:1nǹkan bí 1048 ṣáájú Kristi
Gbogbo àwọn Israẹli kó ara wọn jọ pọ̀ sí ọ̀dọ̀ Dafidi ní Hebroni, wọ́n sì wí pé, “Ẹran-ara rẹ àti ẹ̀jẹ̀ rẹ ni àwa í ṣe.
- 1 Kronika 11:2nǹkan bí 1048 ṣáájú Kristi
Ní àtijọ́, kódà nígbà tí Saulu jẹ ọba, ìwọ ni ẹni tí ó darí Israẹli ní ojú ogun wọn. Olúwa Ọlọ́run rẹ sì wí fún ọ pé, ‘Ìwọ yóò sì jẹ́ olùṣọ́ Israẹli ènìyàn mi, ìwọ yóò sì jẹ́ olórí fún wọn.’ ”
- 1 Kronika 11:3nǹkan bí 1048 ṣáájú Kristi
Nígbà tí gbogbo àwọn ìjòyè Israẹli tí wọ́n ti wá sọ́dọ̀ ọba Dafidi ni Hebroni. Ó sì ṣe májẹ̀mú pẹ̀lú wọn ní Hebroni níwájú Olúwa, wọ́n sì fi òróró yan Dafidi ní ọba lórí Israẹli, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa láti ọwọ́ Samuẹli.
- 1 Kronika 11:4nǹkan bí 1048 ṣáájú Kristi
Dafidi àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jáde lọ sí Jerusalẹmu (tí ṣe Jebusi). Àwọn Jebusi ara ilẹ̀ náà ń gbé níbẹ̀.
- 1 Kronika 11:5nǹkan bí 1048 ṣáájú Kristi
Àwọn ará ìlú Jebusi sì wí fún Dafidi pé, “Ìwọ kò sì gbọdọ̀ wọ ìhín yìí wá.” Ṣùgbọ́n Dafidi kó ìlú odi Sioni—èyí tí í ṣe ìlú Dafidi.
- 1 Kronika 11:6nǹkan bí 1048 ṣáájú Kristi
Dafidi ti wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá tètè kọlu àwọn ará Jebusi ni yóò di olórí àti balógun.” Joabu ọmọ Seruiah sì kọ́kọ́ gòkè lọ, bẹ́ẹ̀ ni ó sì gba olórí.
- 1 Kronika 11:7nǹkan bí 1048 ṣáájú Kristi
Dafidi sì ń gbé inú ìlú odi, nítorí náà ni wọ́n fi ń pè é ni ìlú Dafidi.
- 1 Kronika 11:8nǹkan bí 1048 ṣáájú Kristi
Ó sì kọ́ àwọn ìlú náà yíkákiri; láti Millo yíkákiri; Joabu sì tún ìyókù àwọn ìlú náà ṣe.
- 1 Kronika 11:9nǹkan bí 1048 ṣáájú Kristi
Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi ń ga, ó sì pọ̀ sí i, nítorí pé Olúwa àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú rẹ̀.
- 1 Kronika 11:10nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi
Àwọn wọ̀nyí sì ni ìjòyè alágbára ọkùnrin Dafidi, àwọn pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì fún ìjọba rẹ̀ ní àtìlẹ́yìn tó lágbára láti mú un tàn káàkiri gbogbo ilẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ṣèlérí.
- 1 Kronika 11:11nǹkan bí 1055 ṣáájú Kristi
Èyí sì ni iye àwọn akọni ọkùnrin Dafidi: Jaṣobeamu ọmọ Hakumoni, òun sì ni olórí nínú àwọn ìjòyè, ó sì gbé ọ̀kọ̀ rẹ̀ sókè lórí àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ènìyàn, àwọn ẹni tí ó pa ní ogun ẹ̀ẹ̀kan.