- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Joẹli 2:28nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
“Yóò sì ṣe níkẹyìn ọjọ́, èmi yóò tú nínú Ẹ̀mí mí sí ara ènìyàn gbogbo; àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin yóò máa sọtẹ́lẹ̀, àwọn arúgbó yín yóò máa lá àlá, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín yóò máa ríran.
- Joẹli 2:29nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Àti pẹ̀lú sí ara àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ ọkùnrin, àti sí ara àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ obìnrin, ní èmi yóò tú ẹ̀mí mí jáde ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì.
- Joẹli 2:30nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu hàn ní ọrun àti ní ayé, ẹ̀jẹ̀ àti iná, àti ọ̀wọ́n èéfín.
- Joẹli 2:31nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
A á sọ oòrùn di òkùnkùn, àti òṣùpá di ẹ̀jẹ̀, kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ ẹ̀rù Olúwa tó dé.
- Joẹli 2:32nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Yóò sí ṣe, ẹnikẹ́ni tí ó ba ké pè orúkọ Olúwa ní a ó gbàlà, nítorí ní òkè Sioni àti ní Jerusalẹmu ní ìgbàlà yóò gbé wà, bí Olúwa ti wí, àti nínú àwọn ìyókù tí Olúwa yóò pè.
- Joẹli 3:1nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
“Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àti ní àkókò náà, nígbà tí èmi tún mú ìgbèkùn Juda àti Jerusalẹmu padà bọ̀.
- Joẹli 3:2nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Èmi yóò kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ pẹ̀lú èmi yóò sì mú wọn wá sí àfonífojì Jehoṣafati. Èmi yóò sì bá wọn wíjọ́ níbẹ̀ nítorí àwọn ènìyàn mi, àti nítorí Israẹli ìní mi, tí wọ́n fọ́nká sí àárín àwọn orílẹ̀-èdè, wọ́n sì pín ilẹ̀ mi.
- Joẹli 3:3nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Wọ́n si ti di ìbò fún àwọn ènìyàn mi; wọ́n sì ti fi ọmọdékùnrin kan fún panṣágà obìnrin kan, wọ́n sì ta ọmọdébìnrin kan fún ọtí wáìnì, kí wọ́n kí ó lè mu.
- Joẹli 3:4nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
“Nísinsin yìí, kí ni ẹ̀yin ní fi mí ṣe Tire àti Sidoni, àti gbogbo ẹ̀yin ẹkún Filistia? Ẹ̀yin yóò ha sàn ẹ̀san fún mi? Bí ẹ̀yin bá sì san ẹ̀san fún mi, ní kánkán àti ní kíákíá ní èmi yóò san ẹ̀san ohun ti ẹ̀yin ṣe padà sórí ara yín.
- Joẹli 3:5nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Nítorí tí ẹ̀yin tí mú fàdákà mi àti wúrà mi, ẹ̀yin si tí mú ohun rere dáradára mi lọ sínú tẹmpili yín.
- Joẹli 3:6nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Àti àwọn ọmọ Juda, àti àwọn ọmọ Jerusalẹmu ní ẹ̀yin ti tà fún àwọn ará Giriki, kí ẹ̀yin bá à lè sí wọn jìnnà kúrò ní agbègbè ilẹ̀ ìní wọn.
- Joẹli 3:7nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
“Kíyèsi í, èmi yóò gbé wọ́n dìde kúrò níbi tì ẹ̀yin ti tà wọ́n sí, èmi yóò sì san ẹ̀san ohun ti ẹ ṣe padà sórí ara yín.
- Joẹli 3:8nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Èmi yóò si tà àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin yín sí ọwọ́ àwọn ọmọ Juda, wọ́n yóò sì tà wọ́n fún àwọn ara Sabeani, fún orílẹ̀-èdè kan tí ó jìnnà réré.” Nítorí Olúwa ní o ti sọ ọ.
- Joẹli 3:9nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Ẹ kéde èyí ní àárín àwọn kèfèrí; ẹ dira ogun, ẹ jí àwọn alágbára. Jẹ kí àwọn ajagun kí wọn bẹ̀rẹ̀ ogun.
- Joẹli 3:10nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Ẹ fi irin ìtulẹ̀ yín rọ idà, àti dòjé yín rọ ọ̀kọ̀. Jẹ́ kí aláìlera wí pé, “Ara mi le koko.”
- Joẹli 3:11nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Ẹ wá kánkán, gbogbo ẹ̀yin kèfèrí láti gbogbo àyíká, kí ẹ sì gbá ara yín jọ yí káàkiri. Níbẹ̀ ní kí o mú àwọn alágbára rẹ sọ̀kalẹ̀, Olúwa.
- Joẹli 3:12nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
“Ẹ jí, ẹ sì gòkè wá sí àfonífojì Jehoṣafati ẹ̀yin kèfèrí: nítorí níbẹ̀ ní èmi yóò jókòó láti ṣe ìdájọ́ àwọn kèfèrí yí káàkiri.
- Joẹli 3:13nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Ẹ tẹ dòjé bọ̀ ọ́, nítorí ìkórè pọ́n. Ẹ wá, ẹ sọ̀kalẹ̀, nítorí ìfúntí kún, nítorí àwọn ọpọ́n kún àkúnwọ́sílẹ̀, nítorí ìwà búburú wọn pọ̀!”
- Joẹli 3:14nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Ọ̀pọ̀lọpọ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní àfonífojì ìpinnu! Nítorí ọjọ́ Olúwa kù si dẹ̀dẹ̀ ní àfonífojì ìdájọ́.
- Joẹli 3:15nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Oòrùn àti òṣùpá yóò ṣú òkùnkùn, àti àwọn ìràwọ̀ kí yóò tan ìmọ́lẹ̀ wọn mọ́.
- Joẹli 3:16nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Olúwa yóò sí ké ramúramù láti Sioni wá, yóò sì fọ ohùn rẹ̀ jáde láti Jerusalẹmu wá; àwọn ọ̀run àti ayé yóò sì mì tìtì. Ṣùgbọ́n Olúwa yóò ṣe ààbò àwọn ènìyàn rẹ̀, àti agbára àwọn ọmọ Israẹli.
- Joẹli 3:17nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
“Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, tí ń gbé Sioni òkè mímọ́ mi. Ìgbà náà ni Jerusalẹmu yóò jẹ́ mímọ́; àwọn àjèjì kì yóò sì kó o mọ́.
- Joẹli 3:18nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
“Ní ọjọ́ náà, àwọn òkè ńlá yóò máa kán ọtí wáìnì tuntun sílẹ̀, àwọn òkè kéékèèké yóò máa sàn fún wàrà; gbogbo odò Juda tí ó gbẹ́ yóò máa sàn fún omi. Orísun kan yóò sì ṣàn jáde láti inú ilé Olúwa wá, yóò sì rin omi sí àfonífojì Ṣittimu.
- Joẹli 3:19nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n Ejibiti yóò di ahoro, Edomu yóò sì di aṣálẹ̀ ahoro, nítorí ìwà ipá tí a hù sì àwọn ọmọ Juda, ní ilẹ̀ ẹni tí wọ́n ti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.
- Joẹli 3:20nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n Juda yóò jẹ́ ibùgbé títí láé, àti Jerusalẹmu láti ìran dé ìran.