- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Amosi 1:1nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Àwọn ọ̀rọ̀ Amosi, ọ̀kan lára àwọn olùṣọ́-àgùntàn Tekoa; ohun tí o rí nípa Israẹli ní ọdún méjì ṣáájú ilẹ̀-rírì, nígbà tí Ussiah ọba Juda àti Jeroboamu ọmọ Jehoaṣi jẹ́ ọba ní ilẹ̀ Israẹli.
- Amosi 1:2nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Ó wí pé, “Olúwa yóò bú jáde láti Sioni, ohùn rẹ̀ yóò sì sán bí àrá láti Jerusalẹmu wá; ibùgbé àwọn olùṣọ́-àgùntàn yóò sì ṣọ̀fọ̀, orí òkè Karmeli yóò sì rọ.”
- Amosi 1:3nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta tí Damasku, àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Nítorí wọn fi ohun èlò ìpakà pa Gileadi. Pẹ̀lú ohun èlò irin tí ó ní eyín mímú,
- Amosi 1:4nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Èmi yóò rán iná sí ilé Hasaeli, èyí ti yóò jó àwọn ààfin Beni-Hadadi run.
- Amosi 1:5nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Èmi yóò ṣẹ́ ọ̀pá ìdábùú Damasku; Èmi yóò sì pa ọba tí ó wà ní àfonífojì Afeni run àti ẹni tí ó di ọ̀pá aládé mú ní Beti-Edeni. Àwọn ará a Aramu yóò lọ sí ìgbèkùn sí Kiri,” ni Olúwa wí.
- Amosi 1:6nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta Gasa, àní nítorí mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Gẹ́gẹ́ bí í oníṣòwò ẹrú, ó kó gbogbo àwọn ènìyàn mi ní ìgbèkùn. Ó sì tà wọ́n fún Edomu,
- Amosi 1:7nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Èmi yóò rán iná sí ara odi Gasa tí yóò jó gbogbo ààfin rẹ̀ run.
- Amosi 1:8nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Èmi yóò ké àwọn olùgbé Aṣdodu kúrò, ti ẹni tí ó di ọ̀pá aládé ní Aṣkeloni mú. Èmi yóò yí ọwọ́ mi sí Ekroni títí tí ìyókù Filistini yóò fi ṣègbé,” ni Olúwa Olódùmarè wí.
- Amosi 1:9nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Tire àní nítorí mẹ́rin, Èmi kì yóò yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Nítorí wọ́n ta gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ìgbèkùn fún Edomu. Wọn kò sì náání májẹ̀mú ọbàkan,
- Amosi 1:10nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Èmi yóò rán iná sí ara odi Tire, tí yóò jó gbogbo àwọn ààfin rẹ̀ run.”
- Amosi 1:11nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta tí Edomu, àní nítorí mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Nítorí òhun fi idà lépa arákùnrin rẹ̀, Ó sì gbé gbogbo àánú sọnù, ìbínú rẹ̀ sì ń faniya títí, ó sì pa ìbínú rẹ̀ bí èéfín mọ́,
- Amosi 1:12nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Èmi yóò rán iná sí orí Temani, tí yóò jó gbogbo ààfin Bosra run.”
- Amosi 1:13nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Ammoni, àní mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Nítorí wọn ti la inú àwọn aboyún Gileadi kí wọ́n ba à lè fẹ ilẹ̀ wọn sẹ́yìn.
- Amosi 1:14nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Èmi yóò rán iná sí ara odi Rabba èyí tí yóò jó àwọn ààfin rẹ̀ run pẹ̀lú ìhó ayọ̀ ní ọjọ́ ogun, pẹ̀lú ìjì líle ni ọjọ́ àjà.
- Amosi 1:15nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Ọba wọn yóò sì lọ sí ìgbèkùn, òun àti àwọn ọmọ-aládé rẹ̀ lápapọ̀,” ni Olúwa wí.
- Amosi 2:1nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Èyí ni ohun tí Olúwa wí, “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Moabu, àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà, nítorí ó ti sun ún, di eérú, egungun ọba Edomu,
- Amosi 2:2nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Èmi yóò rán iná sí orí Moabu èyí tí yóò jó àwọn ààfin Kerioti run. Moabu yóò sì kú pẹ̀lú ariwo pẹ̀lú igbe àti pẹ̀lú ìró ìpè.
- Amosi 2:3nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Èmi yóò ké onídàájọ́ rẹ̀ kúrò, Èmi yóò sì pa gbogbo àwọn ọmọ-aládé rẹ́ nínú rẹ̀,” ni Olúwa wí.
- Amosi 2:4nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Èyí ni ohun tí Olúwa wí, “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Juda, àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Nítorí wọn ti kọ òfin Olúwa sílẹ̀, wọn kò sì pa àwọn ìlànà rẹ̀ mọ́. Nítorí àwọn òrìṣà ti sì wọ́n lọ́nà, òrìṣà tí àwọn Baba ńlá wọn ń tẹ̀lé,
- Amosi 2:5nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Èmi yóò rán iná sí orí Juda èyí tí yóò jó àwọn ààfin Jerusalẹmu run.”
- Amosi 2:6nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta Israẹli àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Wọ́n ta olódodo fún fàdákà àti aláìní fún bàtà ẹsẹ̀ méjèèjì.
- Amosi 2:7nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Wọ́n fi ẹsẹ̀ tẹ orí àwọn tálákà mọ́lẹ̀, bí wọ́n ti ń tẹ erùpẹ̀ ilẹ̀ tí wọ́n ko sì ṣe òtítọ́ si àwọn tí a ni lára. Baba àti ọmọ ń wọlé tọ wúńdíá kan náà, láti ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́.
- Amosi 2:8nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Wọ́n dùbúlẹ̀ lẹ́bàá a pẹpẹ, lórí aṣọ tí wọ́n fi jẹ́ ẹ̀jẹ́ ní ilé òrìṣà wọn wọ́n sì mu ọtí tí wọ́n san fún ìtánràn.
- Amosi 2:9nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
“Mo pa àwọn ará Amori run níwájú wọn gíga ẹni tí ó dàbí igi kedari. Òun sì le koko bí igi óákù mo pa èso rẹ̀ run láti òkè wá àti egbò rẹ̀ láti ìsàlẹ̀ wá.
- Amosi 2:10nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá, mo sì sìn yín la aginjù já ní ogójì ọdún láti fi ilẹ̀ àwọn ará Amori fún un yín.