Fò sí àkóónú

circa 800–400 BC

The Hebrew Prophets

God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.

3,706 ẹsẹ · 14 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Mika 1:1nǹkan bí 750 ṣáájú Kristi

    Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Mika ará Moreṣeti wá ní àkókò ìjọba Jotamu, Ahasi, àti Hesekiah, àwọn ọba Juda nìwọ̀nyí, ìran tí ó rí nípa Samaria àti Jerusalẹmu.

  2. Mika 1:2nǹkan bí 750 ṣáájú Kristi

    Ẹ gbọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn, fetísílẹ̀, ìwọ ayé àti gbogbo ohun tó wà níbẹ̀, kí Olúwa Olódùmarè lè ṣe ẹlẹ́rìí sí yín, Olúwa láti inú tẹmpili mímọ́ rẹ̀ wá.

  3. Mika 1:3nǹkan bí 750 ṣáájú Kristi

    Wò ó! Olúwa ń bọ̀ wá láti ibùgbé rẹ̀; yóò sọ̀kalẹ̀, yóò sì tẹ ibi gíga ayé mọ́lẹ̀.

  4. Mika 1:4nǹkan bí 750 ṣáájú Kristi

    Àwọn òkè ńlá yóò sí yọ́ lábẹ́ rẹ̀, àwọn àfonífojì yóò sì pínyà, bí idà níwájú iná, bí omi tí ó ń sàn lọ ni ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́.

  5. Mika 1:5nǹkan bí 750 ṣáájú Kristi

    Nítorí ìré-òfin-kọjá Jakọbu ni gbogbo èyí, àti nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli. Kí ni ìré-òfin-kọjá Jakọbu? Ǹjẹ́ Samaria ha kọ? Kí ni àwọn ibi gíga Juda? Ǹjẹ́ Jerusalẹmu ha kọ?

  6. Mika 1:6nǹkan bí 750 ṣáájú Kristi

    “Nítorí náà, èmi yóò ṣe Samaria bí òkìtì lórí pápá, bí ibi ti à ń lò fún gbígbin ọgbà àjàrà. Èmi yóò gbá àwọn òkúta rẹ̀ dànù sínú àfonífojì. Èmi yóò sí tú ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ palẹ̀.

  7. Mika 1:7nǹkan bí 750 ṣáájú Kristi

    Gbogbo àwọn ère fínfín rẹ̀ ni a ó fọ́ sí wẹ́wẹ́ gbogbo àwọn ẹ̀bùn tẹmpili rẹ̀ ni a ó fi iná sun, Èmi yóò sì pa gbogbo àwọn òrìṣà rẹ̀ run. Nítorí tí ó ti kó àwọn ẹ̀bùn rẹ̀ jọ láti inú owó èrè panṣágà, gẹ́gẹ́ bí owó èrè panṣágà, wọn yóò sì tún padà sí owó iṣẹ́ panṣágà.”

  8. Mika 1:8nǹkan bí 750 ṣáájú Kristi

    Nítorí èyí, èmi yóò sì sọkún, èmi yóò sì pohùnréré ẹkún: èmi yóò máa lọ ní ẹsẹ̀ lásán àti ní ìhòhò. Èmi yóò ké bí akátá, èmi yóò sì máa dárò bí àwọn ọmọ ògòǹgò.

  9. Mika 1:9nǹkan bí 750 ṣáájú Kristi

    Nítorí tí ọgbẹ́ rẹ̀ jẹ́ aláìlèwòtán; ó sì ti wá sí Juda. Ó sì ti dé ẹnu-bodè àwọn ènìyàn mi, àní sí Jerusalẹmu.

  10. Mika 1:10nǹkan bí 750 ṣáájú Kristi

    Ẹ má ṣe sọ ní Gati ẹ má ṣe sọkún rárá. Ní ilẹ̀ Beti-Ofra mo yí ara mi nínú eruku.

  11. Mika 1:11nǹkan bí 750 ṣáájú Kristi

    Ẹ kọjá lọ ni ìhòhò àti ni ìtìjú, ìwọ tí ó ń gbé ni Ṣafiri. Àwọn tí ó ń gbé ni Saanani kì yóò sì jáde wá. Beti-Eseli wà nínú ọ̀fọ̀; a ó sì gba ààbò rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ yin.

  12. Mika 1:12nǹkan bí 750 ṣáájú Kristi

    Nítorí àwọn tí ó ń gbé ni Marati ń retí ìre, ṣùgbọ́n ibi sọ̀kalẹ̀ ti ọ̀dọ̀ Olúwa wá sí ẹnu-bodè Jerusalẹmu.

  13. Mika 1:13nǹkan bí 750 ṣáájú Kristi

    Ìwọ olùgbé Lakiṣi, dì kẹ̀kẹ́ mọ́ ẹranko tí ó yára. Òun sì ni ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ sí àwọn ọmọbìnrin Sioni, nítorí a rí àìṣedéédéé Israẹli nínú rẹ̀.

  14. Mika 1:14nǹkan bí 750 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà ni ìwọ ó ṣe fi ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fún Moreṣeti Gati. Àwọn ilé Aksibu yóò jẹ́ ẹlẹ́tàn sí àwọn ọba Israẹli.

  15. Mika 1:15nǹkan bí 750 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò sì mú àrólé kan wá sórí rẹ ìwọ olùgbé Meraṣa. Ẹni tí ó jẹ́ ògo Israẹli yóò sì wá sí Adullamu.

  16. Mika 1:16nǹkan bí 750 ṣáájú Kristi

    Fá irun orí rẹ nínú ọ̀fọ̀ nítorí àwọn ọmọ rẹ aláìlágbára, sọ ra rẹ̀ di apárí bí ẹyẹ igún, nítorí wọn yóò kúrò lọ́dọ̀ rẹ lọ sí ìgbèkùn.

  17. Mika 2:1nǹkan bí 730 ṣáájú Kristi

    Ègbé ni fún àwọn tí ń gbèrò àìṣedéédéé tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ ibi lórí ibùsùn wọn! Nígbà tí ojúmọ́ bá mọ́, wọn yóò gbé e jáde nítorí ó wà ní agbára wọn láti ṣe é.

  18. Mika 2:2nǹkan bí 730 ṣáájú Kristi

    Wọ́n sì ń ṣe ojúkòkòrò oko, wọ́n sì fi agbára wọn gbà wọ́n, àti àwọn ilé, wọ́n sì gbà wọ́n. Wọ́n sì ni ènìyàn àti ilẹ̀ rẹ̀ lára àní ènìyàn àti ohun ìní rẹ̀.

  19. Mika 2:3nǹkan bí 730 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà, Olúwa wí pé: “Èmi ń gbèrò ibi sí àwọn ìdílé wọ̀nyí, nínú èyí tí wọn kì yóò le è gba ara wọn là. Ìwọ kì yóò sì lè máa rìn ní ìgbéraga mọ́, nítorí yóò jẹ́ àkókò ibi.

  20. Mika 2:4nǹkan bí 730 ṣáájú Kristi

    Ní ọjọ́ náà ni ẹnìkan yóò pa òwe kan sí yín; wọn yóò sì pohùnréré ẹkún kíkorò pé: ‘Ní kíkó a ti kó wọn tán; Olúwa ti pín ohun ìní àwọn ènìyàn mi; Ó ti mú un kúrò lọ́dọ̀ mi! Ó fi oko wa lé àwọn ọlọ̀tẹ̀ lọ́wọ́.’ ”

  21. Mika 2:5nǹkan bí 730 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà, ìwọ kò ní ní ẹnìkankan tí yóò ta okùn nínú ìjọ Olúwa, tí yóò pín ilẹ̀ nípa ìbò.

  22. Mika 2:6nǹkan bí 730 ṣáájú Kristi

    “Ẹ má ṣe sọtẹ́lẹ̀,” ni àwọn wòlíì wọn wí. “Ẹ má ṣe sọtẹ́lẹ̀ nípa nǹkan wọ̀nyí; kí ìtìjú má ṣe le bá wa.”

  23. Mika 2:7nǹkan bí 730 ṣáájú Kristi

    Ṣé kí á sọ ọ́, ìwọ ilé Jakọbu: “Ǹjẹ́ ẹ̀mí Olúwa ha ń bínú bí? Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ ha nìwọ̀nyí?” “Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ mi kò ha ń ṣe rere fún ẹni tí ń rìn déédé bí?

  24. Mika 2:8nǹkan bí 730 ṣáájú Kristi

    Láìpẹ́ àwọn ènìyàn mi dìde bí ọ̀tá sí mi. Ìwọ bọ́ aṣọ ọlọ́rọ̀ kúrò lára àwọn tí ń kọjá lọ ní àìléwu, bí àwọn ẹni tí ó padà bọ̀ láti ojú ogun.

  25. Mika 2:9nǹkan bí 730 ṣáájú Kristi

    Ẹ̀yin sì lé obìnrin àwọn ènìyàn mi kúrò nínú ilé ayọ̀ wọn, ẹ̀yin sì ti gba ògo mi, kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ wọn láéláé.