- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Joẹli 1:1nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Joẹli ọmọ Petueli wá.
- Joẹli 1:2nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Ẹ gbọ́ èyí ẹ̀yin àgbàgbà; ẹ fi etí sílẹ̀ gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ará ilẹ̀ náà. Ǹjẹ́ irú èyí ha wà ní ọjọ́ yín, tàbí ní ọjọ́ àwọn baba yín?
- Joẹli 1:3nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Ẹ sọ ọ́ fún àwọn ọmọ yín, ki àwọn ọmọ yín sọ fún àwọn ọmọ wọn, ki àwọn ọmọ wọn sọ fún àwọn ìran mìíràn.
- Joẹli 1:4nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Èyí tí eṣú tí agénijẹ jẹ kù ní ọ̀wọ́ eṣú ńlá ńlá ti jẹ, èyí tí ọ̀wọ́ eṣú ńlá ńlá jẹ kù ní eṣú kéékèèké jẹ, èyí tí eṣú kéékèèké jẹ kù ni eṣú apanirun mìíràn jẹ.
- Joẹli 1:5nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Ẹ jí gbogbo ẹ̀yin ọ̀mùtí kí ẹ sì sọkún ẹ hu gbogbo ẹ̀yin ọ̀mu-wáìnì; ẹ hu nítorí wáìnì tuntun nítorí a gbà á kúrò lẹ́nu yín.
- Joẹli 1:6nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Nítorí orílẹ̀-èdè kan ti ṣígun sí ilẹ̀ mìíràn ó ní agbára púpọ̀, kò sì ní òǹkà; ó ní eyín kìnnìún ó sì ní èrìgì abo kìnnìún.
- Joẹli 1:7nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Ó ti pa àjàrà mi run, ó sì ti ya ẹ̀ka igi ọ̀pọ̀tọ́ mi kúrò, ó ti bò èèpo rẹ̀ jálẹ̀, ó sì sọ ọ́ nù; àwọn ẹ̀ka rẹ̀ ni a sì sọ di funfun.
- Joẹli 1:8nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Ẹ pohùnréré ẹkún bí wúńdíá tí a fi aṣọ ọ̀fọ̀ dí ni àmùrè, nítorí ọkọ ìgbà èwe rẹ̀.
- Joẹli 1:9nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
A ké ọrẹ jíjẹ́ àti ọrẹ mímu kúrò ní ilé Olúwa. Àwọn àlùfáà ń ṣọ̀fọ̀, àwọn ìránṣẹ́ Olúwa.
- Joẹli 1:10nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Oko di ìgboro, ilẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀, nítorí a fi ọkà ṣòfò: ọtí wáìnì tuntun gbẹ, òróró ń bùṣe.
- Joẹli 1:11nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Kí ojú kí ó tì yín, ẹ̀yin àgbẹ̀; ẹ pohùnréré ẹkún ẹ̀yin olùtọ́jú àjàrà, nítorí alikama àti nítorí ọkà barle; nítorí ìkórè oko ṣègbé.
- Joẹli 1:12nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Àjàrà gbẹ, igi ọ̀pọ̀tọ́ sì rọ̀ dànù; igi pomegiranate, igi ọ̀pẹ pẹ̀lú, àti igi apiili, gbogbo igi igbó ni o rọ. Nítorí náà ayọ̀ ọmọ ènìyàn gbẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn.
- Joẹli 1:13nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Ẹ di ara yín ni àmùrè, sí pohùnréré ẹkún ẹ̀yin àlùfáà: ẹ pohùnréré ẹkún, ẹ̀yin ìránṣẹ́ pẹpẹ: ẹ wá, fi gbogbo òru dùbúlẹ̀ nínú aṣọ ọ̀fọ̀, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Ọlọ́run mi, nítorí tí a dá ọrẹ-jíjẹ àti ọrẹ mímu dúró ní ilé Ọlọ́run yín.
- Joẹli 1:14nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Ẹ yà àwẹ̀ kan sí mímọ́, ẹ pe àjọ kan tí o ní ìrònú, ẹ pe àwọn àgbàgbà, àti gbogbo àwọn ará ilẹ̀ náà jọ sí ilé Olúwa Ọlọ́run yín, kí ẹ sí ké pe Olúwa.
- Joẹli 1:15nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
A! Fún ọjọ́ náà, nítorí ọjọ́ Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀, yóò de bí ìparun láti ọwọ́ Olódùmarè.
- Joẹli 1:16nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
A kò ha ké oúnjẹ kúrò níwájú ojú wá yìí, ayọ̀ àti inú dídùn kúrò nínú ilé Ọlọ́run wá?
- Joẹli 1:17nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Irúgbìn bàjẹ́ nínú ebè wọn, a sọ àká di ahoro, a wó àká palẹ̀; nítorí tí a mú ọkà rọ.
- Joẹli 1:18nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Àwọn ẹranko tí ń kérora tó! Àwọn agbo ẹran dààmú, nítorí tí wọ́n kò ni pápá oko; nítòótọ́, àwọn agbo àgùntàn jìyà.
- Joẹli 1:19nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Olúwa, sí ọ ni èmi o ké pè, nítorí iná tí run pápá oko tútù aginjù, ọwọ́ iná sí ti jó gbogbo igi igbó.
- Joẹli 1:20nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Àwọn ẹranko igbó gbé ojú sókè sí ọ pẹ̀lú, nítorí tí àwọn ìṣàn omi gbẹ, iná sí ti jó àwọn pápá oko aginjù run.
- Joẹli 2:1nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Ẹ fun ìpè ní Sioni, ẹ sì fún ìpè ìdágìrì ní òkè mímọ́ mi. Jẹ́ kí àwọn ará ilẹ̀ náà wárìrì, nítorí tí ọjọ́ Olúwa ń bọ̀ wá, nítorí ó kù sí dẹ̀dẹ̀.
- Joẹli 2:2nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Ọjọ́ òkùnkùn àti ìrọ́kẹ̀kẹ̀, ọjọ́ ìkùùkuu àti òkùnkùn biribiri. Bí ọyẹ́ òwúrọ̀ ti í la bo orí àwọn òkè ńlá: àwọn ènìyàn ńlá àti alágbára; ya dé, ti kó ti ì sí irú rẹ̀ rí, bẹ́ẹ̀ ni irú rẹ̀ kì yóò sí mọ́ lẹ́yìn rẹ̀, títí dé ọdún ìran dé ìran.
- Joẹli 2:3nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Iná ń jó níwájú wọ́n; ọwọ́ iná sì ń jó lẹ́yìn wọn. Ilẹ̀ náà dàbí ọgbà Edeni níwájú wọn, àti lẹ́yìn wọn bí ahoro ijù; nítòótọ́, kò sì sí ohun tí yóò bọ́ lọ́wọ́ wọn.
- Joẹli 2:4nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Ìrí wọn dàbí ìrí àwọn ẹṣin; wọ́n ń sáré lọ bí àwọn ẹlẹ́ṣin ogun.
- Joẹli 2:5nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Bí ariwo kẹ̀kẹ́ ogun ni wọn ń fo ní orí òkè bí ariwo ọ̀wọ́-iná tí ń jó koríko gbígbẹ, bí akọni ènìyàn tí a kójọ fún ogun.