- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Sefaniah 1:1nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Sefaniah ọmọ Kuṣi, ọmọ Gedaliah, ọmọ Amariah, ọmọ Hesekiah, ní ìgbà Josiah ọmọ Amoni ọba Juda.
- Sefaniah 1:2nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
“Èmi yóò mú gbogbo nǹkan kúrò lórí ilẹ̀ náà pátápátá,” ni Olúwa wí.
- Sefaniah 1:3nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
“Èmi yóò mú ènìyàn àti ẹranko kúrò; èmi yóò mú àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run kúrò, àti ẹja inú Òkun, àti ohun ìdìgbòlù pẹ̀lú àwọn ènìyàn búburú; èmi yóò ké ènìyàn kúrò lórí ilẹ̀ ayé,” ni Olúwa wí.
- Sefaniah 1:4nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
“Èmi yóò na ọwọ́ mi sórí Juda àti sórí gbogbo àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Jerusalẹmu. Èmi yóò sì ké kúrò níhìn-ín yìí ìyókù àwọn Baali, àti orúkọ àwọn abọ̀rìṣà pẹ̀lú àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà,
- Sefaniah 1:5nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ lórí òrùlé, àwọn tí ń sin ogun ọ̀run, àwọn tó ń foríbalẹ̀, tí wọ́n sì ń fi Olúwa búra, tí wọ́n sì ń fi Moleki búra.
- Sefaniah 1:6nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
Àwọn tí ó yípadà kúrò lọ́dọ̀ Olúwa; àti àwọn tí kò tí wá Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì béèrè rẹ̀.”
- Sefaniah 1:7nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Olúwa Olódùmarè, nítorí tí ọjọ́ Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀. Olúwa ti pèsè ẹbọ kan sílẹ̀, ó sì ti ya àwọn alápèjẹ rẹ̀ sí mímọ́.
- Sefaniah 1:8nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
“Ní ọjọ́ ẹbọ Olúwa, Èmi yóò bẹ àwọn olórí wò, àti àwọn ọmọ ọba ọkùnrin, pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó wọ àjèjì aṣọ.
- Sefaniah 1:9nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ náà, èmi yóò fi ìyà jẹ gbogbo àwọn tí ó yẹra láti rìn lórí ìloro ẹnu-ọ̀nà, tí wọ́n sì kún tẹmpili àwọn ọlọ́run wọn pẹ̀lú ìwà ipá àti ẹ̀tàn.
- Sefaniah 1:10nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
“Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí, “Ohùn ẹkún yóò wà láti ìhà ibodè ẹja, híhu láti ìhà kejì wá àti ariwo ńlá láti òkè kékeré wá.
- Sefaniah 1:11nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
Ẹ hu, ẹ̀yin tí ń gbé ní agbègbè ọjà, gbogbo àwọn oníṣòwò rẹ̀ ni a ó mú kúrò, gbogbo àwọn ẹni tí ó ń ra fàdákà ni a ó sì parun.
- Sefaniah 1:12nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
Ní àkókò wọ̀n-ọn-nì, èmi yóò wá Jerusalẹmu kiri pẹ̀lú fìtílà, èmi ó sì fi ìyà jẹ àwọn tí kò ní ìtẹ́lọ́rùn, tí wọn sì dàbí àwọn ènìyàn tí ó sinmi sínú gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ wọn, àwọn tí wọn sì ń wí ní ọkàn wọn pé, ‘Olúwa kì yóò ṣe nǹkan kan tí ó jẹ́ rere tàbí tí ó jẹ́ búburú.’
- Sefaniah 1:13nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
Nítorí náà, ọrọ̀ wọn yóò di ìkógun, àti ilé wọn yóò sì run. Àwọn yóò sì kọ́ ilé pẹ̀lú, ṣùgbọ́n wọn kì yóò gbé nínú ilé náà, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, ṣùgbọ́n wọn kì yóò mu ọtí wáìnì láti inú rẹ̀.”
- Sefaniah 1:14nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
“Ọjọ́ ńlá Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀, ó kù sí dẹ̀dẹ̀ ó sì ń yára bọ̀ kánkán. Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, ohùn ẹkún àwọn alágbára; ní ọjọ́ Olúwa yóò korò púpọ̀,
- Sefaniah 1:15nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
ọjọ́ náà yóò jẹ́ ọjọ́ ìbínú, ọjọ́ ìrora àti ìpọ́njú, ọjọ́ òfò àti idà ọjọ́ ìdahoro ọjọ́ òkùnkùn àti ìtẹ̀ba, ọjọ́ kurukuru àti òkùnkùn biribiri,
- Sefaniah 1:16nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
ọjọ́ ìpè àti ìpè ogun sí àwọn ìlú olódi àti sí àwọn ilé ìṣọ́ gíga.
- Sefaniah 1:17nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
“Èmi yóò sì mú ìpọ́njú wá sórí ènìyàn, wọn yóò sì máa rìn gẹ́gẹ́ bí afọ́jú, nítorí àwọn ti dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa. Ẹ̀jẹ̀ wọn ni a ó sì tú jáde bí eruku àti ẹran-ara wọn bí ìgbẹ́.
- Sefaniah 1:18nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
Bẹ́ẹ̀ ni fàdákà tàbí wúrà wọn kì yóò sì le gbà wọ́n là ní ọjọ́ ìbínú Olúwa.” Ṣùgbọ́n gbogbo ayé ni a ó fi iná ìjowú rẹ̀ parun, nítorí òun yóò fi ìyára fi òpin sí gbogbo àwọn tí ń gbé ní ilẹ̀ ayé.
- Sefaniah 2:1nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
Ẹ kó ara yín jọ pọ̀, àní ẹ kó ra yín jọ pọ̀ orílẹ̀-èdè tí kò ní ìtìjú,
- Sefaniah 2:2nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
kí a tó pa àṣẹ náà, kí ọjọ́ náà tó kọjá bí ìyàngbò ọkà, kí gbígbóná ìbínú Olúwa tó dé bá a yín, kí ọjọ́ ìbínú Olúwa kí ó tó dé bá a yín.
- Sefaniah 2:3nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
Ẹ wá Olúwa, gbogbo ẹ̀yin onírẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ náà, ẹ̀yin tí ń ṣe ohun tí ó bá pàṣẹ. Ẹ wá òdodo, ẹ wá ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú, bóyá á ó pa yín mọ́ ní ọjọ́ ìbínú Olúwa.
- Sefaniah 2:4nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
Nítorí pé, a ó kọ Gasa sílẹ̀, Aṣkeloni yóò sì dahoro. Ní ọ̀sán gangan ni a ó lé Aṣdodu jáde, a ó sì fa Ekroni tu kúrò.
- Sefaniah 2:5nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ń gbé etí Òkun, ẹ̀yin ènìyàn ara Kereti; ọ̀rọ̀ Olúwa dojúkọ ọ́, ìwọ Kenaani, ilẹ̀ àwọn ara Filistini. “Èmi yóò pa yín run, ẹnìkan kò sì ní ṣẹ́kù nínú yín.”
- Sefaniah 2:6nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
Ilẹ̀ náà ní etí Òkun, ni ibùgbé àwọn ará Kereti, ni yóò jẹ́ ibùjókòó fún àwọn olùṣọ́-àgùntàn àti agbo àgùntàn.
- Sefaniah 2:7nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
Agbègbè náà yóò sì jẹ́ ti ìyókù àwọn ilé Juda, níbẹ̀ ni wọn yóò sì ti rí koríko fún ẹran. Ní ilé Aṣkeloni ni wọn yóò dùbúlẹ̀ ni àṣálẹ́. Olúwa Ọlọ́run wọn yóò bẹ̀ wọn wò, yóò sì yí ìgbèkùn wọn padà.