Fò sí àkóónú

circa 800–400 BC

The Hebrew Prophets

God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.

3,706 ẹsẹ · 14 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nahumu 1:1nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi

    Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ nípa Ninefe. Ìwé ìran Nahumu ará Elkoṣi.

  2. Nahumu 1:2nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi

    Ọlọ́run ń jẹ owú, ó sì ń gbẹ̀san, Olúwa ń gbẹ̀san, ó sì kún fún ìbínú. Olúwa ń gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀. Ìbínú rẹ̀ kò sì yí padà lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀.

  3. Nahumu 1:3nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi

    Olúwa lọ́ra láti bínú, ó sì tóbi ní agbára; Olúwa kì yóò fi àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sílẹ̀ láìjìyà. Ọ̀nà rẹ̀ wà nínú afẹ́fẹ́ àti nínú ìjì, ìkùùkuu sánmọ̀ sì ni eruku ẹsẹ̀ rẹ̀.

  4. Nahumu 1:4nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi

    Ó bá òkun wí, ó sì mú kí ó gbẹ; Ó sìsọ gbogbo odò di gbígbẹ. Baṣani àti Karmeli sì rọ. Ìtànná Lebanoni sì rẹ̀ sílẹ̀.

  5. Nahumu 1:5nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi

    Àwọn òkè ńlá wárìrì níwájú rẹ̀, àwọn òkè kéékèèké sì di yíyọ́, ilẹ̀ ayé sì jóná níwájú rẹ̀, àní ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.

  6. Nahumu 1:6nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi

    Ta ni ó lé dúró níwájú ìbínú rẹ̀? Ta ni ó lé faradà gbígbóná ìbínú rẹ̀? Ìbínú rẹ̀ tú jáde bí iná; àwọn àpáta sì fọ́ túútúú níwájú rẹ̀.

  7. Nahumu 1:7nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi

    Rere ni Olúwa, òun ni ààbò ní ọjọ́ ìpọ́njú. Òun sì tọ́jú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e,

  8. Nahumu 1:8nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi

    ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìkún omi ńlá ní òun yóò fi ṣe ìparun láti ibẹ̀ dé òpin; òkùnkùn yóò sì máa lépa àwọn ọ̀tá rẹ̀.

  9. Nahumu 1:9nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi

    Kí ni ẹ̀yìn ń gbìmọ̀ lòdì sí Olúwa? Òun yóò fi òpin sí i, ìpọ́njú kì yóò wáyé ní ìgbà kejì.

  10. Nahumu 1:10nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi

    Wọn yóò sì lọ́lù papọ̀ bí ẹ̀gún òṣùṣú wọn yóò sì mu àmupara nínú ọtí wáìnì wọn a ó sì run wọn gẹ́gẹ́ bi àgékù koríko gbígbẹ.

  11. Nahumu 1:11nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi

    Láti ọ̀dọ̀ rẹ, ìwọ Ninefe, ni ẹnìkan ti jáde wá tí ó ń gbèrò ibi sí Olúwa ti ó sì ń gbìmọ̀ búburú.

  12. Nahumu 1:12nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi

    Báyìí ni Olúwa wí: “Bí wọ́n tilẹ̀ ni ìfọwọ́sowọ́pọ̀, tí wọ́n sì pọ̀ níye, ṣùgbọ́n, báyìí ní a ó ké wọn lulẹ̀, nígbà tí òun ó bá kọjá. Bí mo tilẹ̀ ti pọ́n ọ lójú ìwọ Juda, èmi kì yóò pọ́n ọ lójúmọ́.

  13. Nahumu 1:13nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi

    Nísinsin yìí ni èmi yóò já àjàgà wọn kúrò ní ọrùn rẹ èmi yóò já ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ rẹ dànù.”

  14. Nahumu 1:14nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi

    Olúwa ti fi àṣẹ kan lélẹ̀ nítorí tìrẹ Ninefe: “Ìwọ kì yóò ni irú-ọmọ láti máa jẹ́ orúkọ rẹ mọ́, Èmi yóò pa ère fínfín àti ère dídà run tí ó wà nínú tẹmpili àwọn ọlọ́run rẹ. Èmi yóò wa ibojì rẹ, nítorí ẹ̀gbin ni ìwọ.”

  15. Nahumu 1:15nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi

    Wò ó, lórí àwọn òkè, àwọn ẹsẹ̀ ẹni tí ó mú ìròyìn ayọ̀ wá, ẹni tí ó ń kéde àlàáfíà. Ìwọ Juda, pa àṣẹ rẹ tí ó ní ìrònú mọ́, kí ó sì san àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ. Àwọn ènìyàn búburú kì yóò sì gbóguntì ọ́ mọ́; wọn yóò sì parun pátápátá.

  16. Nahumu 2:1nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi

    Àwọn apanirun ti dìde sí ọ, ìwọ Ninefe. Pa ilé ìṣọ́ mọ́, ṣọ́ ọ̀nà náà, di àmùrè, ẹ̀gbẹ́ rẹ kí ó le múra gírí.

  17. Nahumu 2:2nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi

    Olúwa yóò mú ọláńlá Jakọbu padà sípò gẹ́gẹ́ bí ọláńlá Israẹli bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn apanirun ti pa ibẹ̀ run, tí wọ́n sì ba ẹ̀ka àjàrà wọn jẹ́.

  18. Nahumu 2:3nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi

    Asà àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sì di pupa; àwọn ológun wọn sì wọ aṣọ òdòdó. Idẹ tí ó wà lórí kẹ̀kẹ́ ogun ń kọ mọ̀nàmọ́ná ní ọjọ́ tí a bá pèsè wọn sílẹ̀ tán; igi firi ni a ó sì mì tìtì.

  19. Nahumu 2:4nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi

    Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun yóò ya bo àwọn pópónà, wọn yóò sì máa sáré síwá àti sẹ́yìn ní àárín ìgboro. Wọn sì dàbí ètùfù iná; tí ó sì kọ bí i mọ̀nàmọ́ná.

  20. Nahumu 2:5nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi

    Ninefe yóò ṣe àṣàrò àwọn ọlọ́lá rẹ̀; síbẹ̀ wọ́n ń kọsẹ̀ ní ojú ọ̀nà wọn; wọn sáré lọ sí ibi odi rẹ̀, a ó sì pèsè ààbò rẹ̀.

  21. Nahumu 2:6nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi

    A ó ṣí ìlẹ̀kùn àwọn odò wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀, a ó sì mú ààfin náà di wíwó palẹ̀.

  22. Nahumu 2:7nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi

    A pa á láṣẹ pé ìlú náà, èyí tí a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ ni a ó sì kó ní ìgbèkùn lọ. A ó sì mú un gòkè wá àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ yóò kérora bí ti ẹyẹ àdàbà, wọn a sì máa lu àyà wọn.

  23. Nahumu 2:8nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi

    Ninefe dàbí adágún omi, tí omi rẹ̀ sì ń gbẹ́ ẹ lọ. “Dúró! Dúró!” ni wọ́n ó máa kígbe, ṣùgbọ́n ẹnìkankan kì yóò wo ẹ̀yìn.

  24. Nahumu 2:9nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi

    “Ẹ kó ìkógun fàdákà! Ẹ kó ìkógun wúrà! Ìṣúra wọn ti kò lópin náà, àti ọrọ̀ kúrò nínú gbogbo ohun èlò ti a fẹ́!”

  25. Nahumu 2:10nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi

    Òun ti ṣòfò, ó si di asán, ó sì di ahoro: ọkàn pami, eékún ń lu ara wọn, ìrora púpọ̀ sì wà nínú gbogbo ẹgbẹ́ àti ojú gbogbo wọ́n sì rẹ̀wẹ̀sì.