Fò sí àkóónú

circa 800–400 BC

The Hebrew Prophets

God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.

3,706 ẹsẹ · 14 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Malaki 4:1nǹkan bí 397 ṣáájú Kristi

    “Dájúdájú, ọjọ́ náà ń bọ̀; tí yóò máa jó bi iná ìléru. Gbogbo àwọn agbéraga, àti gbogbo àwọn olùṣe búburú yóò dàbí àgékù koríko: ọjọ́ náà tí ń bọ̀ yóò si jó wọn run,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “Ti ki yóò fi kù gbòǹgbò kan tàbí ẹ̀ka kan fún wọn.

  2. Malaki 4:2nǹkan bí 397 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n fún ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù orúkọ mi, oòrùn òdodo yóò yọ, pẹ̀lú ìmúláradá ni ìyẹ́ apá rẹ̀. Ẹ̀yin yóò sì jáde lọ, ẹ̀yin yóò sì máa fò fún ayọ̀ bi àwọn ẹgbọrọ màlúù tí a tú sílẹ̀ lórí ìso.

  3. Malaki 4:3nǹkan bí 397 ṣáájú Kristi

    Ẹ̀yin yóò sì tẹ àwọn ènìyàn búburú mọ́lẹ̀: nítorí wọn yóò di eérú lábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ yín, ní ọjọ́ náà tí èmi yóò ṣe nǹkan wọ̀nyí,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

  4. Malaki 4:4nǹkan bí 397 ṣáájú Kristi

    “Ẹ rántí òfin Mose ìránṣẹ́ mi, àwọn ìlànà àti òfin èyí tí mo fún un ní Horebu fún gbogbo Israẹli.”

  5. Malaki 4:5nǹkan bí 397 ṣáájú Kristi

    “Wò ó, èmi yóò rán wòlíì Elijah sí i yín, ki ọjọ́ ńlá, ọjọ́ ẹ̀rù Olúwa to dé.

  6. Malaki 4:6nǹkan bí 397 ṣáájú Kristi

    Òun yóò sì pa ọkàn àwọn baba dà sí ti àwọn ọmọ, àti ọkàn àwọn ọmọ sì ti àwọn baba wọn, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, èmi yóò wá, èmi yóò sì fi ilẹ̀ náà gégùn.”