Fò sí àkóónú

circa 800–400 BC

The Hebrew Prophets

God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.

3,706 ẹsẹ · 14 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Malaki 2:11nǹkan bí 397 ṣáájú Kristi

    Juda ti ń hùwà àrékérekè, a sì ti hùwà ìríra ní Israẹli àti ni Jerusalẹmu: nítorí Juda tí sọ ìwà mímọ́ Olúwa di aláìmọ́, èyí tí ó fẹ́, nípa gbígbé ọmọbìnrin ọlọ́run àjèjì ni ìyàwó.

  2. Malaki 2:12nǹkan bí 397 ṣáájú Kristi

    Ní ti ẹni tí ó ṣe èyí, ẹni tí ó wù kí ó jẹ, kí Olúwa kí ó gé e kúrò nínú àgọ́ Jakọbu, bí ó tilẹ̀ mú ẹbọ ọrẹ wá fún Olúwa àwọn ọmọ-ogun.

  3. Malaki 2:13nǹkan bí 397 ṣáájú Kristi

    Èyí ni ohun mìíràn tí ẹ̀yin sì túnṣe. Ẹ̀yin fi omijé bo pẹpẹ Olúwa mọ́lẹ̀. Ẹ̀yin sọkún, ẹ̀yin sì ba ara jẹ́ nítorí tì Òun kò ka ọrẹ yín sí mọ́, tàbí kí ó fi inú dídùn gba nǹkan yìí lọ́wọ́ yín.

  4. Malaki 2:14nǹkan bí 397 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, “Nítorí kín ní?” Nítorí Olúwa ti ṣe ẹlẹ́rìí láàrín ìwọ àti láàrín aya èwe rẹ, ẹni tí ìwọ ti ń hùwà ẹ̀tàn sí i: bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkejì rẹ ni òun jẹ́, àti aya májẹ̀mú rẹ.

  5. Malaki 2:15nǹkan bí 397 ṣáájú Kristi

    Ọlọ́run kò ha ti ṣe wọ́n ní ọ̀kan? Ni ara àti ni ẹ̀mí tirẹ̀ ni. Èéṣe tí Ọlọ́run da yín lọ́kàn? Kí òun bá à lè wá irú-ọmọ bí ti Ọlọ́run. Nítorí náà, ẹ tọ́jú ẹ̀mí yín, ẹ má sì ṣe hùwà ẹ̀tàn sí aya èwe yín.

  6. Malaki 2:16nǹkan bí 397 ṣáájú Kristi

    “Ọkùnrin tí ó bá kórìíra, tí ó sì kọ ìyàwó rẹ̀,” se ìwà ipá sí ẹni tí ó yẹ kí ó dá ààbò bò, ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí, Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ ẹ̀mí yín, kí ẹ má ṣe hùwà ẹ̀tàn.

  7. Malaki 2:17nǹkan bí 397 ṣáájú Kristi

    Ẹ̀yin ti fi ọ̀rọ̀ yín dá Olúwa ní agara. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèrè pé, “Nínú kín ni àwa fi dá a ní agara?” Nígbà tí ẹ̀yìn wí pé, “Gbogbo ẹni tí ó ṣe ibi, rere ni níwájú Olúwa, inú rẹ̀ sì dùn sí wọn,” tàbí “Níbo ni Ọlọ́run ìdájọ́ gbé wà?”

  8. Malaki 3:1nǹkan bí 397 ṣáájú Kristi

    “Wò ó, Èmi yóò ran ìránṣẹ́ mi, yóò tún ọ̀nà ṣe ṣáájú mi. Nígbà náà ni Olúwa, tí ẹ̀yin ń wa, yóò dé ni òjijì sí tẹmpili rẹ̀; àní oníṣẹ́ májẹ̀mú náà, tí inú yín dùn sí, yóò dé,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

  9. Malaki 3:2nǹkan bí 397 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n ta ni o lè fi ara da ọjọ́ dídé rẹ̀? Ta ni yóò sì dúró nígbà tí ó bá fi ara hàn? Nítorí òun yóò dàbí iná ẹni tí ń da fàdákà àti bi ọṣẹ alágbàfọ̀.

  10. Malaki 3:3nǹkan bí 397 ṣáájú Kristi

    Òun yóò sì jókòó bí ẹni tí n yọ́, tí ó sì ń da fàdákà; yóò wẹ àwọn ọmọ Lefi mọ́, yóò sì tún wọn dàbí wúrà àti fàdákà, kí wọn bá a lè mú ọrẹ òdodo wá fún Olúwa,

  11. Malaki 3:4nǹkan bí 397 ṣáájú Kristi

    nígbà náà ni ọrẹ Juda àti ti Jerusalẹmu yóò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ti ọjọ́ àtijọ́, àti gẹ́gẹ́ bí ọdún ìgbàanì.

  12. Malaki 3:5nǹkan bí 397 ṣáájú Kristi

    “Èmi ó sì súnmọ́ yin fún ìdájọ́. Èmi yóò sì yára ṣe ẹlẹ́rìí sí àwọn oṣó, sí àwọn panṣágà, sí àwọn abúra èké, àti àwọn tí ó fi ọ̀yà alágbàṣe pọn wọn lójú, àti àwọn tí ó ni àwọn opó àti àwọn aláìní baba lára, àti sí ẹni tí kò jẹ́ kí àjèjì rí ìdájọ́ òdodo gbà, tí wọn kò sì bẹ̀rù mi,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

  13. Malaki 3:6nǹkan bí 397 ṣáájú Kristi

    “Èmi Olúwa kò yípadà. Nítorí náà ni a kò ṣe run ẹ̀yin ọmọ Jakọbu.

  14. Malaki 3:7nǹkan bí 397 ṣáájú Kristi

    Láti ọjọ́ àwọn baba ńlá yín wá ni ẹ̀yin tilẹ̀ ti kọ ẹ̀yìn sí ìlànà mi, tí ẹ kò sì pa wọ́n mọ́. Ẹ padà wá sí ọ̀dọ̀ mi, Èmi yóò sì padà sí ọ̀dọ̀ yín,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèrè pé, ‘Báwo ni àwa yóò ṣe padà?’

  15. Malaki 3:8nǹkan bí 397 ṣáájú Kristi

    “Ènìyàn yóò ha ja Ọlọ́run ni olè bí? Síbẹ̀ ẹ̀yin ti jà mí ní olè. “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèrè pé, ‘Báwo ni àwa ṣe jà ọ́ ní olè?’ “Nípa ìdámẹ́wàá àti ọrẹ.

  16. Malaki 3:9nǹkan bí 397 ṣáájú Kristi

    Ríré ni a ó fi yín ré: gbogbo orílẹ̀-èdè yìí, nítorí ẹ̀yin ti jà mi lólè.

  17. Malaki 3:10nǹkan bí 397 ṣáájú Kristi

    Ẹ mú gbogbo ìdámẹ́wàá wá sí ilé ìṣúra, kí oúnjẹ bá à lè wà ní ilé mi, ẹ fi èyí dán mi wò,” ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “kí ẹ sì wò bí èmi kò bá ní sí àwọn fèrèsé ọ̀run fún yin, kí èmi sì tú ìbùkún àkúnwọ́sílẹ̀ jáde fún yín, tó bẹ́ẹ̀ tí kì yóò sì ààyè láti gbà á.

  18. Malaki 3:11nǹkan bí 397 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò sì bá kòkòrò ajẹnirun wí nítorí yín, òun kò sì ni run èso ilẹ̀ yín, bẹ́ẹ̀ ni àjàrà inú oko yín kò ní rẹ̀ dànù,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

  19. Malaki 3:12nǹkan bí 397 ṣáájú Kristi

    “Nígbà náà ni gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì pè yín ni alábùkún fún, nítorí tiyín yóò jẹ́ ilẹ̀ tí ó wu ni,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

  20. Malaki 3:13nǹkan bí 397 ṣáájú Kristi

    “Ẹ̀yin ti sọ ọ̀rọ̀ líle sí mi,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Síbẹ̀ ẹ̀yin béèrè pé, ‘Ọ̀rọ̀ kín ni àwa sọ sí ọ?’

  21. Malaki 3:14nǹkan bí 397 ṣáájú Kristi

    “Ẹ̀yin ti wí pé, ‘Asán ni láti sin Ọlọ́run. Kí ni àwa jẹ ní èrè, nígbà tí àwa ti pa ìlànà rẹ mọ́, tí àwa sì ń rìn kiri bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ní iwájú Olúwa àwọn ọmọ-ogun?

  22. Malaki 3:15nǹkan bí 397 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí àwa pé agbéraga ni alábùkún fún. Ní òtítọ́ ni àwọn ti ń ṣe búburú ń gbèrú sí i, kódà àwọn ti ó dán Ọlọ́run wò ni a dá sí.’ ”

  23. Malaki 3:16nǹkan bí 397 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa ń ba ara wọn sọ̀rọ̀, Olúwa sì tẹ́tí sí i, ó sì gbọ́. A sì kọ ìwé ìrántí kan níwájú rẹ̀, fún àwọn tí o bẹ̀rù Olúwa, tiwọn sì bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ̀.

  24. Malaki 3:17nǹkan bí 397 ṣáájú Kristi

    “Wọn yóò sì jẹ́ tèmi,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “ni ọjọ́ náà, tí èmi ó dá; èmi yóò sì da wọ́n sí gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí máa ń dá ọmọ rẹ̀ tí yóò sìn ín sí.

  25. Malaki 3:18nǹkan bí 397 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò rí ìyàtọ̀, ìyàtọ̀ láàrín olódodo àti ẹni búburú, láàrín ẹni tí ń sìn Ọlọ́run, àti ẹni tí kò sìn ín.