- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Joẹli 2:3nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Iná ń jó níwájú wọ́n; ọwọ́ iná sì ń jó lẹ́yìn wọn. Ilẹ̀ náà dàbí ọgbà Edeni níwájú wọn, àti lẹ́yìn wọn bí ahoro ijù; nítòótọ́, kò sì sí ohun tí yóò bọ́ lọ́wọ́ wọn.
- Joẹli 2:4nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Ìrí wọn dàbí ìrí àwọn ẹṣin; wọ́n ń sáré lọ bí àwọn ẹlẹ́ṣin ogun.
- Joẹli 2:5nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Bí ariwo kẹ̀kẹ́ ogun ni wọn ń fo ní orí òkè bí ariwo ọ̀wọ́-iná tí ń jó koríko gbígbẹ, bí akọni ènìyàn tí a kójọ fún ogun.
- Joẹli 2:6nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Ní ojú wọn, àwọn ènìyàn yóò jẹ ìrora púpọ̀: gbogbo ojú ní yóò ṣú dudu.
- Joẹli 2:7nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Wọn yóò sáré bi àwọn alágbára; wọn yóò gùn odi bí ọkùnrin ológun; olúkúlùkù wọn yóò sì rìn lọ ní ọ̀nà rẹ̀, wọn kì yóò sì yà kúrò ni ọ̀nà wọn.
- Joẹli 2:8nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì yóò kọlu ẹnìkejì rẹ̀; olúkúlùkù wọn yóò rìn ní ọ̀nà rẹ̀, nígbà tí wọn bá sì ṣubú lù idà wọn kì yóò gbọgbẹ́.
- Joẹli 2:9nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Wọn yóò sáré síwá sẹ́yìn ní ìlú; wọn yóò súré lórí odi, wọn yóò gùn orí ilé; wọn yóò gbà ojú fèrèsé wọ̀ inú ilé bí olè.
- Joẹli 2:10nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Ayé yóò mì níwájú wọn; àwọn ọ̀run yóò wárìrì; oòrùn àti òṣùpá yóò ṣókùnkùn, àwọn ìràwọ̀ yóò sì fà ìmọ́lẹ̀ wọn sẹ́yìn.
- Joẹli 2:11nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Olúwa yóò sì bú ramúramù jáde níwájú ogun rẹ̀: nítorí ibùdó rẹ̀ tóbi gidigidi; nítorí alágbára ní òun, tí n mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ; nítorí ọjọ́ Olúwa tóbi ó sì ní ẹ̀rù gidigidi; ara ta ni ó lè gbà á?
- Joẹli 2:12nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
“Ǹjẹ́ nítorí náà nísinsin yìí,” ni Olúwa wí, “Ẹ fi gbogbo ọkàn yín yípadà sí mi, àti pẹ̀lú àwẹ̀, àti pẹ̀lú ẹkún, àti pẹ̀lú ọ̀fọ̀.”
- Joẹli 2:13nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Ẹ sì fa ọkàn yín ya, kì í sì í ṣe aṣọ yín, ẹ sì yípadà sí Olúwa Ọlọ́run yín, nítorí tí o pọ̀ ní oore-ọ̀fẹ́, ó sì kún fun àánú, ó lọ́ra láti bínú, ó sì ṣeun púpọ̀, ó sì ronúpìwàdà láti ṣe búburú.
- Joẹli 2:14nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Ta ni ó mọ̀ bí òun yóò yípadà, kí o sì ronúpìwàdà, kí ó sì fi ìbùkún sílẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀— àní ọrẹ-jíjẹ àti ọrẹ mímu fún Olúwa Ọlọ́run yín?
- Joẹli 2:15nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Ẹ fún ìpè ní Sioni, ẹ ya àwẹ̀ kan sí mímọ́, ẹ pe àjọ tí ó ni ìrònú.
- Joẹli 2:16nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Ẹ kó àwọn ènìyàn jọ, ẹ ya ìjọ sí mímọ́; ẹ pe àwọn àgbàgbà jọ, ẹ kó àwọn ọmọdé jọ, àti àwọn tí ń mú ọmú, jẹ kí ọkọ ìyàwó kúrò nínú ìyẹ̀wù rẹ̀. Kí ìyàwó sì kúrò nínú iyàrá rẹ̀.
- Joẹli 2:17nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Jẹ́ kí àwọn àlùfáà, àwọn ìránṣẹ́ Olúwa, sọkún láàrín ìloro àti pẹpẹ. Sí jẹ́ kí wọn wí pé, “Dá àwọn ènìyàn rẹ sí, Olúwa. Má sì ṣe fi ìní rẹ fun ẹ̀gàn, tí yóò sì di òwe ní àárín àwọn kèfèrí. Èéṣe tí wọn yóò fi wí láàrín àwọn ènìyàn pé, ‘Ọlọ́run wọn ha da?’ ”
- Joẹli 2:18nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ní Olúwa yóò jowú fún ilẹ̀ rẹ̀, yóò sì káàánú fún ènìyàn rẹ̀.
- Joẹli 2:19nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Nítòótọ́, Olúwa yóò dá wọn lóhùn, yóò sì wí fun àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: “Wò ó èmi yóò rán ọkà, àti ọtí wáìnì tuntun, àti òróró sí i yín, a ó sì fi wọn tẹ́ yín lọ́rùn; Èmi kì yóò sì fi yín ṣe ẹ̀gàn mọ́ láàrín àwọn aláìkọlà.
- Joẹli 2:20nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
“Ṣùgbọ́n èmi yóò lé ogun àríwá jìnnà réré kúrò lọ́dọ̀ yín, èmi yóò sì lé e lọ sí ilẹ̀ tí ó ṣá, tí ó sì di ahoro, pẹ̀lú ojú rẹ̀ sí Òkun ìlà-oòrùn, àti ẹ̀yìn rẹ̀ sí ìwọ̀-oòrùn Òkun. Òórùn rẹ̀ yóò sì gòkè, òórùn búburú rẹ̀ yóò sì gòkè.” Nítòótọ́ ó ti ṣe ohun ńlá.
- Joẹli 2:21nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Má bẹ̀rù, ìwọ ilẹ̀; jẹ́ kí inú rẹ̀ dùn kí o sì yọ̀, nítorí Olúwa ti ṣe ohun ńlá.
- Joẹli 2:22nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Ẹ má bẹ̀rù, ẹranko igbó, nítorí pápá oko aginjù ń rú. Nítorí igi ń so èso rẹ̀, igi ọ̀pọ̀tọ́ àti àjàrà ń so èso ọ̀rọ̀ wọn.
- Joẹli 2:23nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Ẹ jẹ́ kí inú yín dùn, ẹ̀yin ọmọ Sioni, ẹ sì yọ̀ nínú Olúwa Ọlọ́run yín, nítorí ó ti fi àkọ́rọ̀ òjò fún yín bí ó ti tọ́, Òun ti mú kí òjò rọ̀ sílẹ̀ fún un yín, àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò ní oṣù kìn-ín-ní.
- Joẹli 2:24nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Àwọn ilẹ̀ ìpakà yóò kún fún ọkà; àti ọpọ́n wọn nì yóò sàn jáde pẹ̀lú ọtí wáìnì tuntun àti òróró.
- Joẹli 2:25nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
“Èmi yóò sì mú ọdún wọ̀nyí ti eṣú jẹ run padà fún un yín. Èyí tí eṣú agénijẹ àti eṣú jewéjewé ọwọ́ eṣú agénijẹ àti kòkòrò ajẹnirun mìíràn ti fi jẹ àwọn ogun ńlá mi tí mo rán sí àárín yín.
- Joẹli 2:26nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Ẹ̀yin yóò ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti jẹ, títí ẹ̀yin yóò fi yó ẹ ó sì yín orúkọ Olúwa Ọlọ́run yín, ẹni tí ó fi ìyanu bá yín lò; ojú kì yóò sì ti àwọn ènìyàn mi láéláé.
- Joẹli 2:27nǹkan bí 800 ṣáájú Kristi
Ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, èmi wà láàrín Israẹli, àti pé; Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, àti pé kò sí ẹlòmíràn, ojú kì yóò sì ti àwọn ènìyàn mí láéláé.