Fò sí àkóónú

circa 1446 BC

Moses & The Exodus

God raises up Moses to confront Pharaoh; the ten plagues culminate in Israel's dramatic deliverance from four centuries of bondage.

415 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Eksodu 12:42nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Nítorí pé, Olúwa ṣe àìsùn ni òru ọjọ́ náà láti mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, ní òru yìí ni gbogbo Israẹli ní láti máa ṣe àìsùn láti fi bu ọlá fún Olúwa títí di àwọn ìran tí ń bọ̀.

  2. Eksodu 12:43nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé, “Ìwọ̀n yìí ni àwọn òfin fún àjọ ìrékọjá: “Àjèjì kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀.

  3. Eksodu 12:44nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ẹrú tí ẹ̀yin bá rà lè jẹ́ nínú rẹ̀ lẹ́yìn tí ẹ̀yin bá ti kọ ọ́ ní ilà,

  4. Eksodu 12:45nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    ṣùgbọ́n àtìpó àti alágbàṣe kò ni jẹ nínú rẹ̀.

  5. Eksodu 12:46nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    “Nínú ilé ni ẹ ti gbọdọ̀ jẹ ẹ́; ẹ kò gbọdọ̀ mú èyíkéyìí nínú ẹran náà jáde kúrò nínú ilé. Ẹ má ṣe ṣẹ́ ọ̀kankan nínú egungun rẹ̀.

  6. Eksodu 12:47nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Gbogbo àjọ Israẹli ni ó gbọdọ̀ ṣe àjọyọ̀ ọ rẹ̀.

  7. Eksodu 12:48nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    “Àjèjì ti ó bá ń gbé ní àárín yín ti ó bá fẹ́ kópa nínú àjọ ìrékọjá Olúwa, ni o gbọdọ̀ kọ gbogbo àwọn ọmọkùnrin ilé rẹ̀ ní ilà; ní ìgbà náà ni ó lè kó ipa gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí a bí ní ilẹ̀ náà. Gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí a kò bá kọ ní ilà, wọ́n kò ni jẹ nínú rẹ̀.

  8. Eksodu 12:49nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Òfin yìí kan náà ni ó mú àwọn ọmọ tí a bí ni ilẹ̀ náà àti àwọn àlejò tí ń gbé ní àárín yín.”

  9. Eksodu 12:50nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose àti Aaroni.

  10. Eksodu 12:51nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Àti pé ní ọjọ́ náà gan an ni Olúwa mú àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti gẹ́gẹ́ bí ìpín ìpín wọn.

  11. Eksodu 13:1nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Olúwa sọ fún Mose pé,

  12. Eksodu 13:2nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    “Ẹ ya àwọn àkọ́bí yín ọkùnrin sọ́tọ̀ fún mi. Èyí ti ó bá jẹ́ àkọ́bí láàrín àwọn ọmọ Israẹli jẹ́ tèmi, ìbá à ṣe ènìyàn tàbí ẹranko.”

  13. Eksodu 13:3nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Mose sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ rántí ọjọ́ òní, ọjọ́ ti ẹ jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti, kúrò ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin ti ń ṣe ẹrú, nítorí Olúwa mú un yín jáde kúrò ni inú rẹ̀ pẹ̀lú ọwọ́ agbára. Ẹ má ṣe jẹ ohunkóhun tí ó ni ìwúkàrà nínú.

  14. Eksodu 13:4nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Òní, ní oṣù Abibu (oṣù kẹta ọdún tiwa) lónìí ẹ̀yin ń jáde kúrò ní Ejibiti.

  15. Eksodu 13:5nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ní ìgbà tí Olúwa mú un yín jáde wá sí ilẹ̀ Kenaani, Hiti, Amori, Hifi àti ilẹ̀ àwọn Jebusi; ilẹ̀ tí ó ti ṣe búra láti fi fún àwọn baba ńlá yín, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, ẹ ni láti pa ìsìn yìí mọ́ ní oṣù yìí.

  16. Eksodu 13:6nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Fún ọjọ́ méje ni ìwọ yóò fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà nínú àti pé ní ọjọ́ keje ni àjọ yóò wà fún Olúwa.

  17. Eksodu 13:7nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Kí ẹ̀yin ó jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà fún ọjọ́ méje yìí; kó má ṣe sí ohunkóhun tí a fi ìwúkàrà ṣe ní sàkání yín.

  18. Eksodu 13:8nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò sì sọ fún àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin, ‘Mo ń ṣe èyí nítorí ohun tí Olúwa ṣe fún mi nígbà tí èmi jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti.’

  19. Eksodu 13:9nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ṣíṣe èyí yóò wà fún àmì ní ọwọ́ rẹ, àti bí àmì ìrántí ni iwájú orí rẹ, tí yóò máa rán ọ létí òfin Olúwa ní ẹnu rẹ. Nítorí Olúwa mú ọ jáde láti ilẹ̀ Ejibiti pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá rẹ̀.

  20. Eksodu 13:10nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ìwọ gbọdọ̀ pa òfin náà mọ́ ní àkókò tí a yàn bí ọdún tí ń gorí ọdún.

  21. Eksodu 13:11nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    “Lẹ́yìn tí Olúwa tí mú ọ wá sí ilẹ̀ àwọn ará Kenaani tí ó sì fi fún ọ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ìlérí pẹ̀lú ìbúra fún ọ àti fún àwọn baba ńlá rẹ̀,

  22. Eksodu 13:12nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    ìwọ yóò fi àkọ́bí inú rẹ fún Olúwa. Gbogbo àkọ́bí ti ó jẹ́ akọ ti ẹran ọ̀sìn rẹ ní ó jẹ́ ti Olúwa.

  23. Eksodu 13:13nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ìwọ yóò fi ọ̀dọ́-àgùntàn ra àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ padà, ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá rà á padà, ǹjẹ́ kí ìwọ ṣẹ́ ẹ ní ọrùn, gbogbo àkọ́bí ọkùnrin ni kí ìwọ kí ó rà padà.

  24. Eksodu 13:14nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    “Yóò sí ṣe ní àwọn ọjọ́ tí ń bọ̀, ní ìgbà tí àwọn ọmọ yín yóò béèrè lọ́wọ́ yín, ‘Kí ni èyí túmọ̀ sí?’ Kí ìwọ kí ó sọ fún wọn pé, ‘Pẹ̀lú ọwọ́ agbára ní Olúwa fi mú wa jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti, kúrò ní oko ẹrú.

  25. Eksodu 13:15nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ní ìgbà ti Farao ṣe orí kunkun, ti ó kọ̀ láti jẹ́ kí a lọ, Olúwa pa gbogbo àwọn àkọ́bí ilẹ̀ Ejibiti, àti ènìyàn àti ẹranko. Ìdí èyí ni àwa fi ń fi gbogbo àkọ́bí tí í ṣe akọ rú ẹbọ sí Olúwa láti fi ṣe ìràpadà fún àwọn àkọ́bí wa ọkùnrin.’