Skip to content

Pharaoh

5 ẹsẹ · 1 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Pharaoh

  1. Nítorí náà, wọ́n yan àwọn ọ̀gá akóniṣiṣẹ́ lé wọn lórí láti máa ni wọ́n lára pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára. Wọ́n sì kọ́ Pitomi àti Ramesesi gẹ́gẹ́ bí ìlú ìṣúra pamọ́ sí fún Farao.

  2. Àwọn agbẹ̀bí náà sì dá Farao lóhùn pé, “Àwọn obìnrin Heberu kò rí bí àwọn obìnrin Ejibiti, wọ́n ní agbára, wọ́n sì ti máa ń bí ọmọ kí àwọn agbẹ̀bí tó dé ọ̀dọ̀ wọn.”

  3. Nígbà náà ni Farao pàṣẹ yìí fún gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ pé, “Gbogbo ọmọkùnrin tí a bí ni kí ẹ gbé jù sínú odò Naili, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ọmọbìnrin ni kí ẹ jẹ́ kí wọn ó wà láààyè.”

  4. Nígbà náà ni ọmọbìnrin Farao sọ̀kalẹ̀ wá sí etí odò Naili láti wẹ̀, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sì ń rìn ni etí bèbè odò. Ó sì ri apẹ̀rẹ̀ náà ni àárín eèsún, ó sì rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin kan láti lọ gbé e wá,

  5. Nígbà ti Farao sì gbọ́ nípa èyí, ó wá ọ̀nà láti pa Mose, ṣùgbọ́n Mose sá kúrò ní àrọ́wọ́tó o Farao, ó lọ sí Midiani láti máa gbé, nígbà tí ó dé bẹ̀, ó jókòó ni ẹ̀bá a kànga kan.