Fò sí àkóónú

Daughter of Pharaoh

7 ẹsẹ · 1 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Daughter of Pharaoh

  1. Nígbà náà ni ọmọbìnrin Farao sọ̀kalẹ̀ wá sí etí odò Naili láti wẹ̀, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sì ń rìn ni etí bèbè odò. Ó sì ri apẹ̀rẹ̀ náà ni àárín eèsún, ó sì rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin kan láti lọ gbé e wá,

  2. Nígbà náà ni arábìnrin rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ ọmọbìnrin Farao pé, “Ṣé kí èmi lọ wá ọ̀kan lára àwọn obìnrin Heberu wá fún ọ láti bá ọ tọ́jú ọmọ náà?”

  3. Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni; lọ.” Arábìnrin náà sì lọ, ó sì pe ìyá ọmọ náà wá.

  4. Ọmọbìnrin Farao sì wí fún un pé, “Gba ọmọ yìí kí o sì tọ́jú rẹ̀ fún mi, èmi yóò san owó iṣẹ́ ẹ̀ rẹ fún ọ.” Ọmọbìnrin náà sì gbé ọmọ náà lọ, ó sì tọ́jú rẹ̀.

  5. Nígbà tí ọmọ náà sì dàgbà, ó mú un tọ ọmọbìnrin Farao wá, ó sì di ọmọ rẹ̀. Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Mose, ó wí pé, “Nítorí tí mo fà á jáde nínú omi.”

  6. Nígbà tí wọn sí gbe é sọnù, ọmọbìnrin Farao gbé e, ó sì tọ ọ́ dàgbà gẹ́gẹ́ bí ọmọ ara rẹ̀.

  7. Nípa ìgbàgbọ́ ni Mose, nígbà tí o dàgbà, ó kọ̀ ki a máa pé òun ni ọmọ ọmọbìnrin Farao;