Fò sí àkóónú

circa 1446 BC

Moses & The Exodus

God raises up Moses to confront Pharaoh; the ten plagues culminate in Israel's dramatic deliverance from four centuries of bondage.

415 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Eksodu 14:19nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni angẹli Ọlọ́run tó ti ń ṣáájú ogun Israẹli lọ, padà o sì rìn ni ẹ̀yìn wọn; Òpó ìkùùkuu tí ń rìn ni iwájú wọn sì padà sí í rìn ni ẹ̀yìn wọn.

  2. Eksodu 14:20nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ó sì wà láàrín àwọn ọmọ-ogun Ejibiti àti Israẹli. Ìkùùkuu sì ṣú òkùnkùn sí àwọn ará Ejibiti ni òru náà. Ṣùgbọ́n ó tan ìmọ́lẹ̀ sí àwọn Israẹli ni òru náà, ọ̀kan kò sì súnmọ́ èkejì ni gbogbo òru náà.

  3. Eksodu 14:21nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Mose na ọwọ́ rẹ̀ sí orí Òkun, ni gbogbo òru náà ni Olúwa fi lé òkun sẹ́yìn pẹ̀lú ìjì líle láti ìlà-oòrùn wá, ó sì sọ ọ́ di ìyàngbẹ ilẹ̀. Omi òkun sì pínyà,

  4. Eksodu 14:22nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    àwọn ọmọ Israẹli sì la ìyàngbẹ ilẹ̀ kọjá nínú òkun pẹ̀lú ògiri omi ní ọ̀tún àti òsì.

  5. Eksodu 14:23nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Àwọn ará Ejibiti sì ń lépa wọn, gbogbo ẹṣin Farao, kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀ wọ́ tọ̀ wọ́n lọ sínú òkun.

  6. Eksodu 14:24nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ní ìṣọ́ òwúrọ̀ Olúwa bojú wo ogun àwọn ará Ejibiti láàrín ọ̀wọ̀n iná àti ìkùùkuu, ó sì kó ìpayà bá àwọn ọmọ-ogun Ejibiti.

  7. Eksodu 14:25nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ó sì yọ àgbá ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ogun wọn kí ó bá à le ṣòro fún wọn láti fi kẹ̀kẹ́ ogun náà rìn. Àwọn ará Ejibiti wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sá àsálà kúrò ní iwájú àwọn ará Israẹli nítorí Olúwa ń bá wa jà nítorí wọn.”

  8. Eksodu 14:26nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Olúwa sì wí fún Mose pé, “Na ọwọ́ rẹ sí orí òkun kí omi òkun lè ya padà sórí àwọn ará Ejibiti, kẹ̀kẹ́ ogun wọn àti sórí ẹlẹ́ṣin wọn.”

  9. Eksodu 14:27nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Mose sì na ọwọ́ rẹ̀ sí orí òkun, òkun sì padà bọ́ sí ipò rẹ̀ nígbà ti ilẹ̀ mọ́. Àwọn ará Ejibiti ń sá fún omi òkun, Olúwa sì gbá wọn sínú òkun.

  10. Eksodu 14:28nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Omi òkun sì ya padà, ó sì bo kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin: àní, gbogbo ọmọ-ogun Farao tiwọn wọ inú òkun tọ àwọn ọmọ Israẹli lọ kò sí ọ̀kan nínú wọn tí ó yè.

  11. Eksodu 14:29nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n àwọn ará Israẹli la òkun kọjá lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ pẹ̀lú ògiri omi ni ọ̀tún àti òsì wọn.

  12. Eksodu 14:30nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ni ọjọ́ yìí ni Olúwa gba Israẹli là kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Ejibiti; Israẹli sì rí òkú àwọn ará Ejibiti ni etí òkun.

  13. Eksodu 14:31nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Nígbà ti àwọn ọmọ Israẹli rí iṣẹ́ ìyanu ńlá ti Olúwa ṣe fún wọn lára àwọn ará Ejibiti, àwọn ènìyàn bẹ̀rù Olúwa, wọ́n sì gba Olúwa àti Mose ìránṣẹ́ rẹ gbọ́.

  14. Eksodu 15:1nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Mose àti àwọn ọmọ Israẹli kọ orin yìí sí Olúwa, Èmi yóò kọrin sí Olúwa, nítorí òun pọ̀ ní ògo. Ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún ni ó ti sọ sínú Òkun.

  15. Eksodu 15:2nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Olúwa ni agbára àti orin mi; òun ti di Olùgbàlà mi, òun ni Ọlọ́run mi, èmi ó yìn ín, Ọlọ́run baba mi, èmi ó gbé e ga.

  16. Eksodu 15:3nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ológun ni Olúwa, Olúwa ni orúkọ rẹ,

  17. Eksodu 15:4nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    kẹ̀kẹ́ ogun Farao àti ogun rẹ̀ ni ó mú wọ inú Òkun. Àwọn ọmọ-ogun Farao tó jáfáfá jùlọ ni ó rì sínú Òkun Pupa.

  18. Eksodu 15:5nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ibú omi bò wọ́n mọ́lẹ̀; wọ́n sì rì sí ìsàlẹ̀ omi òkun bí òkúta.

  19. Eksodu 15:6nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    “Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, Olúwa, pọ̀ ní agbára. Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, Olúwa, fọ́ àwọn ọ̀tá túútúú.

  20. Eksodu 15:7nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    “Nínú agbára ńlá rẹ ti ó tóbi ìwọ bi àwọn ti ó dìde sí ọ ṣubú. Ìwọ rán ìbínú gbígbóná rẹ; tí ó run wọ́n bí àgémọ́lẹ̀ ìdí koríko.

  21. Eksodu 15:8nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Pẹ̀lú èémí imú rẹ ni omi fi ń wọ́jọ pọ̀. Ìṣàn omi dìde dúró bí odi; ibú omi sì dìpọ̀ láàrín Òkun.

  22. Eksodu 15:9nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ọ̀tá ń gbéraga, ó ń wí pé, ‘Èmi ó lépa wọn, èmi ó bá wọn. èmi ó pín ìkógun; èmi ó tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ mi lọ́run lára wọn. Èmi yóò fa idà mi yọ, ọwọ́ mi yóò pa wọ́n run.’

  23. Eksodu 15:10nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ìwọ fẹ́ èémí rẹ, òkun ru bò wọ́n mọ́lẹ̀. Wọ́n rì bí òjé ni àárín omi ńlá.

  24. Eksodu 15:11nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ta ni nínú àwọn òrìṣà tó dàbí rẹ, Olúwa? Ta ló dàbí rẹ: ní títóbi, ní mímọ́ Ẹlẹ́rù ni yìn, tí ń ṣe ohun ìyanu?

  25. Eksodu 15:12nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    “Ìwọ na apá ọ̀tún rẹ, ilẹ̀ si gbé wọn mì.