Fò sí àkóónú

circa 1446 BC

Moses & The Exodus

God raises up Moses to confront Pharaoh; the ten plagues culminate in Israel's dramatic deliverance from four centuries of bondage.

415 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Eksodu 15:13nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Nínú ìfẹ́ rẹ ti kì í sákí Ìwọ ṣe amọ̀nà àwọn ènìyàn náà tí Ìwọ ti rà padà. Nínú agbára rẹ Ìwọ yóò tọ́ wọn, lọ sí ibi ìjókòó rẹ mímọ́.

  2. Eksodu 15:14nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Orílẹ̀-èdè yóò gbọ́ wọn yóò wárìrì. Ìkáàánú yóò mi àwọn ènìyàn Filistia.

  3. Eksodu 15:15nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ìbẹ̀rù yóò mú àwọn ìjòyè Edomu, àwọn olórí Moabu yóò wárìrì. Àwọn ènìyàn Kenaani yóò sì yọ́ dànù.

  4. Eksodu 15:16nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ìbẹ̀rù bojo yóò ṣubú lù wọ́n, nítorí nína títóbi apá rẹ̀ wọn yóò dúró jẹ́ẹ́ láì mira bí i òkúta, títí àwọn ènìyàn rẹ yóò fi rékọjá, Olúwa, títí tí àwọn ènìyàn tí o ti rà yóò fi rékọjá.

  5. Eksodu 15:17nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ìwọ yóò mú wọn wá láti gbìn wọ́n ni orí òkè ti ìwọ jogún, ní ibi ti ìwọ ṣe fún ara rẹ, Olúwa. Láti máa gbé ibi mímọ́ ti ìwọ fi ọwọ́ rẹ gbé kalẹ̀, Olúwa.

  6. Eksodu 15:18nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    “Olúwa yóò jẹ ọba láé àti láéláé.”

  7. Eksodu 15:19nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Nígbà ti ẹṣin Farao, kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀ wọ inú Òkun, Olúwa mú kí omi òkun padà bò wọ́n mọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Israẹli rìn lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ la òkun kọjá.

  8. Eksodu 15:20nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Miriamu wòlíì obìnrin, arábìnrin Aaroni, mú ohun èlò orin ni ọwọ́ rẹ̀, gbogbo àwọn obìnrin sì jáde tẹ̀lé e pẹ̀lú ìlù òun ijó.

  9. Eksodu 15:21nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Miriamu kọrin sí wọn báyìí pé, “Ẹ kọrin sí Olúwa, nítorí òun ni ológo jùlọ. Ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún, ni òun bi ṣubú sínú Òkun.”

  10. Eksodu 15:22nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Mose ṣe amọ̀nà àwọn ènìyàn Israẹli jáde láti Òkun Pupa lọ sínú ijù Ṣuri. Wọ́n lọ ní ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sínú ijù náà, wọn kò sì rí omi.

  11. Eksodu 15:23nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí wọ́n dé Mara, wọn kò lè mu omi Mara nítorí omi náà korò. (Nítorí náà ni a ṣe pe ibẹ̀ ni Mara: ibi ìkorò.)

  12. Eksodu 15:24nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Àwọn ènìyàn ń kùn sí Mose wí pé, “Kí ni àwa yóò mu?”

  13. Eksodu 15:25nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Mose sì ké pe Olúwa, Olúwa sì fi igi kan hàn án, ó sì sọ igi náà sínú omi, omi náà sì dùn. Níbẹ̀ ni Olúwa ti gbé ìlànà àti òfin kalẹ̀ fún wọn, níbẹ̀ ni ó sì ti dán wọn wò.

  14. Eksodu 15:26nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ó wí pé, “Bí ìwọ bá fetísílẹ̀ dáradára sí òfin Olúwa Ọlọ́run, ti ìwọ sì ṣe ohun tí ó tọ́ ni ojú rẹ̀, ti ìwọ sì tẹ̀lé ohun tí ó pàṣẹ, ti ìwọ si pa ìlànà rẹ̀ mọ́. Èmi kì yóò jẹ́ kí èyíkéyìí nínú àwọn ààrùn wọ̀n-ọn-nì ti mo mú wá sórí àwọn ará Ejibiti wá sí ara rẹ, nítorí Èmi ni Olúwa ti ó mú ọ láradá.”

  15. Eksodu 15:27nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Nígbà ti wọ́n dé Elimu, níbi ti kànga omi méjìlá àti àádọ́rin ọ̀pẹ gbé wà, wọ́n pàgọ́ síbẹ̀ ni etí omi.