Fò sí àkóónú

circa 800–400 BC

The Hebrew Prophets

God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.

3,706 ẹsẹ · 14 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Hosea 5:12nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi

    Mo dàbí kòkòrò aṣọ sí Efraimu, Mo sì dàbí ìdin ara Juda.

  2. Hosea 5:13nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi

    “Nígbà ti Efraimu ri àìsàn rẹ̀, tí Juda sì rí ojú egbò rẹ̀ ni Efraimu bá tọ ará Asiria lọ, ó sì ránṣẹ́ sí ọba ńlá náà fún ìrànlọ́wọ́. Ṣùgbọ́n kò le è wò ó sàn bẹ́ẹ̀ ni kò le wo ojú egbò rẹ̀ jinná.

  3. Hosea 5:14nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi

    Nítorí pé, èmi ó dàbí kìnnìún sí Efraimu, bí i kìnnìún ńlá sí ilé Juda. Èmi ó fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ èmi ó sì lọ; Èmi ó gbé wọn lọ, láìsí ẹni tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀.

  4. Hosea 5:15nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni èmi ó padà lọ sí ààyè mi títí di ìgbà tí wọn ó fi gbà pé àwọn jẹ̀bi wọn yóò sì wá ojú mi nínú ìpọ́njú wọn, wọn ó fi ìtara wá mi.”

  5. Hosea 6:1nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi

    “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a padà sọ́dọ̀ Olúwa ó ti fà wá ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ ṣùgbọ́n yóò mú wa láradá Ó ti pa wá lára ṣùgbọ́n yóò dí ojú ọgbẹ́ wa.

  6. Hosea 6:2nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn ọjọ́ méjì, yóò sọ wá jí ní ọjọ́ kẹta yóò mú wa padà bọ̀ sípò kí a ba à le wá gbé níwájú rẹ̀.

  7. Hosea 6:3nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi

    Ẹ jẹ́ kí a mọ Olúwa; ẹ jẹ́ kí a tẹ̀síwájú láti mọ̀ ọ́n. Gẹ́gẹ́ bí oòrùn ṣe ń yọ, yóò jáde; yóò tọ̀ wá wá bí òjò, bí òjò àkọ́rọ̀ ti ń bomirin ilẹ̀.”

  8. Hosea 6:4nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi

    “Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Efraimu? Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Juda? Ìfẹ́ rẹ dàbí ìkùùkuu òwúrọ̀ bí ìrì ìdájí tí ó kọjá lọ kíákíá.

  9. Hosea 6:5nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà ni mo ṣe gé e yín sí wẹ́wẹ́ láti ọwọ́ àwọn wòlíì, Mo pa yín pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹnu mi, ìdájọ́ mi tàn bí i mọ̀nàmọ́ná lórí yín.

  10. Hosea 6:6nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi

    Nítorí àánú ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ; àti ìmọ̀ Ọlọ́run ju ọrẹ ẹbọ sísun lọ.

  11. Hosea 6:7nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi

    Bí i Adamu, wọ́n da májẹ̀mú wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí mi níbẹ̀.

  12. Hosea 6:8nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi

    Gileadi jẹ́ ìlú àwọn ènìyàn búburú tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, a sí ti fi ẹ̀ṣẹ̀ bà á jẹ́.

  13. Hosea 6:9nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi

    Bí adigunjalè ṣe ń ba ní bùba de àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà, ń parapọ̀; tí wọ́n sì ń pànìyàn lójú ọ̀nà tó lọ sí Ṣekemu, tí wọ́n sì ń dá ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ni lójú.

  14. Hosea 6:10nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi

    Mo ti rí ohun tó ba ni lẹ́rù ní ilé Israẹli. Níbẹ̀ Efraimu, fi ara rẹ̀ fún àgbèrè Israẹli sì di aláìmọ́.

  15. Hosea 6:11nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi

    “Àti fún ìwọ, Juda, a ti yan ọjọ́ ìkórè rẹ. “Nígbà tí mo bá fẹ́ dá ohun ìní àwọn ènìyàn mi padà,

  16. Hosea 7:1nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi

    nígbà tí èmi ìbá mú Israẹli láradá. Ẹ̀ṣẹ̀ Efraimu ń farahàn ìwà búburú Samaria sì ń hàn síta. Wọ́n ń ṣe ẹ̀tàn, àwọn olè ń fọ́ ilé; àwọn ọlọ́ṣà ń jalè ní òpópónà;

  17. Hosea 7:2nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi

    ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ pé mo rántí gbogbo ìwà búburú wọn. Ẹ̀ṣẹ̀ wọn gbé wọn mì pátápátá; wọ́n wà níwájú mi nígbà gbogbo.

  18. Hosea 7:3nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi

    “Wọ́n ń mú inú ọba dùn pẹ̀lú ìwà búburú wọn, àti inú ọmọ-aládé dùn pẹ̀lú irọ́ wọn.

  19. Hosea 7:4nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi

    Alágbèrè ni gbogbo wọn wọ́n gbóná bí ààrò àkàrà tí a dáwọ́ kíkoná dúró, lẹ́yìn ìgbà tí o ti pò ìyẹ̀fun tán, títí ìgbà tí yóò wú.

  20. Hosea 7:5nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi

    Ní ọjọ́ àjọ̀dún ọba wa wáìnì mú ara ọmọ-aládé gbóná ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn oníyẹ̀yẹ́.

  21. Hosea 7:6nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi

    Ọkàn wọn ń gbóná bí i ààrò wọ́n sì tọ̀ ọ́ lọ pẹ̀lú rìkíṣí, ìbínú wọn pa lọ́lọ́ ní gbogbo òru ó sì bú jáde bí ọ̀wọ́-iná ní òwúrọ̀.

  22. Hosea 7:7nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi

    Gbogbo wọn gbóná bí ààrò wọ́n pa gbogbo olórí wọn run, gbogbo ọba wọn si ṣubú kò sì ṣí ẹnìkan nínú wọn tí ó ké pè mí.

  23. Hosea 7:8nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi

    “Efraimu ti darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn náà; Efraimu jẹ́ àkàrà tí a kò yípadà.

  24. Hosea 7:9nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi

    Àwọn àlejò ti jẹ agbára rẹ̀ run ṣùgbọ́n kò sì mọ̀. Ewú ti wà ní orí rẹ̀ káàkiri bẹ́ẹ̀ ni kò kíyèsi i.

  25. Hosea 7:10nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi

    Ìgbéraga Israẹli ń jẹ́rìí sí i ṣùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo èyí kò padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run, tàbí kí ó wá a.