- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Hosea 4:6nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi
àwọn ènìyàn mi ń ṣègbé nítorí pé wọn kò ní ìmọ̀. “Nítorí pé ẹ ti kọ ìmọ̀ sílẹ̀. Èmi náà kọ̀ yín ní àlùfáà mi; nítorí pé ẹ ti kọ òfin Ọlọ́run yín sílẹ̀, Èmi náà yóò gbàgbé àwọn ọmọ yín.
- Hosea 4:7nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi
Bí àwọn àlùfáà ṣe ń pọ̀ sí i bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń dẹ́ṣẹ̀ sí mi. Wọ́n yí ògo mi padà sí ohun ìtìjú
- Hosea 4:8nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi
wọ́n ń jẹun nípa ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn mi, wọ́n sì ń gbádùn nínú ìwà búburú wọn.
- Hosea 4:9nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi
Yóò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ṣe rí náà ni àwọn àlùfáà rí. Èmi ó jẹ gbogbo wọn ní yà nítorí ọ̀nà wọn. Èmi ó sì san án fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn.
- Hosea 4:10nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi
“Wọn ó máa jẹun ṣùgbọ́n wọn kò ní yó; wọn ó ṣe àgbèrè ṣùgbọ́n, wọn kò ni pọ̀ sí i, nítorí pé wọ́n ti kọ Olúwa sílẹ̀, wọ́n sì ti fi ara wọn
- Hosea 4:11nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi
fún àgbèrè; wọ́n fi ara wọn fún wáìnì àtijọ́, àti tuntun èyí tó gba òye àwọn ènìyàn mi sọnù.
- Hosea 4:12nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi
Wọ́n ń gba ìmọ̀ràn lọ́wọ́ ère igi ọ̀pá igi sì ń dá wọn lóhùn. Ẹ̀mí àgbèrè ti mú wọn ṣìnà wọ́n sì jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run wọn.
- Hosea 4:13nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi
Wọ́n ń rú ẹbọ lórí àwọn òkè ńlá, wọ́n sì ń sun ọrẹ tùràrí lórí àwọn òkè kékeré, lábẹ́ igi óákù, àti igi Poplari àti igi ẹlimuati onírúurú igi tí ìbòjú rẹ̀ dára. Nítorí náà àwọn ọmọbìnrin yín yóò ṣe àgbèrè àti àwọn àfẹ́sọ́nà yín yóò ṣe àgbèrè.
- Hosea 4:14nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi
“Èmi kò ní jẹ àwọn ọmọbìnrin yín ní yà nígbà tí wọ́n bá ṣe àgbèrè tàbí àwọn àfẹ́sọ́nà ọmọ yín, nígbà tí wọ́n bá ṣe àgbèrè nítorí pé àwọn ọkùnrin pàápàá ń bá alágbèrè kẹ́gbẹ́. Wọ́n sì ń rú ẹbọ pẹ̀lú àwọn alágbèrè ojúbọ òrìṣà. Nítorí náà, ènìyàn tí kò bá ní òye yóò parun!
- Hosea 4:15nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi
“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o ṣe àgbèrè ìwọ Israẹli, ìdájọ́ yìí wà fún un yín. Ẹ má ṣe jẹ́ kí Juda di ẹlẹ́bi. “Ẹ má ṣe lọ sí Gilgali. Ẹ má sì ṣe gòkè lọ sí Beti-Afeni ẹ má sì búra pé, ‘Bí Olúwa ti wà láààyè nítòótọ́!’
- Hosea 4:16nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi
Àwọn ọmọ Israẹli ṣe agídí bí alágídí ọmọ màlúù. Báwo wá ni Olúwa ṣe fẹ́ bọ́ wọn bí àgùntàn ní pápá oko tútù?
- Hosea 4:17nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi
Efraimu ti darapọ̀ mọ́ òrìṣà, ẹ fi sílẹ̀!
- Hosea 4:18nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi
Bí ohun mímu wọn bá tilẹ̀ tán, wọ́n tún tẹ̀síwájú nínú àgbèrè. Àwọn olórí wọn fẹ́ràn ohun ìtìjú ju ohun ìyìn lọ.
- Hosea 4:19nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi
Ìjì ni yóò gbá wọn lọ. Gbogbo ìrúbọ wọn yóò sì kó ìtìjú bá wọn.
- Hosea 5:1nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi
“Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yìn àlùfáà! Ẹ fetísílẹ̀ ẹ̀yin ọmọ Israẹli! Ẹ gbọ́, ẹ̀yìn ilé ọba! Ìdájọ́ yìí kàn yín. Ẹ ti jẹ́ ẹ̀bìtì ní Mispa àwọ̀n ti a nà sílẹ̀ lórí Tabori.
- Hosea 5:2nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi
Àwọn ọlọ̀tẹ̀ ti gbilẹ̀ nínú ìpànìyàn gbogbo wọn ni èmi ó bá wí,
- Hosea 5:3nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi
mo mọ ohun gbogbo nípa Efraimu Israẹli kò sì pamọ́ fún mi Efraimu, ní báyìí ó ti ṣe àgbèrè Israẹli sì ti díbàjẹ́.
- Hosea 5:4nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi
“Ìṣe wọn kò gbà wọ́n láààyè láti padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọn. Ẹ̀mí àgbèrè wà ni ọkàn wọn, wọn kò sì mọ Olúwa.
- Hosea 5:5nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi
Ìgbéraga Israẹli ń jẹ́rìí lé wọn; àwọn ọmọ Israẹli, àti Efraimu pàápàá kọsẹ̀ nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Juda náà sì kọsẹ̀ pẹ̀lú wọn.
- Hosea 5:6nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi
Nígbà tí wọ́n bá lọ pẹ̀lú agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran wọn láti wá Olúwa, wọn kò ní rí i, ó ti yọ ara rẹ̀ kúrò láàrín wọn.
- Hosea 5:7nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi
Wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Olúwa wọ́n sì bí àwọn àjèjì ọmọ. Nísinsin yìí, ọdún oṣù tuntun wọn, ni yóò pa wọn run pẹ̀lú ìpín wọn.
- Hosea 5:8nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi
“Fọn fèrè ní Gibeah, kí ẹ sì fun ìpè ní Rama. Ẹ pariwo ogun ní Beti-Afeni; máa wárìrì, ìwọ Benjamini.
- Hosea 5:9nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi
Efraimu yóò di ahoro ní ọjọ́ ìbáwí láàrín àwọn ẹ̀yà Israẹli, Mo sọ ohun tí ó dájú.
- Hosea 5:10nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi
Àwọn olórí Juda dàbí àwọn tí í máa yí òkúta ààlà kúrò. Èmi ó tú ìbínú gbígbóná mi lé wọn lórí bí ìkún omi.
- Hosea 5:11nǹkan bí 780 ṣáájú Kristi
A ni Efraimu lára, a sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ ní ìdájọ́, nítorí pé, ó pinnu láti tẹ̀lé òrìṣà.