Fò sí àkóónú

circa 800–400 BC

The Hebrew Prophets

God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.

3,706 ẹsẹ · 14 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Hosea 9:6nǹkan bí 760 ṣáájú Kristi

    Bí wọ́n tilẹ̀ yọ́ kúrò lọ́wọ́ ìparun Ejibiti yóò kó wọn jọ, Memfisi yóò sì sin wọ́n. Ibi ìsọjọ̀ fàdákà wọn ni ẹ̀gún yóò jogún, Ẹ̀gún yóò bo àpótí ìṣúra fàdákà wọn. Ẹ̀gún yóò sì bo gbogbo àgọ́ wọn.

  2. Hosea 9:7nǹkan bí 760 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọjọ́ ìjìyà ń bọ̀; àwọn ọjọ́ ìṣirò iṣẹ́ ti dé. Jẹ́ kí Israẹli mọ èyí. Nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ yín pọ̀ ìkórìíra yín sì pọ̀ gan an ni. A ka àwọn wòlíì sí òmùgọ̀, a ka ẹni ìmísí sí asínwín.

  3. Hosea 9:8nǹkan bí 760 ṣáájú Kristi

    Wòlíì, papọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, ni olùṣọ́ ọ Efraimu. Síbẹ̀ ìdẹ̀kùn dúró dè é ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀ àti ìkórìíra ní ilé Ọlọ́run rẹ̀.

  4. Hosea 9:9nǹkan bí 760 ṣáájú Kristi

    Wọ́n ti gbilẹ̀ nínú ìwà ìbàjẹ́ gẹ́gẹ́ bí i ọjọ́ Gibeah Ọlọ́run yóò rántí ìwà búburú wọn yóò sì jẹ wọ́n ní yà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

  5. Hosea 9:10nǹkan bí 760 ṣáájú Kristi

    “Mo rí Israẹli bí èso àjàrà ní aginjù. Mo rí àwọn baba yín, bí àkọ́pọ́n nínú igi ọ̀pọ̀tọ́ ní àkọ́so rẹ̀. Ṣùgbọ́n wọ́n tọ Baali-Peori lọ, wọ́n yà wọn sọ́tọ̀ fún òrìṣà tó ń mú ìtìjú bá ni, ohun ìríra wọn sì rí gẹ́gẹ́ bí wọn ti fẹ́.

  6. Hosea 9:11nǹkan bí 760 ṣáájú Kristi

    Ògo Efraimu yóò fò lọ bí ẹyẹ kò ní sí ìfẹ́rakù, ìlóyún àti ìbímọ.

  7. Hosea 9:12nǹkan bí 760 ṣáájú Kristi

    Bí wọ́n tilẹ̀ tọ́ ọmọ dàgbà. Èmi yóò mú wọn ṣọ̀fọ̀ lórí gbogbo wọn. Ègbé ni fún wọn, nígbà tí mo yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn!

  8. Hosea 9:13nǹkan bí 760 ṣáájú Kristi

    Mo rí Efraimu bí ìlú Tire tí a tẹ̀dó sí ibi dáradára ṣùgbọ́n Efraimu yóò kó àwọn ọmọ rẹ̀ jáde fún àwọn apànìyàn.”

  9. Hosea 9:14nǹkan bí 760 ṣáájú Kristi

    Fún wọn, Olúwa! Kí ni ìwọ yóò fún wọn? Fún wọn ní inú tí ń ba oyún jẹ́ àti ọyàn gbígbẹ.

  10. Hosea 9:15nǹkan bí 760 ṣáájú Kristi

    “Nítorí gbogbo ìwà búburú tí wọ́n hù ní Gilgali, Mo kórìíra wọn níbẹ̀, nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Èmi yóò lé wọn jáde ní ilé mi, Èmi kò ní ní ìfẹ́ wọn mọ́ ọlọ̀tẹ̀ ni gbogbo olórí wọn.

  11. Hosea 9:16nǹkan bí 760 ṣáájú Kristi

    Efraimu ti rẹ̀ dànù gbogbo rẹ̀ sì ti rọ, kò sì so èso. Bí wọ́n tilẹ̀ bímọ. Èmi ó pa àwọn ọmọ wọn tí wọ́n fẹ́ràn jùlọ.”

  12. Hosea 9:17nǹkan bí 760 ṣáájú Kristi

    Ọlọ́run mi yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀ nítorí pé wọn kò gbọ́rọ̀ sí i; wọn yóò sì di alárìnkiri láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.

  13. Hosea 10:1nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi

    Israẹli jẹ́ igi àjàrà tó gbilẹ̀ ó ń so èso fún ara rẹ̀. Bí èso rẹ̀ ṣe ń pọ̀ bẹ́ẹ̀ ni ó ń kọ́ pẹpẹ sí i bí ilẹ̀ rẹ̀ ṣe ń ṣe rere o bu ọlá fún òkúta ìyàsọ́tọ̀ ère rẹ̀.

  14. Hosea 10:2nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi

    Ọkàn wọn kún fún ìtànjẹ báyìí wọ́n gbọdọ̀ ru ẹ̀bi wọn. Olúwa yóò wó pẹpẹ wọn palẹ̀ yóò sì pa gbogbo òkúta ìyàsọ́tọ̀ wọn run.

  15. Hosea 10:3nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni wọn yóò wí pé, “A kò ní ọba nítorí tí a kò bọ̀wọ̀ fún Olúwa ṣùgbọ́n bí a tilẹ̀ ní ọba, kí ni yóò ṣe fún wa?”

  16. Hosea 10:4nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi

    Wọ́n ṣe ìlérí púpọ̀, wọ́n ṣe ìbúra èké, wọ́n da májẹ̀mú; báyìí ni ìdájọ́ hù sókè bí igi ìwọ̀ ni aporo oko, bi i koríko májèlé láàrín oko tí a ro.

  17. Hosea 10:5nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi

    Àwọn ènìyàn tí ń gbé Samaria bẹ̀rù nítorí ère abo màlúù tó wà ní Beti-Afeni. Àwọn ènìyàn rẹ̀ yóò ṣọ̀fọ̀ le e lórí bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà rẹ̀. Gbogbo àwọn tó láyọ̀ sì dídán rẹ̀, nítorí tí a ti mú lọ sí ìgbèkùn.

  18. Hosea 10:6nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi

    A ó gbé lọ sí Asiria gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún ọba ńlá a ó dójútì Efraimu; ojú yóò ti Israẹli nítorí ìgbìmọ̀ rẹ̀.

  19. Hosea 10:7nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi

    Bí igi tó léfòó lórí omi ni Samaria àti àwọn ọba rẹ yóò sàn lọ.

  20. Hosea 10:8nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi

    Àwọn ibi gíga tí ẹ tí ń hùwà búburú ni a o parun, èyí ni ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli. Ẹ̀gún ọ̀gàn àti ẹ̀gún òṣùṣú yóò hù jáde, yóò sì bo àwọn pẹpẹ wọn. Wọn yóò sọ fún àwọn òkè gíga pé, “Bò wá mọ́lẹ̀!” àti fún àwọn òkè kéékèèké pé, “Ṣubú lù wá!”

  21. Hosea 10:9nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi

    “Láti ìgbà Gibeah, ni ó ti ṣẹ̀, ìwọ Israẹli, ìwọ sì tún wà níbẹ̀. Ǹjẹ́ ogun kò lé ẹ̀yin aṣebi ni Gibeah bá bí?

  22. Hosea 10:10nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi

    Nígbà tó bá tẹ́ mi lọ́rùn, èmi yóò fi ìyà jẹ wọ́n; Orílẹ̀-èdè yóò kó ra wọn jọ, wọ́n ó sì dojúkọ wọn, láti fi wọn sínú ìdè nítorí ìlọ́po ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

  23. Hosea 10:11nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi

    Efraimu jẹ́ ọmọ abo màlúù tí a tí kọ́, to si fẹ́ràn láti máa pa ọkà; lórí ọrun rẹ̀ tó lẹ́wà ni èmi ó dí ẹrù wúwo lé. Èmi yóò mú kí a gun Efraimu bí ẹṣin Juda yóò tú ilẹ̀, Jakọbu yóò sì fọ́ ògúlùtu rẹ̀.

  24. Hosea 10:12nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi

    Ẹ gbin òdòdó fún ara yín, kí ẹ sì ká èso ìfẹ́ àìlópin. Ẹ tu ilẹ̀ yín tí a kò ro, nítorí pé ó ti tó àsìkò láti wá Olúwa, títí tí yóò fi dé, tí yóò sì rọ òjò òdodo lé yín lórí.

  25. Hosea 10:13nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n ẹ tí gbin búburú ẹ si ka ibi, ẹ ti jẹ èso èké nítorí ẹ tí gbẹ́kẹ̀lé agbára yín àti àwọn ọ̀pọ̀ jagunjagun yín,