Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Pride

303 ẹsẹ · 61 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà tí Hamani rí i pé Mordekai kò ní kúnlẹ̀ tàbí bu ọlá fún òun, ó bínú.

  2. Ṣùgbọ́n òmùgọ̀ ènìyàn ki yóò di ọlọ́gbọ́n bi ko ti rọrùn fún ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó láti bí ènìyàn.

  3. “Kò sí àní àní níbẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni àwọn ènìyàn náà, ọgbọ́n yóò sì kú pẹ̀lú yín!

  4. Ṣùgbọ́n èmi ní ìyè nínú gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin; èmi kò kéré sí i yín. Àní, ta ni kò mọ gbogbo nǹkan wọ̀nyí?

  5. Ohun tí ẹ̀yin mọ̀, èmi mọ̀ pẹ̀lú, èmi kò kéré sí i yin.

  6. Háà! ẹ̀yin kì bá kúkú dákẹ́! Èyí ni kì bá sì ṣe ọgbọ́n yín.

  7. Ìgbà náà ní Elifasi, ará Temani, dáhùn wí pé,

  8. “Ọlọ́gbọ́n a máa sọ̀rọ̀ ìmọ̀ asán kí ó sì máa fi afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn kún ara rẹ̀ nínú?

  9. Òun lè máa fi àròyé sọ̀rọ̀ tí kò ní èrè, tàbí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ nínú èyí tí kò lè fi ṣe rere?

  10. Ṣùgbọ́n ìwọ ṣá ìbẹ̀rù tì, ìwọ sì dí iṣẹ́ ìsìn lọ́nà níwájú Ọlọ́run.

  11. Nítorí pé ẹnu ara rẹ̀ ni ó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ìwọ sì yàn ahọ́n alárékérekè ni ààyò.

  12. Ẹnu ara rẹ̀ ni ó dá lẹ́bi, kì í ṣe èmi; àní ètè ara rẹ̀ ni ó jẹ́rìí gbè ọ́.

  13. “Ìwọ ha í ṣe ọkùnrin tí a kọ́ bí? Tàbí a ha dá ọ ṣáájú àwọn òkè?

  14. Ìwọ gbúròó àṣírí Ọlọ́run rí? Tàbí ìwọ ha dá ọgbọ́n dúró sọ́dọ̀ ara rẹ?

  15. Kí ni ìwọ mọ̀ tí àwa kò mọ̀? Òye kí ní ó yé ọ tí kò sí nínú wa?

  16. Àwọn arúgbó àti ògbólógbòó ènìyàn wà pẹ̀lú wa, tí wọ́n dàgbà ju baba rẹ lọ.

  17. Ìtùnú Ọlọ́run ha kéré lọ́dọ̀ rẹ? Ọ̀rọ̀ kan sì ṣe jẹ́jẹ́ jù lọ́dọ̀ rẹ?

  18. Èéṣe ti ọkàn rẹ fi ń ti ọ kiri, kí ni ìwọ tẹjúmọ́ tóbẹ́ẹ̀.

  19. Tí ìwọ fi yí ẹ̀mí rẹ padà lòdì sí Ọlọ́run, tí ó fi ń jẹ́ ki ọ̀rọ̀kọ́rọ̀ kí ó máa bọ́ ní ẹnu rẹ̀ bẹ́ẹ̀?

  20. Nítorí kí ni a ṣe ń kà wá sí bí ẹranko, tí a sì ń kà wá si bí ẹni ẹ̀gàn ní ojú yín?

  21. Ìwọ fa ara rẹ ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ nínú ìbínú rẹ̀; kí a ha kọ ayé sílẹ̀ nítorí rẹ̀ bi? Tàbí kí a sí àpáta kúrò ní ipò rẹ̀?

  22. Ta ni yóò tako ipa ọ̀nà rẹ̀ lójúkojú, ta ni yóò sì san án padà fún un ní èyí tí ó ti ṣe?

  23. Síbẹ̀ a ó sì sin ín ní ọ̀nà ipò òkú, a ó sì máa ṣọ́ ibojì òkú.

  24. Ènìyàn ńlá ńlá kì í ṣe ọlọ́gbọ́n, bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbà ní òye ẹ̀tọ́ kò yé.

  25. “Nítorí náà ní èmí ṣe wí pé, ẹ dẹtí sílẹ̀ sí mi; èmí pẹ̀lú yóò fi ìmọ̀ mi hàn.