Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Pride: Israel
Àwọn ẹsẹ nípa Israel
Ègbé ni fún adé ìgbéraga, fún àwọn ọ̀mùtí Efraimu, àti fún ìtànná rírọ, ẹwà ògo rẹ̀, tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójú àti sí ìlú náà ìgbéraga àwọn tí ọtí wáìnì ń pa tí a rẹ̀ sílẹ̀.
Ìgbéraga Israẹli ń jẹ́rìí lé wọn; àwọn ọmọ Israẹli, àti Efraimu pàápàá kọsẹ̀ nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Juda náà sì kọsẹ̀ pẹ̀lú wọn.
Efraimu yóò di ahoro ní ọjọ́ ìbáwí láàrín àwọn ẹ̀yà Israẹli, Mo sọ ohun tí ó dájú.