Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Pride

303 ẹsẹ · 61 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Èmi fún ọ ni ìmọ̀ràn pé kí o ra wúrà lọ́wọ́ mi tí a ti dà nínú iná, kí ìwọ lè di ọlọ́rọ̀; àti aṣọ funfun, kí ìwọ lè fi wọ ara rẹ̀, àti kí ìtìjú ìhòhò rẹ̀ má ba hàn kí ìwọ sì fi ohun ìkunra kun ojú rẹ̀, kí ìwọ lè ríran.

  2. Níwọ́n bí o ti yin ara rẹ̀ lógo tó, tí ó sì hùwà wọ̀bìà, níwọ̀n bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ dá a lóró kí ẹ sì fún un ní ìbànújẹ́; nítorí tí ó wí ní ọkàn rẹ̀ pé, ‘Mo jókòó bí ọbabìnrin, èmi kì sì í ṣe opó, èmí kì yóò sì rí ìbànújẹ́ láé.’

  3. Nítorí náà, ní ọjọ́ kan ni ìyọnu rẹ̀ yóò dé, ikú, àti ìbìnújẹ́, àti ìyàn; a ó sì fi iná sun ún pátápátá: nítorí pé alágbára ni Olúwa Ọlọ́run tí ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀.