Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Pride

303 ẹsẹ · 61 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ìwọ fi àwọn agbéraga bú, àwọn tí a fi gégùn ún tí ó ṣìnà kúrò nínú àṣẹ rẹ.

  2. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn agbéraga ti gbìmọ̀ èké sí mí, èmi pa ẹ̀kọ́ rẹ mọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi.

  3. Ọkàn wọn yigbì kò sì ní àánú, ṣùgbọ́n èmi ní inú dídùn nínú òfin rẹ.

  4. Kí ojú kí ó ti àwọn agbéraga nítorí wọn pa mí lára láìnídìí ṣùgbọ́n èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú ẹ̀kọ́ rẹ.

  5. Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi. Olúwa àyà mi kò gbéga, bẹ́ẹ̀ ni ojú mi kò gbé sókè: bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi ọwọ́ mi lé ọ̀ràn ńlá, tàbí lé ohun tí ó ga jù mí lọ.

  6. Bí Olúwa tilẹ̀ ga, síbẹ̀ ó júbà àwọn onírẹ̀lẹ̀; ṣùgbọ́n agbéraga ni ó mọ̀ ní òkèrè réré.

  7. Ó fi àwọn ẹlẹ́yà ṣe yẹ̀yẹ́, ṣùgbọ́n ó fi oore-ọ̀fẹ́ fún onírẹ̀lẹ̀.

  8. Àwọn ohun mẹ́fà wà tí Olúwa kórìíra, ohun méje ní ó jẹ́ ìríra sí i,

  9. Ojú ìgbéraga, ahọ́n tó ń parọ́ ọwọ́ tí ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀,

  10. “Èmi, ọgbọ́n ń gbé pẹ̀lú òye; mo ní ìmọ̀ àti ọgbọ́n-inú.

  11. Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìkórìíra ibi mo kórìíra ìgbéraga àti agídí, ìwà ibi àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.

  12. Ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí fi ọ̀nà sí ìyè hàn, ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ ìbáwí mú àwọn mìíràn ṣìnà.

  13. Nígbà tí ìgbéraga bá dé, nígbà náà ni ìdójútì dé, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ ni ọgbọ́n ń wá.

  14. Ẹni tí kò gbọ́n fojú kékeré wo aládùúgbò rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó ní òye pa ẹnu rẹ̀ mọ́.

  15. Ó sàn kí a má jẹ́ ènìyàn pàtàkì kí a sì ní ìránṣẹ́ ju kí a díbọ́n pé a jẹ́ ẹni pàtàkì láìní oúnjẹ.

  16. Ọ̀nà aláìgbọ́n dára lójú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa gba ìmọ̀ràn.

  17. Ìgbéraga máa ń dá ìjà sílẹ̀ ni ṣùgbọ́n ọgbọ́n wà nínú àwọn tí ń gba ìmọ̀ràn.

  18. Ẹni tí ó kẹ́gàn aládùúgbò o rẹ̀ ti dẹ́ṣẹ̀ ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ẹni tí ó ṣàánú àwọn aláìní.

  19. Aláìgbọ́n ọmọ kọ ìbáwí baba rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí jẹ́ ọlọ́gbọ́n.

  20. Ẹni tí ó kúrò lójú ọ̀nà yóò rí ìbáwí gan an, ẹni tí ó kórìíra ìbáwí yóò kú.

  21. Ẹlẹ́gàn kò fẹ́ ẹni tí ń ba wí: kò ní gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ ọlọ́gbọ́n.

  22. Olúwa fa ilé onígbèéraga ya lulẹ̀, ṣùgbọ́n ó pa ààlà opó onírẹ̀lẹ̀ mọ́ láìyẹ̀.

  23. Ẹni tí ó kọ̀ ìbáwí kẹ́gàn ara rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí yóò ní ìmọ̀ sí i.

  24. Olúwa kórìíra gbogbo ẹni tí ń gbéraga lọ́kàn rẹ̀ mọ èyí dájú pé wọn kò ní lọ láìjìyà.

  25. Ìgbéraga ní í ṣáájú ìparun, agídí ọkàn ní í ṣáájú ìṣubú.