Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Pride

303 ẹsẹ · 61 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ó sàn láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ọkàn láàrín àwọn olùpọ́njú jù láti máa pín ìpín pẹ̀lú àwọn agbéraga.

  2. Ẹni tí ó fẹ́ràn ìjà fẹ́ràn ẹ̀ṣẹ̀; ẹni tí ó kọ́ ibodè gígàn ń wá ìparun.

  3. Ọ̀rọ̀ olówó ni ìlú olódi wọn; wọ́n rò ó bí i wí pé odi tí kò ṣe é gùn ni.

  4. Ṣáájú ìṣubú ọkàn ènìyàn a kọ́kọ́ máa gbéraga, ṣùgbọ́n ìrẹ̀lẹ̀ ni ó máa ń ṣáájú ọlá.

  5. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni wọ́n máa ń sọ pe àwọn ní ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn, ṣùgbọ́n kò rọrùn láti rí ènìyàn olóòtítọ́.

  6. Ojú tí ó gbéga àti ọkàn ìgbéraga, ìmọ́lẹ̀ àwọn ènìyàn búburú, ẹ̀ṣẹ̀ ni!

  7. Agbéraga àti alágídí ènìyàn ń gan orúkọ ara rẹ̀ nítorí ó ń hùwà nínú ìwà ìgbéraga rẹ̀, àti nínú ìbínú púpọ̀púpọ̀.

  8. Bí ojú ṣíṣú àti afẹ́fẹ́ láìsí òjò ni ènìyàn tí ń yangàn nípa ẹ̀bùn tí kò fún ni.

  9. Kò dára láti jẹ oyin àjẹjù, bẹ́ẹ̀ ni kò pọ́n ni lé láti máa wá ọlá fún ara ẹni.

  10. Dá aláìgbọ́n lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò dàbí ọlọ́gbọ́n lójú ara rẹ̀.

  11. Ǹjẹ́ o rí ènìyàn tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ojú ara rẹ̀? Ìrètí ń bẹ fún aláìgbọ́n ènìyàn jù ú lọ.

  12. Ọ̀lẹ gbọ́n ní ojú ara rẹ̀, ju ènìyàn méje tí wọ́n le è fún un ní ìdáhùn ọlọ́gbọ́n.

  13. Jẹ́ kí ẹlòmíràn yìn ọ́ dípò ẹnu ara rẹ, àní àlejò, kí ó má sì ṣe ètè ìwọ fúnra rẹ̀.

  14. Ọlọ́rọ̀ ènìyàn le è gbọ́n lójú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n tálákà tí ó ní òye rí ìdí, rẹ̀.

  15. Ọ̀kánjúwà ènìyàn a máa dá ìjà sílẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò gbilẹ̀.

  16. Àwọn ẹlẹ́yà a máa ru ìlú sókè, ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn máa ń mú ìbínú kúrò.

  17. Ìgbéraga ènìyàn a máa sọ ọ́ di ẹni ilẹ̀ ṣùgbọ́n onírẹ̀lẹ̀ ènìyàn a máa gba iyì kún iyì.

  18. Àwọn tí ó mọ́ ní ojú ara wọn síbẹ̀ tí wọn kò sì mọ́ kúrò nínú èérí wọn;

  19. àwọn ẹni tí ojú wọn gbéga nígbà gbogbo, tí ìwolẹ̀ wọn sì kún fún ìgbéraga.

  20. Ojú agbéraga ènìyàn ni a ó rẹ̀ sílẹ̀ a ó sì tẹrí ìgbéraga ènìyàn ba, Olúwa nìkan ṣoṣo ni a ó gbéga ní ọjọ́ náà.

  21. Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ọjọ́ kan ní ìpamọ́ fún gbogbo agbéraga àti ọlọ́kàn gíga nítorí gbogbo àwọn tí a gbéga (ni a ó rẹ̀ sílẹ̀),

  22. nítorí gbogbo igi kedari Lebanoni, tó ga tó rìpó àti gbogbo óákù Baṣani,

  23. nítorí gbogbo òkè gíga ńlá ńlá àti àwọn òkè kéékèèké,

  24. fún ilé ìṣọ́ gíga gíga àti àwọn odi ìdáàbòbò,

  25. fún gbogbo ọkọ̀ àwọn oníṣòwò àwọn ọkọ̀ tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́.