Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Pride

303 ẹsẹ · 61 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Bí ènìyàn ti í tọwọ́ bọ ìtẹ́ ẹyẹ, bẹ́ẹ̀ ni ọwọ́ mi tẹ ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè. Bí ènìyàn ti í kó ẹyin tí a kọ̀sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni mo kó àwọn orílẹ̀-èdè kò sí èyí tí ó fi apá lu apá, tàbí kí ó ya ẹnu láti dún.’ ”

  2. Ǹjẹ́ àáké le gbé ara rẹ̀ sókè kọjá ẹni tí ó ń fì í, tàbí kí ayùn fọ́nnu sí ẹni tí ó ń lò ó? Àfi bí ẹni pé ọ̀pá ó na ẹni tí ó gbé e sókè, tàbí kí kùmọ̀ lu èyí tí kì í ṣe igi.

  3. Nítorí náà, ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, yóò rán ààrùn ìrẹ̀dànù sórí àwọn akíkanjú jagunjagun, lábẹ́ ògo rẹ̀ ni iná kan yóò ti sọ gẹ́gẹ́ bí iná ajónirun.

  4. Èmi yóò jẹ ayé ní ìyà nítorí ibi rẹ̀, àwọn ìkà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Èmi yóò fi òpin sí gààrù àwọn agbéraga èmi ó sì rẹ ìgbéraga àwọn aláìláàánú sílẹ̀.

  5. Báwo ni ìwọ ṣe ṣubú lulẹ̀ láti ọ̀run wá, ìwọ ìràwọ̀ òwúrọ̀, ọmọ òwúrọ̀ náà! A ti sọ ọ́ sílẹ̀ sínú ayé, ìwọ tí o ti tẹ orí àwọn orílẹ̀-èdè ba rí!

  6. Ìwọ sọ nínú ọkàn rẹ pé, “Èmi yóò gòkè lọ sí ọ̀run; èmi yóò gbé ìtẹ́ mi sókè ga ju àwọn ìràwọ̀ Ọlọ́run, Èmi yóò gúnwà ní orí òkè àpéjọ ní ṣóńṣó orí òkè mímọ́.

  7. Èmi yóò gòkè lọ rékọjá àwọn àwọsánmọ̀; èmi yóò ṣe ara mi gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gá-ògo.”

  8. Ṣùgbọ́n a ti rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ wọ inú ibojì lọ lọ sí ìsàlẹ̀ ọ̀gbun.

  9. Àwọn tí ó rí ọ yóò tẹjúmọ́ ọ, wọ́n ronú nípa àtubọ̀tán rẹ: “Ǹjẹ́ èyí ni ẹni tí ó mi ayé tìtì tí ó sì jẹ́ kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì.

  10. Àwa ti gbọ́ nípa ìgbéraga Moabu, ìwọ̀sí ìgbéraga rẹ̀ àti fùlenge fùlenge, gààrù rẹ̀ àti àfojúdi rẹ̀, ṣùgbọ́n ìfọ́nnu rẹ̀ jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.

  11. Nítorí náà ni àwọn ará Moabu hu, wọ́n jùmọ̀ hu lórí Moabu. Sọkún kí o sì banújẹ́ fún àkàrà díndín Kiri-Hareseti.

  12. Kí ni ohun tí ò ń ṣe níhìn-ín yìí àti pé ta ni ó sì fún ọ ní àṣẹ láti gbẹ́ ibojì kan fún ara rẹ níhìn-ín yìí, tí ó gbẹ́ ibojì ní ibi gíga tí ó sì gbẹ́ ibi ìsinmi rẹ nínú àpáta?

  13. Èmi yóò yọ ọ́ kúrò ní ipò rẹ, a ó sì lé ọ kúrò ní ipò rẹ.

  14. Ǹjẹ́ èyí náà ni ìlú àríyá yín, ògbólógbòó ìlú náà, èyí tí ẹsẹ̀ rẹ̀ ti sìn ín lọ láti lọ tẹ̀dó sí ilẹ̀ tí ó jìnnà réré.

  15. Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti ṣètò rẹ̀, láti tẹrí ìgbéraga àti ògo rẹ ba àti láti rẹ gbogbo àwọn ọlọ́lá ilé ayé sílẹ̀.

  16. Ilẹ̀ ayé ti gbẹ ó sì sá, ayé ń ṣòjòjò, àárẹ̀ mú un, àwọn ẹni gíga ilẹ̀ ayé wà nínú ìpọ́njú

  17. Ní ọjọ́ náà ni Olúwa yóò jẹ ẹ́ ní yà gbogbo agbára tí ó wà lókè lọ́run àti àwọn ọba tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé.

  18. Ó sọ àwọn tí ó ń gbé ní òkè di onírẹ̀lẹ̀ ó rẹ ìlú agbéraga náà nílẹ̀; ó sọ ọ́ di ilẹ̀ pẹrẹsẹ ó sì sọ ọ́ sílẹ̀ nínú erùpẹ̀.

  19. Ègbé ni fún adé ìgbéraga, fún àwọn ọ̀mùtí Efraimu, àti fún ìtànná rírọ, ẹwà ògo rẹ̀, tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójú àti sí ìlú náà ìgbéraga àwọn tí ọtí wáìnì ń pa tí a rẹ̀ sílẹ̀.

  20. Adé ìgbéraga àwọn ọ̀mùtí Efraimu, ni a ó fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.

  21. Ìwọ wí pé, ‘Èmi yóò tẹ̀síwájú títí láé— ọbabìnrin ayérayé!’ Ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsi nǹkan wọ̀nyí tàbí kí o ronú nípa ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀.

  22. “Nísinsin yìí, tẹ́tí sílẹ̀, ìwọ oníwọ̀ra ẹ̀dá tí o kẹ̀tẹ̀ǹfẹ̀ nínú ààbò rẹ tí o sì ń sọ fún ara rẹ pé, ‘Èmi ni, kò sì ṣí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi. Èmi kì yóò di opó tàbí kí n pàdánù àwọn ọmọ.’

  23. Méjèèjì yìí ni yóò wá sórí rẹ láìpẹ́ jọjọ, ní ọjọ́ kan náà: pípàdánù ọmọ àti dídi opó. Wọn yóò wá sórí rẹ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ìṣe oṣó rẹ àti àwọn èpè rẹ tí ko lágbára.

  24. Ìwọ ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìwà ìkà rẹ ó sì ti wí pé, ‘Kò sí ẹni tí ó rí mi?’ Ọgbọ́n àti òye rẹ ti ṣì ọ́ lọ́nà nígbà tí o wí fún ara rẹ pé, ‘Èmi ni, kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.’

  25. Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Má ṣe jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n yangàn nítorí agbára ọgbọ́n rẹ̀, tàbí alágbára nítorí agbára rẹ̀, tàbí ọlọ́rọ̀ nítorí ọrọ̀ rẹ̀.