Fò sí àkóónú

circa 1446–1406 BC

The Wilderness Years

Forty years of wandering in the desert test Israel's faith and prepare a new generation to enter the promised land.

2,247 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Numeri 34:14nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Nítorí ará ilẹ̀ ẹ̀yà ti Reubeni, ẹ̀yà Gadi àti ẹ̀yà ààbọ̀ ti Manase ti gba ogún tiwọn.

  2. Numeri 34:15nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Ẹ̀yà méjèèjì àti ààbọ̀ yìí ti gba ogún tiwọn ní ìhà ìhín Jordani létí i Jeriko, ní ìhà ìlà-oòrùn, ní ìdojúkọ Jordani.”

  3. Numeri 34:16nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Olúwa sọ fún Mose pé,

  4. Numeri 34:17nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    “Èyí ni orúkọ àwọn ọkùnrin náà tí yóò pín ilẹ̀, náà fún yín gẹ́gẹ́ bí ogún: Eleasari àlùfáà àti Joṣua ọmọ Nuni.

  5. Numeri 34:18nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Kí o sì yan olórí kan nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan láti pín ilẹ̀ náà.

  6. Numeri 34:19nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    “Èyí ni orúkọ wọn: “Kalebu ọmọ Jefunne, láti ẹ̀yà Juda;

  7. Numeri 34:20nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Ṣemueli ọmọ Ammihudu, láti ẹ̀yà Simeoni;

  8. Numeri 34:21nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Elidadi ọmọ Kisloni, láti ẹ̀yà Benjamini;

  9. Numeri 34:22nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Bukki ọmọ Jogli, láti ẹ̀yà olórí àwọn ọmọ Dani;

  10. Numeri 34:23nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Hannieli ọmọ Efodu, láti ẹ̀yà Manase, olórí àwọn ọmọ Josẹfu,

  11. Numeri 34:24nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Kemueli ọmọ Ṣiftani, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ, Efraimu, ọmọ Josẹfu;

  12. Numeri 34:25nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Elisafani ọmọ Parnaki, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Sebuluni;

  13. Numeri 34:26nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Paltieli ọmọ Assani, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Isakari;

  14. Numeri 34:27nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Ahihudu ọmọ Ṣelomi, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Aṣeri;

  15. Numeri 34:28nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Pedaheli ọmọ Ammihudu, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Naftali.”

  16. Numeri 34:29nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Èyí ni àwọn ẹni tí Olúwa yàn láti pín ogún náà fún àwọn ọmọ Israẹli ní ilẹ̀ Kenaani.

  17. Numeri 35:1nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Lórí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní Jordani tí ó rékọjá láti Jeriko, Olúwa sọ fún Mose pé,

  18. Numeri 35:2nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli láti fún àwọn Lefi ní ilẹ̀ láti gbé lára ogún tí àwọn ọmọ Israẹli yóò jogún. Kí ẹ sì fún wọn ní ilẹ̀ lára pápá oko tútù, káàkiri ìlú.

  19. Numeri 35:3nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà, wọn yóò ní ìlú tí wọn yóò gbé àti ilẹ̀ pápá oko tútù fún ẹran ọ̀sìn, ọ̀wọ́ ẹran pẹ̀lú gbogbo ìní wọn.

  20. Numeri 35:4nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    “Ilẹ̀ pápá oko tútù káàkiri ìlú tí ẹ ó fi fún àwọn ọmọ Lefi, wíwọ̀n rẹ̀ yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ (1,500 ẹsẹ̀ bàtà) láti ògiri ìlú náà.

  21. Numeri 35:5nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn ìlú náà, wọn ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ìgbọ̀nwọ́ lápá ibi ìhà ìlà-oòrùn, ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ẹsẹ̀ bàtà ní ìhà gúúsù, ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ní ìhà ìwọ̀-oòrùn àti ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ní ìhà àríwá, kí ìlú náà sì wà ní àárín. Wọn yóò ní agbègbè yìí gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ pápá oko tútù fún ìlú náà.

  22. Numeri 35:6nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    “Mẹ́fà lára ìlú tí ẹ fún àwọn ọmọ Lefi yóò jẹ́ ìlú ààbò, tí ẹni tí ó bá pa ènìyàn yóò sá sí. Ní àfikún, ẹ fún wọn ní méjìlélógójì ìlú sí i.

  23. Numeri 35:7nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ní gbogbo rẹ̀, kí ẹ fún àwọn ọmọ Lefi ní méjìdínláàádọ́ta ìlú lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn.

  24. Numeri 35:8nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Ìlú tí ẹ fún àwọn ọmọ Lefi láti ara ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli jogún, olúkúlùkù kí ó fi nínú ìlú rẹ̀ fún àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní rẹ̀ tí ó ní. Gba púpọ̀ lọ́wọ́ ẹ̀yà tí ó ní púpọ̀ àti díẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀yà tí ó ní díẹ̀.”

  25. Numeri 35:9nǹkan bí 1451 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé,