- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 6 BC – AD 30
The Life of Jesus
The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Johanu 14:2nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nínú ilé Baba mi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibùgbé ni ó wà, ìbá má ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ìbá tí sọ fún yín. Èmi ń lọ láti pèsè ààyè sílẹ̀ fún yín.
- Johanu 14:3nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Bí mo bá sì lọ láti pèsè ààyè sílẹ̀ fún un yín, èmi ó tún padà wá, èmi ó sì mú yín lọ sọ́dọ̀ èmi tìkára mi; pé níbi tí èmi gbé wà, kí ẹ̀yin lè wà níbẹ̀ pẹ̀lú.
- Johanu 14:4nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ẹ̀yin mọ ibi tí èmi gbé ń lọ, ẹ sì mọ ọ̀nà náà.”
- Johanu 14:5nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Tomasi wí fún un pé, “Olúwa, a kò mọ ibi tí ìwọ ń lọ, a ó ha ti ṣe mọ ọ̀nà náà?”
- Johanu 14:6nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi ni ọ̀nà, òtítọ́ àti ìyè, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè wá sọ́dọ̀ Baba, bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.
- Johanu 14:7nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ìbá ṣe pé ẹ̀yin ti mọ̀ mí, ẹ̀yin ìbá ti mọ Baba mi pẹ̀lú, láti ìsinsin yìí lọ ẹ̀yin mọ̀ ọ́n, ẹ sì ti rí i.”
- Johanu 14:8nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Filipi wí fún un pé, “Olúwa, fi Baba náà hàn wá, yóò sì tó fún wa.”
- Johanu 14:9nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Jesu wí fún un pé, “Bí àkókò tí mo bá yín gbé ti tó yìí, ìwọ, kò sì tí ì mọ̀ mí síbẹ̀ Filipi? Ẹni tí ó bá ti rí mi, ó ti rí Baba. Ìwọ ha ti ṣe wí pé, ‘Fi Baba hàn wá!’
- Johanu 14:10nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ìwọ kò ha gbàgbọ́ pé, èmi wà nínú Baba, àti pé Baba wà nínú mi? Ọ̀rọ̀ tí èmi ń sọ fún yín, èmi kò dá a sọ; ṣùgbọ́n Baba ti ó wà nínú mi, òun ní ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀.
- Johanu 14:11nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ẹ gbà mí gbọ́ pé, èmi wà nínú Baba, Baba sì wà nínú mi, bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ gbà mí gbọ́ nítorí àwọn ẹ̀rí iṣẹ́ náà pàápàá!
- Johanu 14:12nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, iṣẹ́ tí èmi ń ṣe ni òun yóò ṣe pẹ̀lú; iṣẹ́ tí ó tóbi ju wọ̀nyí lọ ni yóò sì ṣe; nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba.
- Johanu 14:13nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá sì béèrè ní orúkọ mi, òun náà ni èmi ó ṣe, kí a lè yin Baba lógo nínú Ọmọ.
- Johanu 14:14nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Bí ẹ̀yin bá béèrè ohunkóhun ní orúkọ mi, èmi ó ṣe é.
- Johanu 14:15nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Bí ẹ̀yin bá fẹ́ràn mi, ẹ ó pa òfin mi mọ́.
- Johanu 14:16nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà náà èmi yóò wá béèrè lọ́wọ́ Baba. Òun yóò sì fún yín ní olùtùnú mìíràn. Olùtùnú náà yóò máa bá yín gbé títí láé.
- Johanu 14:17nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Òun ni Ẹ̀mí òtítọ́. Ayé kò le gbà á. Nítorí ayé kò mọ̀ ọ́n, bẹ́ẹ̀ ni kò rí i rí. Ẹ̀yin mọ̀ ọn nítorí láti ìgbà tí ẹ ti wà pẹ̀lú mí. Òun náà ti wà pẹ̀lú yín. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kan yóò wọ inú yín láti máa gbé ibẹ̀.
- Johanu 14:18nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Èmi kò ní fi yín sílẹ̀ láìní Olùtùnú, kí ẹ ma dàbí ọmọ tí kò ní òbí. Rárá o! Mo tún ń tọ̀ yín bọ̀.
- Johanu 14:19nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà díẹ̀ sí i, ayé kì yóò rí mi mọ́; ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò rí mi, nítorí tí èmi wà láààyè, ẹ̀yin yóò wà láààyè pẹ̀lú.
- Johanu 14:20nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ní ọjọ́ náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi wà nínú Baba mi, àti ẹ̀yin nínú mi, àti èmi nínú yín.
- Johanu 14:21nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ẹni tí ó bá ní òfin mi, tí ó bá sì ń pa wọ́n mọ́, òun ni ẹni tí ó fẹ́ràn mi, ẹni tí ó bá sì fẹ́ràn mi, a ó fẹ́ràn rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba mi, èmi ó sì fẹ́ràn rẹ̀, èmi ó sì fi ara mi hàn fún un.”
- Johanu 14:22nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Judasi (kì í ṣe Judasi Iskariotu) wí fún un pé, “Olúwa, èéha ti ṣe tí ìwọ ó fi ara rẹ hàn fún àwa, tí kì yóò sì ṣe fún aráyé?”
- Johanu 14:23nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Jesu dáhùn ó sì wí fún un pé, “Bí ẹnìkan bá fẹ́ràn mi, yóò pa ọ̀rọ̀ mi mọ́. Baba mi yóò sì fẹ́ràn rẹ̀, àwa ó sì tọ̀ ọ́ wá, a ó sì ṣe ibùgbé wa pẹ̀lú rẹ̀.
- Johanu 14:24nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ẹni tí kò fẹ́ràn mi ni kò pa ọ̀rọ̀ mi mọ́. Ọ̀rọ̀ tí ẹ̀yin ń gbọ́ kì í ṣe ti èmi, ṣùgbọ́n ti Baba tí ó rán mi.
- Johanu 14:25nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Nǹkan wọ̀nyí ni èmi ti sọ fún yín, nígbà tí mo ń bá yín gbé.
- Johanu 14:26nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n Olùtùnú náà, Ẹ̀mí Mímọ́, ẹni tí Baba yóò rán ní orúkọ mi, òun ni yóò kọ́ yín ní ohun gbogbo, yóò sì rán yín létí ohun gbogbo tí mo ti sọ fún yín.