circa 6 BC – AD 30
The Life of Jesus
The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Johanu 12:40nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Ó ti fọ́ wọn lójú, Ó sì ti sé àyà wọn le; kí wọn má ba à fi ojú wọn rí, kí wọn má ba à fi ọkàn wọn mọ̀, kí wọn má ba à yípadà, kí èmi má ba à mú wọn láradá.”
- Johanu 12:41nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nǹkan wọ̀nyí ni Isaiah wí, nítorí ó ti rí ògo rẹ̀, ó sì sọ̀rọ̀ rẹ̀.
- Johanu 12:42nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Síbẹ̀ ọ̀pọ̀ nínú àwọn olórí gbà á gbọ́ pẹ̀lú; ṣùgbọ́n nítorí àwọn Farisi wọn kò jẹ́wọ́ rẹ̀, kí a má ba à yọ wọ́n kúrò nínú Sinagọgu,
- Johanu 12:43nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
nítorí wọ́n fẹ́ ìyìn ènìyàn ju ìyìn ti Ọlọ́run lọ.
- Johanu 12:44nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Jesu sì kígbe ó sì wí pé, “Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, èmi kọ́ ni ó gbàgbọ́ ṣùgbọ́n ẹni tí ó rán mi.
- Johanu 12:45nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ẹni tí ó bá sì rí mi, ó rí ẹni tí ó rán mi.
- Johanu 12:46nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Èmi ni ìmọ́lẹ̀ tí ó wá sí ayé, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí gbọ́ má ṣe wà nínú òkùnkùn.
- Johanu 12:47nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Bí ẹnikẹ́ni bá sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí kò sì pa wọ́n mọ́, èmi kì yóò ṣe ìdájọ́ rẹ̀ nítorí tí èmi kò wá láti ṣe ìdájọ́ ayé, bí kò ṣe láti gba ayé là.
- Johanu 12:48nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ẹni tí ó bá kọ̀ mí, tí kò sì gba ọ̀rọ̀ mi, ó ní ẹnìkan tí ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀; ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ, òun náà ni yóò ṣe ìdájọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹyìn.
- Johanu 12:49nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí èmi kò dá ọ̀rọ̀ sọ fún ara mi, ṣùgbọ́n Baba tí ó rán mi, ni ó ti fún mi ní àṣẹ, ohun tí èmi ó sọ, àti èyí tí èmi ó wí.
- Johanu 12:50nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Èmi sì mọ̀ pé ìyè àìnípẹ̀kun ni òfin rẹ̀, nítorí náà, àwọn ohun tí mo bá wí, gẹ́gẹ́ bí Baba ti sọ fún mi, bẹ́ẹ̀ ni mo wí!”
- Johanu 13:1nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ǹjẹ́ kí àjọ ìrékọjá tó dé, nígbà tí Jesu mọ̀ pé, wákàtí rẹ̀ dé tan, tí òun ó ti ayé yìí kúrò lọ sọ́dọ̀ Baba, fífẹ́ tí ó fẹ́ àwọn tirẹ̀ tí ó wà ní ayé, ó fẹ́ wọn títí dé òpin.
- Johanu 13:2nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Bí wọ́n sì ti ń jẹ oúnjẹ alẹ́, tí èṣù ti fi í sí ọkàn Judasi Iskariotu ọmọ Simoni láti fi í hàn;
- Johanu 13:3nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
tí Jesu sì ti mọ̀ pé Baba ti fi ohun gbogbo lé òun lọ́wọ́, àti pé lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni òun ti wá, òun sì ń lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run;
- Johanu 13:4nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ó dìde ní ìdí oúnjẹ alẹ́, ó sì fi agbádá rẹ̀ lélẹ̀ ní apá kan; nígbà tí ó sì mú aṣọ ìnura, ó di ara rẹ̀ ní àmùrè.
- Johanu 13:5nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Lẹ́yìn náà, ó bu omi sínú àwokòtò kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í máa wẹ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì ń fi aṣọ ìnura tí ó fi di àmùrè nù wọ́n.
- Johanu 13:6nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà náà ni ó dé ọ̀dọ̀ Simoni Peteru, òun sì wí fún un pé, “Olúwa, ìwọ yóò ha wẹ ẹsẹ̀ mi?”
- Johanu 13:7nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Jesu dá a lóhùn, ó sì wí fún un pé, “Ohun tí èmi ń ṣe ni ìwọ kò mọ̀ nísinsin yìí; ṣùgbọ́n yóò yé ọ ní ìkẹyìn.”
- Johanu 13:8nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Peteru wí fún un pé, “Ìwọ kì yóò wẹ̀ ẹsẹ̀ mi láé.” Jesu sì dalóhùn pé, “Bí èmi kò bá wẹ̀ ọ́, ìwọ kò ní ìpín ní ọ̀dọ̀ mi.”
- Johanu 13:9nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Simoni Peteru wí fún ún pé, “Olúwa, kì í ṣe ẹsẹ̀ mi nìkan, ṣùgbọ́n àti ọwọ́ àti orí mi pẹ̀lú.”
- Johanu 13:10nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Jesu wí fún un pé, “Ẹni tí a wẹ̀ kò tún fẹ́ ju kí a ṣan ẹsẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó mọ́ níbi gbogbo: ẹ̀yin sì mọ́, ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo yín.”
- Johanu 13:11nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí tí ó mọ ẹni tí yóò fi òun hàn; nítorí náà ni ó ṣe wí pé, kì í ṣe gbogbo yín ni ó mọ́.
- Johanu 13:12nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà lẹ́yìn tí ó wẹ ẹsẹ̀ wọn tán, tí ó sì ti mú agbádá rẹ̀, tí ó tún jókòó, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin mọ ohun tí mo ṣe sí yín bí?
- Johanu 13:13nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ẹ̀yin ń pè mí ní ‘Olùkọ́’ àti ‘Olúwa,’ ẹ̀yin wí rere; bẹ́ẹ̀ ni mo jẹ́.
- Johanu 13:14nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ǹjẹ́ bí èmi tí í ṣe Olúwa àti olùkọ́ yín bá wẹ ẹsẹ̀ yín, ó tọ́ kí ẹ̀yin pẹ̀lú sì máa wẹ ẹsẹ̀ ara yín.