Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Strife

158 ẹsẹ · 57 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ojú ìgbéraga, ahọ́n tó ń parọ́ ọwọ́ tí ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀,

  2. ọkàn tí ń pète ohun búburú, ẹsẹ̀ tí ó yára láti sáré sínú ìwà ìkà,

  3. ajẹ́rìí èké tí ń tú irọ́ jáde lẹ́nu àti ènìyàn tí ń dá ìjà sílẹ̀ láàrín àwọn ọmọ ìyá kan.

  4. Ìríra a máa dá ìjà sílẹ̀, ṣùgbọ́n ìfẹ́ a máa bo gbogbo àṣìṣe mọ́lẹ̀.

  5. Ìgbéraga máa ń dá ìjà sílẹ̀ ni ṣùgbọ́n ọgbọ́n wà nínú àwọn tí ń gba ìmọ̀ràn.

  6. Ènìyàn onínú ríru dá ìjà sílẹ̀ ṣùgbọ́n onísùúrù paná ìjà.

  7. Aláyídáyidà ènìyàn dá ìjà sílẹ̀ olófòófó a sì máa pín ọ̀rẹ́ kòríkòsùn ní yà.

  8. Òkèlè gbígbẹ tòun tàlàáfíà àti ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ sàn ju ilé tí ó kún fọ́fọ́ fún ẹran àti ìjà.

  9. Bíbẹ̀rẹ̀ ìjà dàbí ẹni tí ó dá ojú fún adágún omi; nítorí náà mẹ́nu kúrò nínú ọ̀rọ̀ kí ó tó di ìjà.

  10. Ẹni tí ó fẹ́ràn ìjà fẹ́ràn ẹ̀ṣẹ̀; ẹni tí ó kọ́ ibodè gígàn ń wá ìparun.

  11. Ètè aláìgbọ́n dá ìjà sílẹ̀ ẹnu rẹ̀ sì ń ṣokùnfà ẹgba.

  12. Arákùnrin tí a ṣẹ̀ sí ṣòro yípadà ju ìlú olódi lọ, ìjà wọ sì dàbí ọ̀pá ìdábùú ààfin.

  13. Aṣiwèrè ọmọ jẹ́ ìparun baba rẹ̀, aya tí ó máa ń jà sì dàbí ọ̀ṣọ̀ọ̀rọ̀ òjò.

  14. Iyì ni ó jẹ́ fún ènìyàn láti sá fún ìjà, ṣùgbọ́n gbogbo aláìgbọ́n a máa tètè wá ìjà.

  15. Má ṣe wí pé, “N ó sẹ̀san àṣìṣe rẹ yìí fún ọ.” Dúró de Olúwa yóò sì gbà ọ́ là.

  16. Ó sàn láti jókòó ní aginjù ju pẹ̀lú oníjà obìnrin àti òṣónú lọ.

  17. Lé ẹlẹ́gàn sí ìta, ìjà yóò sì jáde; nítòótọ́ ìjà àti ẹ̀gàn yóò dẹ́kun.

  18. Ta ni ó ni òsì? Ta ni ó ni ìbànújẹ́? Ta ni ó ni ìjà? Ta ni ó ni asọ̀? Ta ni ó ni ọgbẹ́ láìnídìí?

  19. Àwọn tí ó dúró pẹ́ níbi ọtí wáìnì; àwọn tí ń lọ láti dán ọtí wáìnì àdàlú wò.

  20. Ohun tí o ti fi ojú ara rẹ rí má ṣe kánjú gbé e lọ sílé ẹjọ́ nítorí kí ni ìwọ yóò ṣe ní ìgbẹ̀yìn bí aládùúgbò rẹ bá dójútì ọ́?

  21. Ó sàn láti gbé ní ibi igun kan lórí òrùlé ju láti bá aya oníjà gbé ilé pọ̀.

  22. Bí ènìyàn tí ó di ajá ní etí mú ni ẹni tí ń kọjá lọ tí ó dá sí ọ̀rọ̀ ìjà tí kì í ṣe tirẹ̀.

  23. Láìsí igi, iná yóò kú láìsí ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn, ìjà máa ń parí.

  24. Bí èédú ti rí sí ẹyin iná, igi fún iná, bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn oníjà fún ìjà dídá sílẹ̀.

  25. Àyà tí ó máa ń jà dàbí ọ̀wààrà òjò ní ọjọ́ tí òjò ń rọ̀;