Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Strife: Christ, an example of avoiding

12 ẹsẹ · 57 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Christ, an example of avoiding

  1. Òun kì yóò pariwo tàbí kígbe sókè, tàbí kí ó gbóhùn rẹ̀ sókè ní òpópónà.

  2. Nígbà tí Jesu sì mọ̀, ó yẹra kúrò níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó sì mú gbogbo àwọn aláìsàn láradá.

  3. Ṣùgbọ́n ó kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n kí ó má ṣe fi òun hàn.

  4. Èyí jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ èyí tí wòlíì Isaiah sọ nípa rẹ̀ pé,

  5. “Ẹ wo ìránṣẹ́ mi ẹni tí mo yàn. Àyànfẹ́ mi ni ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi; èmi yóò fi ẹ̀mí mi fún un. Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ àwọn kèfèrí.

  6. Òun kì yóò jà, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò kígbe; ẹnikẹ́ni kì yóò gbọ́ ohùn rẹ ní ìgboro.

  7. Ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ lọ sí iwájú rẹ̀. Nígbà tí wọ́n sì lọ wọ́n wọ ìletò kan tí í ṣe ti ará Samaria láti pèsè sílẹ̀ dè é.

  8. Wọn kò sì gbà á, nítorí pé ó ń lọ sí Jerusalẹmu.

  9. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ Jakọbu àti Johanu sì rí i, wọ́n ní, “Olúwa wa, jẹ́ kí a pe iná láti ọ̀run wá, kí a sì pa wọ́n run, bí Elijah ti ṣe?”

  10. Ṣùgbọ́n Jesu yípadà, ó sì bá wọn wí.

  11. Lẹ́yìn náà Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì lọ sí ìletò mìíràn.

  12. Ẹni, nígbà tí a kẹ́gàn rẹ̀, tí kò sì padà kẹ́gàn; nígbà tí ó jìyà tí kò sì halẹ̀; ṣùgbọ́n ó fi ọ̀ràn rẹ̀ lé ẹni ti ń ṣe ìdájọ́ òdodo lọ́wọ́.