Fò sí àkóónú

circa 1010–970 BC

The Reign of David

David unites the tribes, conquers Jerusalem, and establishes Israel's golden age—even through deep personal failure.

1,230 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. 1 Kronika 15:24nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Ṣebaniah, Jehoṣafati, Netaneli, Amasai, Sekariah, Benaiah àti Elieseri ní àwọn àlùfáà, tí o ń fún ìpè níwájú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run. Obedi-Edomu àti Jehiah ni ó sì gbọdọ̀ jẹ́ olùṣọ́nà fún àpótí ẹ̀rí.

  2. 1 Kronika 15:25nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi àti àwọn àgbàgbà Israẹli àti àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ láti gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú Olúwa láti ilé Obedi-Edomu, pẹ̀lú inú dídùn.

  3. 1 Kronika 15:26nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Nítorí Ọlọ́run tì ràn wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Lefi ẹni tí ó gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú Olúwa, akọ màlúù méje pẹ̀lú àgbò méje láti fi ṣé ìrúbọ.

  4. 1 Kronika 15:27nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Dafidi sì wọ efodu; aṣọ ìgúnwà ọ̀gbọ̀ dáradára, àti gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí ń ru àpótí ẹ̀rí náà, àti àwọn akọrin, àti Kenaniah olórí pẹ̀lú àwọn akọrin. Dafidi sì wọ aṣọ ìgúnwà funfun.

  5. 1 Kronika 15:28nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Israẹli gbé àpótí ẹ̀rí àti májẹ̀mú Olúwa gòkè wá pẹ̀lú ariwo, pẹ̀lú àyíká ìhó ayọ̀ àti láti fọn fèrè ti ìpè, àti kimbali, àti láti ta ohun èlò orin olókùn àti dùùrù olóhùn gooro.

  6. 1 Kronika 15:29nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Bí àpótí ẹ̀rí Olúwa ti ń wọ ìlú ńlá Dafidi, Mikali ọmọbìnrin Saulu ń wò láti ojú fèrèsé nígbà tí ó sì rí ọba Dafidi ń jó, ó sì ń ṣe àjọyọ̀, ó sì kẹ́gàn rẹ̀ ní ọkàn rẹ̀.

  7. 1 Kronika 16:1nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, wá sínú àgọ́ ti Dafidi ti pèsè fún un, wọ́n sì gbé ẹbọ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀ kalẹ̀ níwájú Ọlọ́run.

  8. 1 Kronika 16:2nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn tí Dafidi parí ẹbọ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀, ó bùkún àwọn ènìyàn ní orúkọ Olúwa.

  9. 1 Kronika 16:3nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ó fún olúkúlùkù ọkùnrin àti obìnrin ọmọ Israẹli ní ìṣù àkàrà kan, àkàrà dídùn ti àkókò kan àti àkàrà dídùn ti èso àjàrà kan.

  10. 1 Kronika 16:4nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Ó yan díẹ̀ lára àwọn ará Lefi láti máa jọ́sìn níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa, àti láti ṣe ìrántí àti dúpẹ́ àti láti yin Olúwa, Ọlọ́run Israẹli.

  11. 1 Kronika 16:5nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Asafu ni olóyè, àtẹ̀lé rẹ ni Sekariah, Jehieli, Ṣemiramotu, Asieli, Mattitiah, Eliabu, Benaiah, Obedi-Edomu àti Jeieli, àwọn ni yóò lu ohun èlò orin olókùn àti dùùrù haapu. Asafu ni yóò lu símbálì kíkan.

  12. 1 Kronika 16:6nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Àti Benaiah àti Jahasieli àwọn àlùfáà ni yóò fọn ìpè nígbà gbogbo níwájú àpótí ẹ̀rí májẹ̀mú ti Ọlọ́run.

  13. 1 Kronika 16:7nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Ní ọjọ́ náà Dafidi kọ́kọ́ fi lé Asafu àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ orin Dafidi ti ọpẹ́ sí Olúwa.

  14. 1 Kronika 16:8nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, ẹ pe orúkọ rẹ̀, ẹ fi iṣẹ́ rẹ̀ hàn nínú àwọn ènìyàn fún ohun tí ó ṣe

  15. 1 Kronika 16:9nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Ẹ kọrin sí i, ẹ kọrin ìyìn, sí i, ẹ sọ ti gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀.

  16. 1 Kronika 16:10nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Ìyìn nínú orúkọ rẹ̀ mímọ́; jẹ kí ọkàn àwọn tí ó yin Olúwa kí ó yọ̀.

  17. 1 Kronika 16:11nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Ẹ wá Olúwa àti agbára rẹ̀; e wá ojú rẹ̀ nígbà gbogbo.

  18. 1 Kronika 16:12nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Rántí àwọn ìyanu tí Ó ti ṣe, iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àti ìdájọ́ tí Ó ti sọ.

  19. 1 Kronika 16:13nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    A! ẹ̀yin ìran ọmọ Israẹli ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn ọmọ Jakọbu, ẹ̀yin tí ó ti yàn.

  20. 1 Kronika 16:14nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Òun ni Olúwa Ọlọ́run wa; ìdájọ́ rẹ̀ wà ní gbogbo ayé.

  21. 1 Kronika 16:15nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ láéláé, ọ̀rọ̀ tí ó pàṣẹ, fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìran,

  22. 1 Kronika 16:16nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    májẹ̀mú tí ó dá pẹ̀lú Abrahamu, ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú fún Isaaki.

  23. 1 Kronika 16:17nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Ó ṣe ìdánilójú u rẹ̀ fún Jakọbu, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ sí Israẹli, gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú ayérayé:

  24. 1 Kronika 16:18nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    “Sí ọ, ni èmi yóò fún ní ilẹ̀ Kenaani. Gẹ́gẹ́ bí ààyè tí ìwọ yóò jogún.”

  25. 1 Kronika 16:19nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí wọn kéré ní iye, wọ́n kéré gidigidi, wọ́n sì jẹ́ àlejò níbẹ̀,