Fò sí àkóónú

circa 1010–970 BC

The Reign of David

David unites the tribes, conquers Jerusalem, and establishes Israel's golden age—even through deep personal failure.

1,230 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. 1 Kronika 14:16nǹkan bí 1047 ṣáájú Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi ṣe ohun tí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún wọn, wọ́n sì kọlu àwọn ọmọ-ogun Filistini láti gbogbo ọ̀nà Gibeoni lọ sí Geseri.

  2. 1 Kronika 14:17nǹkan bí 1047 ṣáájú Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni òkìkí Dafidi tàn ká gbogbo ilẹ̀ káàkiri, Olúwa sì mú kí gbogbo orílẹ̀-èdè bẹ̀rù rẹ̀.

  3. 1 Kronika 15:1nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn ìgbà tí Dafidi ti kọ́ ilé fún ara rẹ̀ ní ìlú Dafidi. Ó sì fi ààyè sílẹ̀ fún àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ó sì pàgọ́ fún un.

  4. 1 Kronika 15:2nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà Dafidi wí pé, kò sí ẹnìkan àyàfi àwọn ọmọ Lefi ni ó lè gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, nítorí Olúwa yàn wọ́n láti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa àti láti máa ṣe ìránṣẹ́ níwájú rẹ̀ títí láé.

  5. 1 Kronika 15:3nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Dafidi kó gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ ní Jerusalẹmu láti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa wá sí ibi tí ó ti pèsè sílẹ̀ fún un.

  6. 1 Kronika 15:4nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Aaroni àti àwọn ọmọ Lefi tí Dafidi péjọ papọ̀.

  7. 1 Kronika 15:5nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Ọgọ́fà nínú àwọn ọmọ Kohati; Urieli olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀.

  8. 1 Kronika 15:6nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Igba ó lé ogún nínú àwọn ọmọ Merari; Asaiah olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀.

  9. 1 Kronika 15:7nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Àádóje nínú àwọn ọmọ Gerṣoni; Joẹli olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀.

  10. 1 Kronika 15:8nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Igba nínú àwọn ọmọ Elisafani; Ṣemaiah olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀.

  11. 1 Kronika 15:9nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Ọgọ́rin nínú àwọn ọmọ Hebroni; Elieli olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀.

  12. 1 Kronika 15:10nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Méjìléláàádọ́fà nínú àwọn ọmọ Usieli; Amminadabu olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀.

  13. 1 Kronika 15:11nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Dafidi sì ránṣẹ́ pe Sadoku, Abiatari tí wọ́n jẹ́ àlùfáà, àti Urieli, Asaiah. Joẹli, Ṣemaiah, Elieli àti Amminadabu tí wọ́n jẹ́ Lefi.

  14. 1 Kronika 15:12nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Ó sì fi fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni olórí àwọn ìdílé Lefi; ẹ̀yin àti àwọn Lefi ènìyàn yín, ẹ ya ara yín sí mímọ́ kí ẹ lè gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, lọ sí ibi tí mó ti pèsè sílẹ̀ fún un.

  15. 1 Kronika 15:13nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Nítorí tí ẹ̀yin ọmọ Lefi kò gbe gòkè wá ní ìgbà àkọ́kọ́ ti Olúwa Ọlọ́run fi ìbínú rẹ̀ ko lù wá. Àwa kò sì ṣe ìwádìí lọ́wọ́ rẹ̀ nípa bí a ti ń ṣe é gẹ́gẹ́ bí ọ́nà tí a là sílẹ̀.”

  16. 1 Kronika 15:14nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà àti àwọn Lefi ya ara wọn sí mímọ́ láti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa gòkè wá, Ọlọ́run Israẹli.

  17. 1 Kronika 15:15nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni àwọn Lefi gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run pẹ̀lú ọ̀pá ní èjìká wọn gẹ́gẹ́ bí Mose ti pa á láṣẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa.

  18. 1 Kronika 15:16nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Dafidi sọ fún àwọn olórí àwọn Lefi láti yan àwọn arákùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí akọrin láti kọ orin ayọ̀, pẹ̀lú àwọn ohun èlò orin olókùn, dùùrù, àti símbálì.

  19. 1 Kronika 15:17nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Lefi yan Hemani ọmọ Joẹli; àti nínú àwọn arákùnrin rẹ̀, Asafu ọmọ Berekiah, àti nínú àwọn ọmọ Merari arákùnrin wọn, Etani ọmọ Kuṣaiah;

  20. 1 Kronika 15:18nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    àti pẹ̀lú wọn àwọn arákùnrin wọn tí a yàn bí olùrànlọ́wọ́ wọn: Sekariah, Jaasieli, Ṣemiramotu, Jehieli, Unni, Eliabu, Benaiah, Maaseiah, Mattitiah, Elifelehu, Mikimeiah, àti Obedi-Edomu àti Jeieli, àwọn aṣọ́bodè.

  21. 1 Kronika 15:19nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Àwọn akọrin sì ni Hemani, Asafu, àti Etani ti àwọn ti kimbali idẹ tí ń dún kíkan;

  22. 1 Kronika 15:20nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Sekariah, Asieli, Ṣemiramotu, Jehieli, àti Unni, Eliabu, Maaseiah àti Benaiah àwọn tí ó gbọdọ̀ ta ohun èlò orin olókùn gẹ́gẹ́ bí alamoti,

  23. 1 Kronika 15:21nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    àti Mattitiah, Elifelehu, Mikneiah, Obedi-Edomu, Jeieli àti Asasiah ni ó ní láti ta ohun èlò olóhùn gooro, láti darí gẹ́gẹ́ bí ṣeminiti.

  24. 1 Kronika 15:22nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Kenaniah olórí àwọn ará Lefi ni ó wà ní ìkáwọ́ orin èyí sì ni ojúṣe nítorí ó mòye nípa rẹ̀.

  25. 1 Kronika 15:23nǹkan bí 1042 ṣáájú Kristi

    Berekiah àti Elkana ni kí ó wà gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́nà fún àpótí ẹ̀rí.