- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1010–970 BC
The Reign of David
David unites the tribes, conquers Jerusalem, and establishes Israel's golden age—even through deep personal failure.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
Nígbà náà ni Dafidi pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, láti ọ̀dọ̀ Ṣihori ní Ejibiti lọ sí Lebo ní ọ̀nà à bá wọ Hamati, láti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run padà láti Kiriati-Jearimu.
Dafidi àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pẹ̀lú rẹ̀ lọ sí Baalahi ti Juda (Kiriati-Jearimu) láti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run Olúwa tí a fi orúkọ rẹ̀ pè, tí ó jókòó láàrín kérúbù gòkè wá.
Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run láti ilé Abinadabu lórí kẹ̀kẹ́ tuntun, Ussa àti Ahio ń ṣọ́ ọ.
Dafidi àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n ṣe àjọyọ̀ pẹ̀lú gbogbo agbára wọn níwájú Ọlọ́run, pẹ̀lú orin àti pẹ̀lú dùùrù, ohun èlò orin olókùn, tambori, kimbali pẹ̀lú ìpè.
Nígbà tí wọ́n dé sí ilẹ̀ ìpakà Kidoni, Ussa sì na ọwọ́ rẹ̀ síta láti di àpótí ẹ̀rí Olúwa mú, nítorí màlúù kọsẹ̀.
Ìbínú Olúwa, sì ru sí Ussa, ó sì lù ú bolẹ̀ nítorí o ti fi ọwọ́ rẹ̀ lórí àpótí ẹ̀rí. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì kú síbẹ̀ níwájú Ọlọ́run.
Nígbà náà Dafidi sì bínú nítorí ìbínú Olúwa ké jáde lórí Ussa, àti títí di òní, wọ́n sì ń pe ibẹ̀ ní Peresi-Usa.
Dafidi sì bẹ̀rù Ọlọ́run ní ọjọ́ náà, ó sì béèrè pé, báwo ni èmi náà ó ṣe gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run sí ọ̀dọ̀ mi?
Kò gbé àpótí ẹ̀rí náà wá sí ọ̀dọ̀ ará rẹ̀ ní ìlú ti Dafidi dípò èyí, ó sì gbé e yà sí ilé Obedi-Edomu ará Gitti.
Àpótí ẹ̀rí Olúwa sì wà lọ́dọ̀ àwọn ará ilé Obedi-Edomu ní ilé rẹ̀ fún oṣù mẹ́ta, Olúwa sì bùkún agbo ilé àti gbogbo ohun tí ó ní.
- 1 Kronika 14:1nǹkan bí 1043 ṣáájú Kristi
Nísinsin yìí Hiramu àti ọba Tire rán oníṣẹ́ sí Dafidi, àti pẹ̀lú igi kedari pẹ̀lú àwọn ọ̀mọ̀lé àti gbẹ́nàgbẹ́nà láti kọ́ ààfin fún un.
- 1 Kronika 14:2nǹkan bí 1043 ṣáájú Kristi
Dafidi sì mọ Israẹli àti pé Olúwa ti fi òun ṣe ọba lórí Israẹli àti pé ìjọba rẹ̀ ga jùlọ nítorí ti àwọn ènìyàn rẹ̀.
- 1 Kronika 14:3nǹkan bí 1043 ṣáájú Kristi
Ní Jerusalẹmu Dafidi mú ọ̀pọ̀ ìyàwó ó sì di baba àwọn ọmọ ọkùnrin púpọ̀ àti ọmọbìnrin.
- 1 Kronika 14:4nǹkan bí 1043 ṣáájú Kristi
Èyí ni orúkọ àwọn ọmọ náà tí wọ́n bí fún un níbẹ̀: Ṣammua, Ṣobabu, Natani, Solomoni,
- 1 Kronika 14:5nǹkan bí 1043 ṣáájú Kristi
Ibhari, Eliṣua, Elifeleti,
- 1 Kronika 14:6nǹkan bí 1043 ṣáájú Kristi
Noga, Nefegi, Jafia,
- 1 Kronika 14:7nǹkan bí 1043 ṣáájú Kristi
Eliṣama, Beeliada, àti Elifeleti.
- 1 Kronika 14:8nǹkan bí 1047 ṣáájú Kristi
Nígbà tí àwọn ará Filistini gbọ́ pé a ti fi àmì òróró yàn Dafidi ní ọba lórí gbogbo Israẹli, wọ́n sì lọ sókè pẹ̀lú ipá láti wá a rí, ṣùgbọ́n Dafidi gbọ́ nípa rẹ̀ ó sì jáde lọ láti pàdé wọn.
- 1 Kronika 14:9nǹkan bí 1047 ṣáájú Kristi
Nísinsin yìí àwọn ará Filistini ti wá láti gbógun ti àfonífojì Refaimu;
- 1 Kronika 14:10nǹkan bí 1047 ṣáájú Kristi
Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ Ọlọ́run wí pé, “Kí èmi kí ó gòkè tọ àwọn ará Filistini lọ bí? Ìwọ ó ha fi wọ́n lé mi lọ́wọ́?” Olúwa sì wí fún un pé, “Gòkè lọ èmi ó sì fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́.”
- 1 Kronika 14:11nǹkan bí 1047 ṣáájú Kristi
Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi àti àwọn ènìyàn rẹ̀ gòkè lọ sí Baali-Perasimu, níbẹ̀ ó sì kọlù wọ́n. Ó sí wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí omi tí ya jáde, Ọlọ́run ti ya Dafidi lórí àwọn ọ̀tá mi pẹ̀lú ọwọ́ mi.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń pè ibẹ̀ ní Baali-Perasimu.
- 1 Kronika 14:12nǹkan bí 1047 ṣáájú Kristi
Àwọn ará Filistini sì ti fi àwọn òrìṣà wọn sílẹ̀ níbẹ̀. Dafidi sì pa á láṣẹ láti jó wọn nínú iná.
- 1 Kronika 14:13nǹkan bí 1047 ṣáájú Kristi
Lẹ́ẹ̀kan sí i àwọn ará Filistini gbógun wọ́n sì fọ́nká àfonífojì,
- 1 Kronika 14:14nǹkan bí 1047 ṣáájú Kristi
Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì tún béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Ọlọ́run sì dalóhùn pé, “Má ṣe gòkè tààrà, ṣùgbọ́n ẹ yí wọn ká, kí ẹ sì mú wọn níwájú igi muliberi.
- 1 Kronika 14:15nǹkan bí 1047 ṣáájú Kristi
Tí ó bá sì ṣe, tí ẹ̀yin bá ti gbọ́ ìró ẹsẹ̀ ní orí òkè igi muliberi, ẹ jáde fún ogun, nítorí èyí yóò fihàn pé Ọlọ́run ti jáde níwájú rẹ láti kọlu àwọn ọmọ-ogun Filistini.”