- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa God
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Wo gbogbo ìwà ìgbéraga, ènìyàn kí o sì rẹ ẹ sílẹ̀ kí o sì tẹ ènìyàn búburú mọ́lẹ̀ ní ipò wọn.
Sin gbogbo wọn papọ̀ nínú erùpẹ̀, kí o sì di ojú ìkọ̀kọ̀ wọn ní isà òkú.
Nígbà náà ní èmi ó yìn ọ́ pé, ọwọ́ ọ̀tún ara rẹ lè gbà ọ́ là.
“Ǹjẹ́ nísinsin yìí kíyèsi Behemoti, tí mo dá pẹ̀lú rẹ, òun a máa jẹ koríko bí ọ̀dá màlúù.
Wò o nísinsin yìí, agbára rẹ wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ, àti ipa rẹ nínú ìṣàn ìkún rẹ.
Òun a máa jù ìrù rẹ̀ bí i igi kedari, iṣan itan rẹ̀ dìjọ pọ̀.
Egungun rẹ̀ ní ògùṣọ̀ idẹ, Egungun rẹ̀ dàbí ọ̀pá irin.
Òun ni olórí nínú àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run; síbẹ̀ Ẹlẹ́dàá rẹ̀ fi idà rẹ̀ lé e lọ́wọ́.
Nítòótọ́ òkè ńlá ńlá ní i mu ohun jíjẹ fún un wá, níbi tí gbogbo ẹranko igbó máa ṣiré ní ẹ̀gbẹ́ ibẹ̀.
Ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi lótusì, lábẹ́ eèsún àti ẹrẹ̀.
Igi lótusì síji wọn bò o; igi arọrọ odò yí i káàkiri.
Kíyèsi i, odò ńlá sàn jọjọ, òun kò sálọ; ó wà láìléwu bí ó bá ṣe pé odò Jordani ti ṣàn lọ sí ẹnu rẹ̀.
Ẹnìkan ha lè mú un ní ojú rẹ̀, tàbí dẹkùn fún tàbí a máa fi ọ̀kọ̀ gún imú rẹ̀?
“Ǹjẹ́ ìwọ le è fi ìwọ̀ fa Lefitani jáde? Tàbí ìwọ lè fi okùn so ahọ́n rẹ̀ mọ́lẹ̀?
Ìwọ lè fi okùn bọ̀ ọ́ ní í mú, tàbí fi ìwọ̀ ẹ̀gún gun ní ẹ̀rẹ̀kẹ́?
Òun ha jẹ́ bẹ ẹ̀bẹ̀ fún àánú lọ́dọ̀ rẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ bí òun ha bá ọ sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́?
Òun ha bá ọ dá májẹ̀mú bí? Ìwọ ó ha máa mú ṣe ẹrú láéláé bí?
Ìwọ ha lè ba sáré bí ẹni pé ẹyẹ ni, tàbí ìwọ ó dè é fún àwọn ọmọbìnrin ìránṣẹ́ rẹ̀?
Ẹgbẹ́ àwọn apẹja yóò ha máa tà á bí? Wọn ó ha pín láàrín àwọn oníṣòwò?
Ìwọ ha lè fi ọ̀kọ̀-irin gun awọ rẹ̀, tàbí orí rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀kọ̀ ìpẹja.
Fi ọwọ́ rẹ lé e lára, ìwọ ó rántí ìjà náà, ìwọ kì yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.
Kíyèsi, ìgbìyànjú láti mú un ní asán; ní kìkì ìrí rẹ̀ ara kì yóò ha rọ̀ ọ́ wẹ̀sì?
Kò sí ẹni aláyà lílé tí ó lè ru sókè. Ǹjẹ́ ta ni ó lè dúró níwájú mi.
Ta ni ó kọ́kọ́ ṣe fún mi, tí èmi ìbá fi san án fún un? Ohunkóhun ti ń bẹ lábẹ́ ọ̀run gbogbo, tèmi ni.
“Èmi kì yóò fi ẹ̀yà ara Lefitani, tàbí ipá rẹ, tàbí ìhámọ́ra rẹ tí ó ní ẹwà pamọ́.