Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa God

662 ẹsẹ · 46 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ta ni yóò lè rídìí aṣọ àpáta rẹ̀? Tàbí ta ni ó lè súnmọ́ ọ̀nà méjì eyín rẹ̀?

  2. Ta ni ó lè ṣí ìlẹ̀kùn iwájú rẹ̀? Àyíká ẹ̀yin rẹ ni ìbẹ̀rù ńlá.

  3. Ìpẹ́ lílé ní ìgbéraga rẹ̀; ó pàdé pọ̀ tímọ́tímọ́ bí àmì èdìdì.

  4. Èkínní fi ara mọ́ èkejì tó bẹ́ẹ̀ tí afẹ́fẹ́ kò lè wọ àárín wọn.

  5. Èkínní fi ara mọ́ èkejì rẹ̀; wọ́n lè wọ́n pọ̀ tí a kò lè mọ̀ wọ́n.

  6. Nípa sí sin rẹ̀ ìmọ́lẹ̀ á mọ́, ojú rẹ̀ a sì dàbí ìpéǹpéjú òwúrọ̀.

  7. Láti ẹnu rẹ ni ọ̀wọ́-iná ti jáde wá, ìpẹ́pẹ́ iná a sì ta jáde.

  8. Láti ihò imú rẹ ni èéfín ti jáde wá, bí ẹni pé láti inú ìkòkò tí a fẹ́ iná ìfèéfèé lábẹ́ rẹ̀.

  9. Èémí rẹ̀ tiná bọ ẹ̀yin iná, ọ̀wọ́-iná sì ti ẹnu rẹ̀ jáde.

  10. Ní ọrùn rẹ̀ ní agbára kù sí, àti ìbànújẹ́ àyà sì padà di ayọ̀ níwájú rẹ̀.

  11. Jabajaba ẹran rẹ̀ dìjọ pọ̀, wọ́n múra gírí fún ara wọn, a kò lè sí wọn ní ipò.

  12. Àyà rẹ̀ dúró gbagidi bí òkúta, àní, ó le bi ìyá ọlọ.

  13. Nígbà tí ó bá gbé ara rẹ̀ sókè, àwọn alágbára bẹ̀rù; nítorí ìbẹ̀rù ńlá, wọ́n dààmú.

  14. Ọ̀kọ̀ tàbí idà, tàbí ọfà, ẹni tí ó ṣá a kò lè rán an.

  15. Ó ká irin sí ibi koríko gbígbẹ àti idẹ si bi igi híhù.

  16. Ọfà kò lè mú un sá; òkúta kànnakánná lọ́dọ̀ rẹ̀ dàbí àgékù koríko.

  17. Ó ka ẹṣin sí bí àgékù ìdì koríko; ó rẹ́rìn-ín sí mímì ọ̀kọ̀.

  18. Òkúta mímú ń bẹ nísàlẹ̀ abẹ́ rẹ̀, ó sì tẹ́ ohun mímú ṣóńṣó sórí ẹrẹ̀.

  19. Ó mú ibú omi hó bí ìkòkò; ó sọ̀ agbami òkun dàbí kólòbó ìkunra.

  20. Ó mú ipa ọ̀nà tan lẹ́yìn rẹ̀; ènìyàn a máa ka ibú sí ewú arúgbó.

  21. Lórí ilẹ̀ ayé kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ̀, tí a dá láìní ìbẹ̀rù.

  22. Ó bojú wo ohun gíga gbogbo, ó sì nìkan jásí ọba lórí gbogbo àwọn ọmọ ìgbéraga.”

  23. Nígbà náà ní Jobu dá Olúwa lóhùn, ó sì wí pé,

  24. “Èmi mọ̀ pé, ìwọ lè e ṣe ohun gbogbo, àti pé, kò si ìrò inú tí a lè fa sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ.

  25. Ìwọ béèrè, ta ni ẹni tí ń fi ìgbìmọ̀ pamọ́ láìní ìmọ̀? Nítorí náà ní èmi ṣe ń sọ èyí tí èmi kò mọ̀, ohun tí ó ṣe ìyanu jọjọ níwájú mi, ti èmi kò mòye.