Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa God: Longsuffering of, abused

16 ẹsẹ · 46 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Longsuffering of, abused

  1. “Ṣùgbọ́n bí wọ́n bá ti wà nínú ìsinmi, wọn a sì túnṣe búburú lójú rẹ. Nígbà náà ni ìwọ kọ̀ wọ́n sílẹ̀ ṣọ́wọ́ àwọn ọ̀tá kí wọ́n lè jẹ ọba lórí wọn. Nígbà tí wọ́n bá sì tún kígbe sí ọ, ìwọ a gbọ́ láti ọ̀run wá, àti nínú àánú rẹ ni ìwọ gbà láti ìgbà dé ìgbà.

  2. “Ìwọ kìlọ̀ fún wọn láti padà sínú òfin rẹ, ṣùgbọ́n wọ́n hu ìwà ìgbéraga, wọ́n sì ṣe àìgbọ́ràn si àṣẹ rẹ. Wọ́n ṣẹ̀ sí ìlànà rẹ, nípa èyí tí ènìyàn yóò yè tí wọ́n bá pa wọ́n mọ́. Nínú agídí ọkàn wọ́n kọ ẹ̀yìn sí ọ, wọ́n jẹ́ olórí kunkun wọn kò sì fẹ́ gbọ́.

  3. Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni ìwọ fi ní sùúrù pẹ̀lú wọn. Nípa ẹ̀mí rẹ ni ìwọ kìlọ̀ fún wọn nípasẹ̀ àwọn wòlíì. Síbẹ̀ wọn kò fi etí sílẹ̀, nítorí náà ni ìwọ ṣe fi wọ́n lé àwọn aládùúgbò wọn lọ́wọ́.

  4. Ṣùgbọ́n nínú ọ̀pọ̀ àánú rẹ, ìwọ kò mú òpin bá wọn tàbí kọ̀ wọ́n sílẹ̀, nítorí ìwọ ni Ọlọ́run olóore-ọ̀fẹ́ àti aláàánú.

  5. Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ẹ ti kọ ìpè ní ìgbà tí mo pè kò sì sí ẹni tí ó kọ ibi ara sí mi gbà tí mo na ọwọ́ sí wọn,

  6. níwọ́n bí ẹ ti kọ gbogbo ìmọ̀ràn mi, tí ẹ̀yin kò sì gba ìbáwí mi,

  7. Èmi pẹ̀lú yóò fi ìdààmú yín rẹ́rìn-ín; èmi yóò ṣẹ̀fẹ̀ nígbà tí ìyọnu bá dé bá a yín.

  8. Nígbà tí ìyọnu bá dé bá a yín bí ìjì líle, nígbà tí ìdààmú bá dé bá ọ bí ààjà, nígbà tí wàhálà àti ìbànújẹ́ ọkàn bá bò ọ́ mọ́lẹ̀.

  9. Ṣùgbọ́n bí ọmọ ọ̀dọ̀ náà bá jẹ́ ènìyàn búburú náà bá wí ní ọkàn rẹ̀ pé, ‘Olúwa mi kì yóò tètè dé.’

  10. Tí ó sì bẹ̀rẹ̀ si í fi ìyà jẹ́ àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí ó ń jẹ, tí ó sì ń mu àmupara.

  11. Nígbà náà ni olúwa ọmọ ọ̀dọ̀ yóò wá ní ọjọ́ àti wákàtí tí kò retí.

  12. Yóò sì jẹ ẹ́ ní ìyà gidigidi, yóò sì rán an sí ibùgbé àwọn àgàbàgebè, níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpayínkeke yóò wà.

  13. Ó sì pa òwe yìí fún wọn pé, “Ọkùnrin kan ní igi ọ̀pọ̀tọ́ kan tí a gbìn sí ọgbà àjàrà rẹ̀; ó sì dé, ó ń wá èso lórí rẹ̀, kò sì rí nǹkan.

  14. Ó sì wí fún olùṣọ́gbà rẹ̀ pé, ‘Sá à wò ó, láti ọdún mẹ́ta ni èmi ti ń wá í wo èso lórí igi ọ̀pọ̀tọ́ yìí, èmi kò sì rí nǹkan: ké e lulẹ̀; èéṣe tí ó fi ń gbilẹ̀ lásán pẹ̀lú?’

  15. “Ó sì dáhùn ó wí fún un pé, ‘Olúwa, jọ̀wọ́ rẹ̀ ní ọdún yìí pẹ̀lú, títí èmi ó fi tu ilẹ̀ ìdí rẹ̀ yíká, títí èmi ó sì fi bu ìlẹ̀dú sí i.

  16. Bí ó bá sì so èso, o dara bẹ́ẹ̀: bí kò bá sì so, ǹjẹ́ lẹ́yìn èyí nì kí ìwọ kí ó ké e lulẹ̀.’ ”